LUKU 10

10
Jesu Rán Àwọn Mejilelaadọrin Níṣẹ́
1Lẹ́yìn èyí, Oluwa yan àwọn mejilelaadọrin#10:1 Àwọn Bibeli àtijọ́ mìíràn ní aadọrin dípò mejilelaadọrin. mìíràn, ó rán wọn ní meji-meji ṣiwaju rẹ̀ lọ sí gbogbo ìlú ati ibi tí òun náà fẹ́ dé. 2Ó sọ fún wọn pé, “Àwọn nǹkan tí ó tó kórè pọ̀ ninu oko, ṣugbọn àwọn òṣìṣẹ́ kò pọ̀ tó. Nítorí náà, ẹ bẹ Oluwa ìkórè kí ó rán àwọn alágbàṣe sí ibi ìkórè rẹ̀.#Mat 9:37-38 3Ẹ máa lọ. Mo ran yín lọ bí aguntan sí ààrin ìkookò.#Mat 10:16 4Ẹ má mú àpò owó lọ́wọ́, tabi àpò báárà. Ẹ má wọ bàtà. Bẹ́ẹ̀ ní kí ẹ má kí ẹnikẹ́ni ní ọ̀nà. 5Ilékílé tí ẹ bá wọ̀, ẹ kọ́kọ́ wí pé, ‘Alaafia fún ilé yìí.’ 6Bí ọmọ alaafia bá wà níbẹ̀, alaafia yín yóo máa wà níbẹ̀. Bí kò bá sí, alaafia yín yóo pada sọ́dọ̀ yín. 7Ninu ilé kan náà ni kí ẹ máa gbé. Ohun tí wọ́n bá gbé kalẹ̀ fun yín ni kí ẹ máa jẹ, kí ẹ sì máa mu. Owó iṣẹ́ alágbàṣe tọ́ sí i. Ẹ má máa lọ láti ilé dé ilé.#1 Kọr 9:14; 1 Tim 5:18 8Ìlúkílùú tí ẹ bá wọ̀, tí wọn bá gbà yín, ẹ máa jẹ ohun tí wọn bá gbé kalẹ̀ níwájú yín. 9Ẹ máa wo àwọn aláìsàn sàn. Kí ẹ sọ fún wọn pé, ‘Ìjọba Ọlọrun ti dé àrọ́wọ́tó yín.’#O. Daf 91:13 10Ṣugbọn ìlúkílùú tí ẹ bá wọ̀ tí wọn kò bá gbà yín, ẹ jáde lọ sí títì ibẹ̀, kí ẹ sọ pé, 11‘Erùpẹ̀ tí ó lẹ̀ mọ́ wa lẹ́sẹ̀ ninu ìlú yín, a gbọ̀n ọ́n kúrò kí ojú lè tì yín. Ṣugbọn kí ẹ mọ èyí pé ìjọba Ọlọrun wà ní àrọ́wọ́tó yín.’#Mat 10:7-14; Mak 6:8-11; Luk 9:3-5 #A. Apo 13:51 12Mo sọ fun yín pé yóo sàn fún Sodomu ní ọjọ́ ńlá náà jù fún ìlú náà lọ.#a Jẹn 19:24-28; Mat 11:24 b Mat 10:15
Jesu Dárò Àwọn Ìlú tí Kò Ronupiwada
(Mat 11:20-24)
13“O gbé! Korasini. O gbé! Bẹtisaida. Nítorí bí ó bá jẹ́ pé ní Tire ati ní Sidoni ni a ti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu tí a ṣe láàrin yín ni, wọn ìbá ti ronupiwada tipẹ́tipẹ́, wọn ìbá jókòó ninu eérú pẹlu aṣọ ọ̀fọ̀.#Ais 23:1-18; Isi 26:1–28:26; Joẹl 3:4-8; Amos 1:9-10; Sak 9:2-4 14Yóo sàn fún Tire ati fún Sidoni ní ọjọ́ ìdájọ́ jù fún yín lọ. 15Ìwọ Kapanaumu, o rò pé a óo gbé ọ ga dé ọ̀run ni? Rárá o! Ní ọ̀gbun jíjìn ni a óo sọ ọ́ sí!#Ais 14:13-15
16“Ẹni tí ó bá gbọ́ tiyín, ó gbọ́ tèmi. Ẹni tí ó bá kọ̀ yín èmi ni ó kọ̀. Ẹni tí ó bá sì wá kọ̀ mí, ó kọ ẹni tí ó fi iṣẹ́ rán mi.”#Mat 10:40; Mak 9:37; Luk 9:48 Joh 13:20
Àwọn Mejilelaadọrin Pada Dé
17Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejilelaadọrin#10:17 Àwọn Bibeli àtijọ́ mìíràn ní aadọrin dípò mejilelaadọrin. pada dé pẹlu ayọ̀. Wọ́n ní, “Oluwa, àwọn ẹ̀mí èṣù pàápàá gbọ́ràn sí wa lẹ́nu ní orúkọ rẹ.”
18Ó bá sọ fún wọn pé, “Mo rí Satani tí ó ti ọ̀run já bọ́ bí ìràwọ̀. 19Mo fun yín ní àṣẹ láti tẹ ejò ati àkeekèé mọ́lẹ̀. Mo tún fun yín ní àṣẹ lórí gbogbo agbára ọ̀tá. Kò sí ohunkohun tí yóo pa yín lára. 20Ẹ má yọ̀ ní ti pé àwọn ẹ̀mí èṣù gbọ́ràn si yín lẹ́nu; ṣugbọn ẹ máa yọ̀ nítorí a ti kọ orúkọ yín sí ọ̀run.”
Jesu Láyọ̀
(Mat 11:25-27; 13:16-17)
21Ní àkókò náà Jesu láyọ̀ ninu Ẹ̀mí Mímọ́.#10:21 Àwọn Bibeli àtijọ́ mìíràn ní ninu Ẹ̀mí dípò ninu Ẹ̀mí Mímọ́. Ó ní, “Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, Baba, Oluwa ọ̀run ati ayé, nítorí o ti pa nǹkan wọnyi mọ́ fún àwọn ọlọ́gbọ́n ati àwọn olóye; ṣugbọn o fi wọ́n han àwọn òpè. Bẹ́ẹ̀ ni, Baba, nítorí bí ó ti tọ́ ní ojú rẹ ni.
22“Baba mi ti fi ohun gbogbo lé mi lọ́wọ́. Kò sí ẹni tí ó mọ ẹni tí Ọmọ jẹ́, àfi Baba. Kò sí ẹni tí ó mọ ẹni tí Baba jẹ́, àfi Ọmọ; àtúnfi àwọn tí Ọmọ bá fẹ́ fi Baba hàn fún.”#a Joh 3:35; b Joh 10:15
23Jesu yipada sí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ níkọ̀kọ̀, ó ní, “Ẹ ṣe oríire tí ojú yín rí àwọn ohun tí ẹ rí, 24nítorí mò ń sọ fun yín pé ọ̀pọ̀ àwọn wolii ati àwọn ọba ni wọ́n fẹ́ rí àwọn nǹkan tí ẹ rí, ṣugbọn tí wọn kò rí i; wọ́n fẹ́ gbọ́ ohun tí ẹ gbọ́ ṣugbọn wọn kò gbọ́ ọ.”
Aláàánú Ará Samaria
25Amòfin kan wá, ó fi ìbéèrè yìí wá Jesu lẹ́nu wò. Ó ní, “Olùkọ́ni, kí ni kí n ṣe kí n lè jogún ìyè ainipẹkun?”
26Jesu bi í pé, “Kí ni ó wà ní àkọsílẹ̀ ninu òfin? Báwo ni o ti túmọ̀ rẹ̀?”
27Ó dáhùn pé, “Kí ìwọ fẹ́ràn Oluwa Ọlọrun rẹ pẹlu gbogbo ọkàn rẹ, ati pẹlu gbogbo ẹ̀mí rẹ, ati pẹlu gbogbo agbára rẹ ati pẹlu gbogbo òye rẹ; sì fẹ́ràn ọmọnikeji rẹ bí ara rẹ.”#a Diut 6:5; b Lef 19:18
28Jesu sọ fún un pé, “O wí ire. Máa ṣe bẹ́ẹ̀, ìwọ yóo sì yè.”#Mat 22:35-40; Mak 12:28-34 #Lef 18:5
29Ṣugbọn amòfin náà fẹ́ wẹ ara rẹ̀ mọ́. Ó wá bi Jesu pé, “Ta ni ọmọnikeji mi?”
30Jesu bá dá a lóhùn pé, “Ọkunrin kan ń ti Jerusalẹmu lọ sí Jẹriko, ni ó bá bọ́ sí ọwọ́ àwọn ọlọ́ṣà. Wọ́n gba aṣọ lára rẹ̀, wọ́n lù ú, wọ́n bá fi í sílẹ̀ nígbà tí ó fẹ́rẹ̀ kú tán. 31Alufaa kan tí ó ń bọ̀ ṣe kòńgẹ́ rẹ̀ ní ọ̀nà, ṣugbọn nígbà tí ó rí i, ó gba òdìkejì kọjá lọ. 32Bákan náà ni ọmọ Lefi kan. Nígbà tí òun náà dé ibẹ̀, tí ó rí i, ó gba òdìkejì kọjá lọ. 33Ṣugbọn ará Samaria kan tí ó ń gba ọ̀nà yìí kọjá lọ dé ọ̀dọ̀ ọkunrin náà. Nígbà tí ó rí i, àánú ṣe é. 34Ó bá lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, ó fi òróró ati ọtí waini sí ojú ọgbẹ́ rẹ̀, ó sì fi aṣọ wé e. Ó gbé ọkunrin náà ka orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ tí ó gùn. Ó gbé e lọ sí ilé èrò níbi tí ó ti ṣe ìtọ́jú rẹ̀.#2Kron 28:15 35Nígbà tí ó di ọjọ́ keji, ó yọ owó fadaka meji jáde, ó fún olùtọ́jú ilé èrò, ó ní, ‘Ṣe ìtọ́jú ọkunrin yìí. Ohun tí o bá ná lé e lórí, n óo san án fún ọ nígbà tí mo bá pada dé.’
36“Ninu àwọn mẹta yìí, ta ni o rò pé ó jẹ́ ọmọnikeji ẹni tí ó bọ́ sọ́wọ́ àwọn ọlọ́ṣà?”
37Amòfin náà dáhùn pé, “Ẹni tí ó ṣàánú fún un ni.”
Jesu sọ fún un pé, “Ìwọ náà lọ ṣe bẹ́ẹ̀ gan-an.”
Jesu Bẹ Mata ati Maria Wò
38Bí wọ́n ti ń lọ ninu ìrìn àjò wọn, Jesu wọ inú abúlé kan. Obinrin kan tí ń jẹ́ Mata bá gbà á lálejò. 39Mata ní arabinrin kan tí ó ń jẹ́ Maria. Maria yìí jókòó lẹ́bàá ẹsẹ̀ Jesu, ó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀.#Joh 11:1 40Ṣugbọn Mata kò rójú nítorí aájò tí ó ń ṣe nípa oúnjẹ. Ni Mata bá wá, ó ní, “Alàgbà, arabinrin mi fi èmi nìkan sílẹ̀ láti máa tọ́jú oúnjẹ, o sì dákẹ́ ò ń wò ó níran! Sọ fún un kí ó wá ràn mí lọ́wọ́.”
41Ṣugbọn Oluwa dá a lóhùn pé, “Mata! Mata! Ò ń ṣe aájò, o sì ń dààmú nípa ohun pupọ. 42Ṣugbọn ẹyọ nǹkankan ni ó jẹ́ koṣeemani. Maria ti yan ipò tí ó dára tí a kò ní gbà kúrò lọ́wọ́ rẹ̀.”

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

LUKU 10: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa