Amòfin kan wá, ó fi ìbéèrè yìí wá Jesu lẹ́nu wò. Ó ní, “Olùkọ́ni, kí ni kí n ṣe kí n lè jogún ìyè ainipẹkun?”
Jesu bi í pé, “Kí ni ó wà ní àkọsílẹ̀ ninu òfin? Báwo ni o ti túmọ̀ rẹ̀?”
Ó dáhùn pé, “Kí ìwọ fẹ́ràn Oluwa Ọlọrun rẹ pẹlu gbogbo ọkàn rẹ, ati pẹlu gbogbo ẹ̀mí rẹ, ati pẹlu gbogbo agbára rẹ ati pẹlu gbogbo òye rẹ; sì fẹ́ràn ọmọnikeji rẹ bí ara rẹ.”
Jesu sọ fún un pé, “O wí ire. Máa ṣe bẹ́ẹ̀, ìwọ yóo sì yè.”
Ṣugbọn amòfin náà fẹ́ wẹ ara rẹ̀ mọ́. Ó wá bi Jesu pé, “Ta ni ọmọnikeji mi?”
Jesu bá dá a lóhùn pé, “Ọkunrin kan ń ti Jerusalẹmu lọ sí Jẹriko, ni ó bá bọ́ sí ọwọ́ àwọn ọlọ́ṣà. Wọ́n gba aṣọ lára rẹ̀, wọ́n lù ú, wọ́n bá fi í sílẹ̀ nígbà tí ó fẹ́rẹ̀ kú tán. Alufaa kan tí ó ń bọ̀ ṣe kòńgẹ́ rẹ̀ ní ọ̀nà, ṣugbọn nígbà tí ó rí i, ó gba òdìkejì kọjá lọ. Bákan náà ni ọmọ Lefi kan. Nígbà tí òun náà dé ibẹ̀, tí ó rí i, ó gba òdìkejì kọjá lọ. Ṣugbọn ará Samaria kan tí ó ń gba ọ̀nà yìí kọjá lọ dé ọ̀dọ̀ ọkunrin náà. Nígbà tí ó rí i, àánú ṣe é. Ó bá lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, ó fi òróró ati ọtí waini sí ojú ọgbẹ́ rẹ̀, ó sì fi aṣọ wé e. Ó gbé ọkunrin náà ka orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ tí ó gùn. Ó gbé e lọ sí ilé èrò níbi tí ó ti ṣe ìtọ́jú rẹ̀. Nígbà tí ó di ọjọ́ keji, ó yọ owó fadaka meji jáde, ó fún olùtọ́jú ilé èrò, ó ní, ‘Ṣe ìtọ́jú ọkunrin yìí. Ohun tí o bá ná lé e lórí, n óo san án fún ọ nígbà tí mo bá pada dé.’
“Ninu àwọn mẹta yìí, ta ni o rò pé ó jẹ́ ọmọnikeji ẹni tí ó bọ́ sọ́wọ́ àwọn ọlọ́ṣà?”
Amòfin náà dáhùn pé, “Ẹni tí ó ṣàánú fún un ni.”
Jesu sọ fún un pé, “Ìwọ náà lọ ṣe bẹ́ẹ̀ gan-an.”
Bí wọ́n ti ń lọ ninu ìrìn àjò wọn, Jesu wọ inú abúlé kan. Obinrin kan tí ń jẹ́ Mata bá gbà á lálejò. Mata ní arabinrin kan tí ó ń jẹ́ Maria. Maria yìí jókòó lẹ́bàá ẹsẹ̀ Jesu, ó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ṣugbọn Mata kò rójú nítorí aájò tí ó ń ṣe nípa oúnjẹ. Ni Mata bá wá, ó ní, “Alàgbà, arabinrin mi fi èmi nìkan sílẹ̀ láti máa tọ́jú oúnjẹ, o sì dákẹ́ ò ń wò ó níran! Sọ fún un kí ó wá ràn mí lọ́wọ́.”
Ṣugbọn Oluwa dá a lóhùn pé, “Mata! Mata! Ò ń ṣe aájò, o sì ń dààmú nípa ohun pupọ. Ṣugbọn ẹyọ nǹkankan ni ó jẹ́ koṣeemani. Maria ti yan ipò tí ó dára tí a kò ní gbà kúrò lọ́wọ́ rẹ̀.”