LEFITIKU 16

16
Ọjọ́ Ètùtù
1Lẹ́yìn tí meji ninu àwọn ọmọ Aaroni kú, nígbà tí wọ́n fi iná tí kò mọ́ rúbọ sí OLUWA, OLUWA bá sọ fún Mose pé, 2“Sọ fún Aaroni arakunrin rẹ pé kí ó má ṣe máa wọ ibi mímọ́ jùlọ, tí ó wà lẹ́yìn aṣọ títa, níwájú ìtẹ́ àánú tí ó wà lórí àpótí ẹ̀rí nígbà gbogbo, kí ó má baà kú; nítorí pé n óo fi ara hàn ninu ìkùukùu, lórí ìtẹ́ àánú.#Heb 6:19; 3Ṣugbọn ohun tí yóo ṣe, nígbà tí yóo bá wọ ibi mímọ́ náà nìyí: kí ó mú ọ̀dọ́ akọ mààlúù kan lọ́wọ́ fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ati àgbò kan fún ẹbọ sísun.#Heb 9:7
4“Kí ó kọ́kọ́ wẹ̀, lẹ́yìn náà, kí ó wọ àwọn aṣọ mímọ́ nnì: ẹ̀wù funfun mímọ́, pẹlu ṣòkòtò funfun, kí ó fi ọ̀já funfun di àmùrè, kí ó sì dé fìlà funfun.
5“Yóo gba òbúkọ meji lọ́wọ́ ìjọ eniyan Israẹli fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ati àgbò kan fún ẹbọ sísun. 6Aaroni yóo fi ọ̀dọ́ mààlúù kan rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ fún ara rẹ̀, yóo sì ṣe ètùtù fún ara rẹ̀ ati ilé rẹ̀. 7Lẹ́yìn náà yóo mú àwọn ewúrẹ́ mejeeji, yóo fà wọ́n kalẹ̀ níwájú OLUWA, ní ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ. 8Lẹ́yìn náà, yóo ṣẹ́ gègé lórí àwọn ewúrẹ́ mejeeji, gègé kan fún OLUWA, ekeji fún Asaseli. 9Aaroni yóo fa ẹran tí gègé OLUWA bá mú kalẹ̀ níwájú OLUWA, yóo sì fi rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. 10Ṣugbọn láàyè ni yóo fa ẹran tí gègé Asaseli bá mú kalẹ̀ níwájú OLUWA, yóo ṣe ètùtù lórí rẹ̀, yóo sì tú u sílẹ̀, kí ó sá tọ Asaseli lọ ninu aṣálẹ̀.
11“Aaroni yóo fa akọ mààlúù kan kalẹ̀ tí yóo fi rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ fún ara rẹ̀, yóo sì ṣe ètùtù fún ara rẹ̀ ati ilé rẹ̀; yóo pa akọ mààlúù náà fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ fún ara rẹ̀. 12Lẹ́yìn náà, yóo mú ẹ̀yinná láti orí pẹpẹ tí ó wà níwájú OLUWA sinu àwo turari, yóo sì bu turari olóòórùn dídùn tí wọ́n gún, ẹ̀kúnwọ́ meji, yóo sì gbé e lọ sinu ibi tí aṣọ ìbòjú wà. 13Yóo da turari náà sórí iná níwájú OLUWA, kí èéfín turari náà lè bo ìtẹ́ àánú tí ó wà lórí àpótí ẹ̀rí, kí Aaroni má baà kú. 14Yóo mú díẹ̀ ninu ẹ̀jẹ̀ akọ mààlúù náà, yóo fi ìka wọ́n ọn siwaju ìbòrí ìtẹ́ àánú. Bákan náà, yóo fi ìka wọ́n ẹ̀jẹ̀ náà siwaju Àpótí Ẹ̀rí nígbà meje.
15“Lẹ́yìn náà yóo pa ewúrẹ́ ìrúbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ tí ó jẹ́ ti àwọn eniyan Israẹli, yóo sì gbé ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ lọ sinu ibi tí aṣọ ìbòjú wà, yóo sì ṣe é bí ó ti ṣe ẹ̀jẹ̀ akọ mààlúù, yóo wọ́n ọn siwaju ìbòrí ìtẹ́ àánú, yóo sì tún wọ́n ọn siwaju Àpótí Ẹ̀rí.#Heb 9:12. 16Bẹ́ẹ̀ ni yóo ti ṣe ètùtù fún ibi mímọ́ náà, nítorí àìmọ́ àwọn eniyan Israẹli, ati nítorí ìrékọjá ati gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn, bẹ́ẹ̀ gan-an ni yóo sì ṣe sí Àgọ́ Àjọ tí ó wà láàrin wọn, nítorí àìmọ́ wọn. 17Kò ní sí ẹnikẹ́ni ninu Àgọ́ Àjọ nígbà tí ó bá wọlé lọ láti ṣe ètùtù ninu ibi mímọ́ náà, títí tí yóo fi jáde, lẹ́yìn tí ó bá ti ṣe ètùtù fún ara rẹ̀, ati ilé rẹ̀, ati fún gbogbo ìjọ eniyan Israẹli. 18Lẹ́yìn náà, yóo jáde lọ sí ibi pẹpẹ tí ó wà níwájú OLUWA, yóo sì ṣe ètùtù fún un. Yóo mú díẹ̀ ninu ẹ̀jẹ̀ akọ mààlúù náà ati ti ewúrẹ́ náà, yóo sì fi ra àwọn ìwo pẹpẹ náà yípo. 19Yóo sì fi ìka wọ́n díẹ̀ ninu ẹ̀jẹ̀ náà sí ara pẹpẹ nígbà meje, yóo sọ ọ́ di mímọ́, yóo sì yà á sí mímọ́ kúrò ninu àìmọ́ àwọn eniyan Israẹli.
Ewúrẹ́ tí A Di Ẹrù Ẹ̀ṣẹ̀ lé Lórí
20“Lẹ́yìn ìgbà tí ó bá ti parí ṣíṣe ètùtù fún ibi mímọ́ náà, ati fún Àgọ́ Àjọ náà, ati pẹpẹ náà, yóo fa ààyè ewúrẹ́ náà kalẹ̀. 21Yóo gbé ọwọ́ rẹ̀ mejeeji lé e lórí, yóo jẹ́wọ́ gbogbo àìṣedéédé ati ìrékọjá ati ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli lórí rẹ̀, yóo sì kó wọn lé e lórí, yóo fà á lé ẹnìkan tí ó ti múra sílẹ̀ lọ́wọ́, láti fà á lọ sinu aṣálẹ̀. 22Òbúkọ náà yóo sì fi orí rẹ̀ ru gbogbo àìṣedéédé wọn, títí tí ẹni náà yóo fi fà á dé ibi tí eniyan kì í gbé, ibẹ̀ ni yóo ti sọ ọ́ sílẹ̀ kí ó lè wọ inú aṣálẹ̀ lọ.#Tob 8:3
23“Aaroni yóo pada wá sinu Àgọ́ Àjọ, yóo bọ́ àwọn aṣọ funfun tí ó wọ̀ kí ó tó wọ inú ibi mímọ́ lọ, yóo sì fi wọ́n sílẹ̀ níbẹ̀.#Isi 44:19 24Yóo wẹ̀ ní ibi mímọ́, yóo kó àwọn aṣọ tirẹ̀ wọ̀, yóo sì jáde. Lẹ́yìn náà yóo rú ẹbọ sísun tirẹ̀ ati ẹbọ sísun ti àwọn eniyan náà, yóo sì ṣe ètùtù fún ara rẹ̀ ati fún àwọn eniyan náà. 25Yóo sun ọ̀rá ẹran ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ lórí pẹpẹ náà. 26Ẹni tí ó fa ewúrẹ́ náà tọ Asaseli lọ ninu aṣálẹ̀ yóo fọ aṣọ rẹ̀, yóo sì wẹ̀, lẹ́yìn náà, ó lè wọ ibùdó. 27Lẹ́yìn náà, wọn yóo gbé òkú akọ mààlúù ati ti òbúkọ tí wọ́n fi rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ati ẹ̀jẹ̀ wọn tí wọ́n gbé wọ ibi mímọ́ lọ láti fi ṣe ètùtù, wọn yóo rù wọ́n jáde kúrò ní ibùdó, wọn yóo sì dáná sun ati awọ, ati ara ẹran ati nǹkan inú wọn.#Heb 13:11, 28Ẹni tí ó bá lọ sun wọ́n, yóo fọ aṣọ rẹ̀, yóo sì wẹ̀, lẹ́yìn náà, ó lè wọ ibùdó wá.
Ìlànà fún Ìrántí Ọjọ́ Ètùtù
29“Kí ó jẹ́ ìlànà fun yín títí lae pé, ní ọjọ́ kẹwaa oṣù keje, ati onílé ati àlejò yín, ẹ gbọdọ̀ gbààwẹ̀, ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan. 30Nítorí pé, ní ọjọ́ náà ni wọn yóo máa ṣe ètùtù fun yín, tí yóo sọ yín di mímọ́ kúrò ninu gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ yín, kí ẹ lè jẹ́ mímọ́ níwájú OLUWA. 31Ọjọ́ ìsinmi tí ó lọ́wọ̀ ni ó jẹ́ fun yín, ẹ sì gbọdọ̀ gbààwẹ̀; ìlànà ni èyí jẹ́ fun yín títí lae. 32Alufaa tí wọ́n bá ta òróró sí lórí, tí wọ́n sì yà sí mímọ́ gẹ́gẹ́ bí alufaa àgbà ní ipò baba rẹ̀ ni kí ó máa ṣe ètùtù, kí ó sì máa wọ aṣọ mímọ́ náà. 33Yóo ṣe ètùtù fún Àgọ́ mímọ́ náà, ati Àgọ́ Àjọ, ati pẹpẹ náà, kí ó sì ṣe ètùtù fún àwọn alufaa pẹlu ati ìjọ eniyan náà. 34Èyí yóo jẹ́ ìlànà ayérayé fun yín, kí wọ́n lè máa ṣe ètùtù fún àwọn ọmọ Israẹli ní ẹ̀ẹ̀kan lọ́dún, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn.”#Lef 23:26-32; Nọm 29:7-11.
Mose sì ṣe gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí OLUWA pa fún un.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

LEFITIKU 16: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀