LEFITIKU 9:1-6

LEFITIKU 9:1-6 YCE

Ní ọjọ́ kẹjọ, Mose pe Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ ati àwọn àgbààgbà Israẹli; ó wí fún Aaroni pé, “Mú ọ̀dọ́ akọ mààlúù kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ati àgbò kan fún ẹbọ sísun kí o sì fi wọ́n rúbọ níwájú OLUWA. Àwọn ẹran mejeeji yìí kò gbọdọ̀ ní àbààwọ́n. Sì sọ fún àwọn eniyan Israẹli pé, ‘Ẹ mú òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ati ọmọ mààlúù kan ati ọ̀dọ́ aguntan kan fún ẹbọ sísun, kí àwọn mejeeji jẹ́ ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan, wọn kò sì gbọdọ̀ ní àbààwọ́n. Sì mú akọ mààlúù kan ati àgbò kan fún ẹbọ alaafia, kí ẹ fi wọ́n rúbọ níwájú OLUWA pẹlu ẹbọ ohun jíjẹ tí a fi òróró pò, nítorí pé OLUWA yóo fi ara hàn yín lónìí.’ ” Wọ́n mú àwọn ohun tí Mose paláṣẹ wá siwaju Àgọ́ Àjọ, gbogbo ìjọ eniyan sì dúró níwájú OLUWA. Mose sọ fún wọn pé, “Ohun tí OLUWA paláṣẹ fun yín láti ṣe nìyí, ògo OLUWA yóo hàn sí yín.”