Si kiyesi i, amofin kan dide, o ndán a wò, o ni, Olukọni, kili emi o ṣe ki emi ki o le jogún iyè ainipẹkun?
O si bi i pe, Kili a kọ sinu iwe ofin? bi iwọ ti kà a?
O si dahùn wipe, Ki iwọ ki o fi gbogbo àiya rẹ, ati gbogbo ọkàn rẹ, ati gbogbo agbara rẹ, ati gbogbo inu rẹ fẹ Oluwa Ọlọrun rẹ; ati ẹnikeji rẹ bi ara rẹ.
O si wi fun u pe, Iwọ dahùn rere: ṣe eyi, iwọ o si yè.
Ṣugbọn o nfẹ lati dá ara rẹ̀ lare, o wi fun Jesu pe, Tani ha si li ẹnikeji mi?
Jesu si dahùn o wipe, Ọkunrin kan nti Jerusalemu sọkalẹ lọ si Jeriko, o si bọ si ọwọ́ awọn ọlọṣà, ti nwọn gbà a li aṣọ, nwọn ṣá a lọgbẹ, nwọn si fi i silẹ lọ li aipa li apatan.
Ni alabapade, alufa kan si nsọkalẹ lọ lọna na: nigbati o si ri i, o kọja lọ niha keji.
Bẹ̃na si ni ọmọ Lefi kan pẹlu, nigbati o de ibẹ̀, ti o si ri i, o kọja lọ niha keji.
Ṣugbọn ara Samaria kan, bi o ti nrè àjo, o de ibi ti o gbé wà: nigbati o si ri i, ãnu ṣe e,
O si tọ̀ ọ lọ, o si dì i lọgbẹ, o da oróro on ọti-waini si i, o si gbé e le ori ẹranko ti on tikalarẹ̀, o si mu u wá si ile-èro, o si nṣe itọju rẹ̀.
Nigbati o si lọ ni ijọ keji, o fi owo idẹ meji fun olori ile-ero, o si wi fun u pe, Mã tọju rẹ̀; ohunkohun ti iwọ ba si ná kun u, nigbati mo ba pada de, emi ó san a fun ọ.
Ninu awọn mẹtẹta wọnyi, tani iwọ rò pe iṣe ẹnikeji ẹniti o bọ si ọwọ́ awọn ọlọṣà?
O si dahùn wipe, Ẹniti o ṣãnu fun u ni. Jesu si wi fun u pe, Lọ, ki iwọ ki o si ṣe bẹ̃ gẹgẹ.
O si ṣe, bi nwọn ti nlọ, o wọ̀ iletò kan: obinrin kan ti a npè ni Marta si gbà a si ile rẹ̀.
O si ni arabinrin kan ti a npè ni Maria, ti o si joko lẹba ẹsẹ Jesu, ti o ngbọ́ ọ̀rọ rẹ̀.
Ṣugbọn Marta nṣe iyọnu ohun pupọ, o si tọ̀ ọ wá, o ni, Oluwa, iwọ kò kuku ṣu si i ti arabinrin mi fi mi silẹ lati mã nikan ṣe aisimi? Wi fun u ki o ràn mi lọwọ.
Ṣugbọn Jesu si dahùn, o si wi fun u pe, Marta, Marta, iwọ nṣe aniyan ati lãlã nitori ohun pipọ:
Ṣugbọn ohun kan li a kò le ṣe alaini. Maria si ti yàn ipa rere na, ti a kò le gbà lọwọ rẹ̀.