Lef 9:1-6
Lef 9:1-6 Yoruba Bible (YCE)
Ní ọjọ́ kẹjọ, Mose pe Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ ati àwọn àgbààgbà Israẹli; ó wí fún Aaroni pé, “Mú ọ̀dọ́ akọ mààlúù kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ati àgbò kan fún ẹbọ sísun kí o sì fi wọ́n rúbọ níwájú OLUWA. Àwọn ẹran mejeeji yìí kò gbọdọ̀ ní àbààwọ́n. Sì sọ fún àwọn eniyan Israẹli pé, ‘Ẹ mú òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ati ọmọ mààlúù kan ati ọ̀dọ́ aguntan kan fún ẹbọ sísun, kí àwọn mejeeji jẹ́ ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan, wọn kò sì gbọdọ̀ ní àbààwọ́n. Sì mú akọ mààlúù kan ati àgbò kan fún ẹbọ alaafia, kí ẹ fi wọ́n rúbọ níwájú OLUWA pẹlu ẹbọ ohun jíjẹ tí a fi òróró pò, nítorí pé OLUWA yóo fi ara hàn yín lónìí.’ ” Wọ́n mú àwọn ohun tí Mose paláṣẹ wá siwaju Àgọ́ Àjọ, gbogbo ìjọ eniyan sì dúró níwájú OLUWA. Mose sọ fún wọn pé, “Ohun tí OLUWA paláṣẹ fun yín láti ṣe nìyí, ògo OLUWA yóo hàn sí yín.”
Lef 9:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní ọjọ́ kẹjọ, Mose pe Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn àgbàgbà Israẹli. Ó sọ fún Aaroni pé, “Mú akọ ọmọ màlúù kan wá fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti àgbò kan fún ẹbọ sísun, kí méjèèjì jẹ́ aláìlábùkù, kí o sì mú wọn wá sí iwájú OLúWA. Kí o sì sọ fún àwọn ará Israẹli pé, ‘Ẹ mú òbúkọ kan wá fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, ọmọ màlúù àti ọ̀dọ́-àgùntàn kan, kí méjèèjì jẹ́ ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan tí kò ní àbùkù fún ẹbọ sísun, àti akọ màlúù kan àti àgbò kan fún ẹbọ àlàáfíà àti ẹbọ ohun jíjẹ tí a fi òróró pò láti fi rú ẹbọ ní iwájú OLúWA. Nítorí pé OLúWA yóò farahàn yín ní òní.’ ” Wọ́n kó gbogbo àwọn nǹkan tí Mose pàṣẹ wá sí iwájú àgọ́ ìpàdé, gbogbo ìjọ ènìyàn sì súnmọ́ tòsí, wọ́n sì dúró níwájú OLúWA. Nígbà náà ni Mose wí pé, “Ohun tí OLúWA pàṣẹ fún yín láti ṣe nìyìí, kí ògo OLúWA bá à lè farahàn yín.”
Lef 9:1-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si ṣe ni ijọ́ kẹjọ, ni Mose pè Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn àgba Israeli; O si wi fun Aaroni pe, Mú ọmọ akọmalu kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati àgbo kan alailabùku fun ẹbọ sisun, ki o fi wọn rubọ niwaju OLUWA. Ki iwọ ki o si sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, Ẹ mú obukọ kan wá fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ; ati ọmọ malu kan, ati ọdọ-agutan kan, mejeji ọlọdún kan, alailabùku, fun ẹbọ sisun; Ati akọmalu kan ati àgbo kan fun ẹbọ alafia, lati fi ru ẹbọ niwaju OLUWA; ati ẹbọ ohunjijẹ ti a fi oróro pò: nitoripe li oni li OLUWA yio farahàn nyin. Nwọn si mú ohun ti Mose filelẹ li aṣẹ́ wá siwaju agọ́ ajọ: gbogbo ijọ si sunmọtosi nwọn si duro niwaju OLUWA. Mose si wipe, Eyi li ohun ti OLUWA filelẹ li aṣẹ, ki ẹnyin ki o ṣe: ogo OLUWA yio si farahàn nyin.