LEFITIKU 17

17
Ẹ̀jẹ̀ Lọ́wọ̀–Ninu Rẹ̀ Ni Ẹ̀mí wà
1OLUWA sọ fún Mose pé 2kí ó sọ fún Aaroni, ati àwọn ọmọkunrin rẹ̀, ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli pé, “Ohun tí OLUWA paláṣẹ nìyí: 3Bí ẹnìkan ninu àwọn ọmọ Israẹli bá pa akọ mààlúù, tabi ọ̀dọ́ aguntan, tabi ewúrẹ́ kan ní ibùdó, tabi lẹ́yìn ibùdó, 4tí kò bá mú un wá sí ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ láti fi ṣe ẹ̀bùn fún OLUWA níwájú Àgọ́ mímọ́ rẹ̀, olúwarẹ̀ yóo jẹ̀bi ìtàjẹ̀sílẹ̀, ó ti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀, a óo sì yọ ọ́ kúrò láàrin àwọn eniyan rẹ̀. 5OLUWA pa àṣẹ yìí kí àwọn ọmọ Israẹli lè máa mú ẹran ìrúbọ tí wọ́n bá pa ninu pápá wá fún OLUWA, kí wọn mú un tọ alufaa wá lẹ́nu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ, kí wọn sì pa á láti fi rú ẹbọ alaafia sí OLUWA. 6Alufaa yóo sì máa wọ́n ẹ̀jẹ̀ wọn sí ara pẹpẹ OLUWA lẹ́nu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ, yóo sì sun ọ̀rá wọn bí ẹbọ sísun olóòórùn dídùn sí OLUWA. 7Kí àwọn ọmọ Israẹli má baà tún máa fi ẹran wọn rúbọ sí oriṣa bí wọ́n ti ń ṣe rí. Òfin yìí wà fún arọmọdọmọ wọn títí lae.
8“Bákan náà, ẹnikẹ́ni ninu àwọn ọmọ Israẹli tabi àlejò tí ń ṣe àtìpó láàrin wọn, tí ó bá rú ẹbọ sísun tabi ẹbọ mìíràn, 9tí kò bá mú ẹran tí yóo fi rú ẹbọ náà wá sí ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ láti fi rúbọ sí OLUWA, a óo yọ ẹni náà kúrò láàrin àwọn eniyan rẹ̀.
10“Bí ẹnikẹ́ni ninu àwọn ọmọ Israẹli tabi àlejò tí ń ṣe àtìpó láàrin wọn bá jẹ ẹ̀jẹ̀, èmi OLUWA yóo bínú sí olúwarẹ̀, n óo sì yọ ọ́ kúrò láàrin àwọn eniyan rẹ̀. #Jẹn 9:4; Lef 7:26-27; 19:26; Diut 12:16, 23; 15:23; 11Nítorí pé, ninu ẹ̀jẹ̀ ni ẹ̀mí ohun alààyè gbogbo wà; mo sì ti fun yín, pé kí ẹ máa ta á sórí pẹpẹ, kí ẹ máa fi ṣe ètùtù fún ẹ̀mí yín; nítorí pé ẹ̀jẹ̀ níí ṣe ètùtù, nítorí ẹ̀mí tí ó wà ninu rẹ̀. #Heb 9:22. 12Nítorí rẹ̀ ni mo fi sọ fún ẹ̀yin ọmọ Israẹli pé, ẹnikẹ́ni ninu yín kò gbọdọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni àlejò tí ń ṣe àtìpó láàrin yín kò gbọdọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀.
13“Ẹnikẹ́ni ninu àwọn ọmọ Israẹli, tabi àwọn àlejò tí ń ṣe àtìpó láàrin wọn tí ó bá lọ ṣe ọdẹ tí ó sì pa ẹran tabi ẹyẹ tí eniyan lè jẹ, ó níláti ro gbogbo ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀ kí ó sì wa erùpẹ̀ bò ó. 14Nítorí pé, ninu ẹ̀jẹ̀ ni ẹ̀mí gbogbo ohun alààyè wà, nítorí náà ni mo fi sọ fún ẹ̀yin ọmọ Israẹli pé, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀ ẹ̀dá alààyè kankan, nítorí pé, ninu ẹ̀jẹ̀ ni ẹ̀mí ẹ̀dá alààyè gbogbo wà, ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ ẹ́, a óo yọ ọ́ kúrò.
15“Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì jẹ ohunkohun tí ó kú fúnra rẹ̀, tabi tí ẹranko burúkú fà ya, kí ẹni náà fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀, yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́, lẹ́yìn ìgbà náà ni yóo tó pada di mímọ́. 16Ṣugbọn, tí kò bá fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀, yóo jìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.”

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

LEFITIKU 17: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀