LUKU 13

13
Ẹ Ronupiwada, Bí Bẹ́ẹ̀ Kọ̀ Ẹ Óo Ṣègbé
1Ní àkókò náà gan-an, àwọn kan sọ fún un nípa àwọn ará Galili kan tí Pilatu pa bí wọ́n ti ń rúbọ lọ́wọ́. 2Jesu sọ fún wọn pé, “Ẹ rò pé àwọn ará Galili wọnyi jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ ju gbogbo ará Galili yòókù lọ ni, tí wọ́n fi jẹ irú ìyà yìí? 3Rárá o! Mò ń sọ fun yín pé bí ẹ kò bá ronupiwada, gbogbo yín ni ẹ óo ṣègbé bákan náà. 4Tabi àwọn mejidinlogun tí ilé-ìṣọ́ gíga ní Siloamu wólù, tí ó pa wọ́n, ṣé ẹ rò pé wọ́n burú ju gbogbo àwọn eniyan yòókù tí ó ń gbé Jerusalẹmu lọ ni? 5Rárá ó! Mo sọ fun yín pé bí ẹ kò bá ronupiwada, gbogbo yín ni ẹ óo ṣègbé bákan náà.”
Ẹ̀kọ́ Nípa Igi Ọ̀pọ̀tọ́ Tí Kò Léso
6Ó wá pa òwe yìí fún wọn. Ó ní, “Ẹnìkan gbin igi ọ̀pọ̀tọ́ sinu ọgbà rẹ̀. Ó dé, ó ń wá èso lórí rẹ̀, ṣugbọn kò rí. 7Ó wá sọ fún olùtọ́jú ọgbà pé, ‘Ṣé o rí i! Ó di ọdún mẹta tí mo ti ń wá èso lórí igi ọ̀pọ̀tọ́ yìí tí n kò rí. Gé e lulẹ̀. Kí ló dé tí yóo kàn máa gbilẹ̀ lásán?’ 8Ṣugbọn olùtọ́jú ọgbà dá a lóhùn pé, ‘Alàgbà, fi í sílẹ̀ ní ọdún yìí, kí n walẹ̀ yí i ká, kí n bu ilẹ̀dú sí i. 9Bí ó bá so èso ní ọdún tí ń bọ̀, ó dára. Bí kò bá so èso, gé e.’ ”
Jesu Wo Obinrin Tí Kò Lè Nàró Sàn Ní Ọjọ́ Ìsinmi
10Jesu ń kọ́ àwọn eniyan lẹ́kọ̀ọ́ ninu ilé ìpàdé kan ní Ọjọ́ Ìsinmi. 11Obinrin kan wà tí ó ní irú ẹ̀mí èṣù kan tí ó sọ ọ́ di aláìlera fún ọdún mejidinlogun. Ẹ̀yìn rẹ̀ tẹ̀, kò lè nàró dáradára. 12Nígbà tí Jesu rí i, ó pè é, ó sọ fún un pé, “Obinrin yìí, a wò ọ́ sàn kúrò ninu àìlera rẹ.” 13Jesu bá gbé ọwọ́ mejeeji lé e. Lẹsẹkẹsẹ ni ẹ̀yìn rẹ̀ bá nà, ó bá ń fi ògo fún Ọlọrun.
14Ṣugbọn inú bí olórí ilé ìpàdé nítorí Jesu ṣe ìwòsàn ní Ọjọ́ Ìsinmi. Ó bá sọ fún àwọn eniyan pé, “Ọjọ́ mẹfa wà tí a níláti fi ṣiṣẹ́. Ẹ wá fún ìwòsàn láàrin àwọn ọjọ́ mẹfa yìí. Ẹ má wá fún ìwòsàn ní Ọjọ́ Ìsinmi mọ́!”#Eks 20:9-10; Diut 5:13-14
15Ṣugbọn Oluwa dá a lóhùn pé, “Ẹ̀yin alágàbàgebè! Èwo ninu yín ni kì í tú mààlúù tabi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ sílẹ̀ ní ibùjẹ ẹran kí ó lọ fún un ní omi ní Ọjọ́ Ìsinmi? 16Ẹ wá wo obinrin yìí, ọmọ Abrahamu, tí Satani ti dè fún ọdún mejidinlogun. Ṣé kò yẹ kí á tú u sílẹ̀ ninu ìdè yìí ní Ọjọ́ Ìsinmi?” 17Nígbà tí ó sọ̀rọ̀ báyìí, ojú ti gbogbo àwọn tí ó takò o. Ńṣe ni inú gbogbo àwọn eniyan dùn nítorí gbogbo ohun ìyanu tí ó ń ṣe.
Àwọn Òwe Nípa Wóró Musitadi ati Nípa Ìwúkàrà
(Mat 13:31-33; Mak 4:30-32)
18Nítorí náà Jesu sọ pé, “Kí ni à bá fi ìjọba Ọlọrun wé? Kí ni ǹ bá fi ṣe àkàwé rẹ̀? 19Ó dàbí ẹyọ wóró musitadi kan, tí ẹnìkan mú, tí ó gbìn sí oko rẹ̀. Nígbà tí ó bá dàgbà, ó di igi, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run wá ń ṣe ìtẹ́ wọn sí orí ẹ̀ka rẹ̀.”
20Ó tún sọ pé, “Kí ni ǹ bá fi ìjọba Ọlọrun wé? 21Ó dàbí ìwúkàrà tí obinrin kan mú, tí ó pò mọ́ òṣùnwọ̀n ìyẹ̀fun ńláńlá mẹta títí gbogbo rẹ̀ fi wú sókè.”
Ẹnu Ìlẹ̀kùn Tí Ó Há
(Mat 7:13-14, 21-23)
22Bí Jesu ti ń bá ìrìn àjò rẹ̀ lọ láti ìlú dé ìlú ati láti abúlé dé abúlé, ó ń kọ́ àwọn eniyan bí ó ti ń lọ sí Jerusalẹmu. 23Ẹnìkan wá bi í pé, “Alàgbà, ǹjẹ́ àwọn eniyan tí yóo là kò ní kéré báyìí?”
Jesu wá sọ fún àwọn eniyan pé, 24“Ẹ dù láti gba ẹnu ọ̀nà tí ó há wọlé, nítorí mò ń sọ fun yín pé ọpọlọpọ ni ó ń wá ọ̀nà láti wọlé ṣugbọn wọn kò lè wọlé. 25Nígbà tí baálé ilé bá ti dìde, tí ó bá ti ìlẹ̀kùn, ẹ óo wá dúró lóde, ẹ óo bẹ̀rẹ̀ sí kanlẹ̀kùn, ẹ óo wí pé, ‘Alàgbà, ṣílẹ̀kùn fún wa!’ Ṣugbọn yóo da yín lóhùn pé, ‘Èmi kò mọ̀ yín rí!’ 26Ẹ óo wá máa sọ pé, ‘A jẹ, a mu níwájú rẹ. O kọ́ àwọn eniyan lẹ́kọ̀ọ́ ní ìgboro wa.’ 27Ṣugbọn yóo sọ fun yín pé, ‘Èmi kò mọ̀ yín rí. Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin oníṣẹ́ ibi.’#O. Daf 6:8 28Ẹkún ati ìpayínkeke yóo wà nígbà tí ẹ bá rí Abrahamu ati Isaaki ati Jakọbu ati gbogbo àwọn wolii ní ìjọba Ọlọrun, tí wọ́n wá tì yín mọ́ òde.#Mat 22:13; 25:30 29Àwọn eniyan yóo wá láti ìlà oòrùn ati láti ìwọ̀ oòrùn, láti àríwá ati láti gúsù, wọn yóo jókòó níbi àsè ní ìjọba Ọlọrun.#Mat 8:11-12 30Àwọn èrò ẹ̀yìn yóo di ará iwájú; àwọn ará iwájú yóo di èrò ẹ̀yìn.”#Mat 19:30; 20:16; Mak 10:31
Jesu Dárò Jerusalẹmu
(Mat 23:37-39)
31Ní àkókò náà, àwọn Farisi kan wá sọ́dọ̀ Jesu, wọ́n sọ fún un pé, “Kúrò níhìn-ín nítorí Hẹrọdu fẹ́ pa ọ́.”
32Ó dá wọn lóhùn pé, “Ẹ lọ sọ fún ọlọ́gbọ́n ẹ̀wẹ́ yẹn pé, ‘Mò ń lé ẹ̀mí èṣù jáde, mo tún ń ṣe ìwòsàn lónìí ati lọ́la. Ní ọ̀tunla n óo parí iṣẹ́ mi.’ 33Mo níláti kúrò kí n máa bá iṣẹ́ mi lọ lónìí, lọ́la ati lọ́tùn-unla, nítorí bí wolii kan yóo bá kú, ní Jerusalẹmu ni yóo ti kú.
34“Jerusalẹmu! Jerusalẹmu! Ìwọ tí ò ń pa àwọn wolii, tí ò ń sọ òkúta lu àwọn tí a ti rán sí ọ, nígbà mélòó ni mo ti fẹ́ kó àwọn ọmọ rẹ jọ, bí adìẹ tií kó àwọn ọmọ rẹ̀ sí abẹ́ ìyẹ́ rẹ̀, ṣugbọn ẹ kò gbà fún mi! 35Ẹ wò ó! Ọlọrun ti fi ìlú yín sílẹ̀ fun yín! Ṣugbọn mo wí fun yín pé ẹ kò ní rí mi títí di ìgbà tí ẹ óo wí pé, ‘Alábùkún ni ẹni tí ó ń bọ̀ wá ní orúkọ Oluwa.’ ”#O. Daf 118:26

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

LUKU 13: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀