JOBU 33

33
1“Jobu, tẹ́tí sílẹ̀ nisinsinyii kí o gbọ́ ọ̀rọ̀ mi.
2Wò ó! Mo fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀,
ọ̀rọ̀ sì pọ̀ tí mo fẹ́ sọ.
3Òtítọ́ inú ni mo fi fẹ́ sọ̀rọ̀,
ohun tí mo mọ̀ pé òdodo ni ni mo sì fẹ́ sọ.
4Ẹ̀mí Ọlọrun ni ó dá mi,
èémí Olodumare ni ó sì fún mi ní ìyè.
5“Bí o bá lè dá mi lóhùn, dáhùn.
Ro ohun tí o fẹ́ sọ dáradára,
kí o sì múra láti wí àwíjàre.
6Wò ó, bákan náà ni èmi pẹlu rẹ rí lójú Ọlọrun,
amọ̀ ni a fi mọ èmi náà.
7Má jẹ́ kí ẹ̀rù mi bà ọ́,
bẹ́ẹ̀ ni n kò ní le kankan mọ́ ọ.
8“Lóòótọ́, o ti sọ̀rọ̀ ní etígbọ̀ọ́ mi,
mo sì ti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ.
9O ní o mọ́, o kò ní ẹ̀ṣẹ̀,
ara rẹ mọ́ o kò sì ṣe àìdára kankan.
10Sibẹ Ọlọrun wá ẹ̀sùn sí ọ lẹ́sẹ̀,
ó sọ ọ́ di ọ̀tá rẹ̀,
11ó kan ààbà mọ́ ọ lẹ́sẹ̀,
ó sì ń ṣọ́ ìrìn rẹ.#Job 13:27
12“Jobu, n óo dá ọ lóhùn,
nítorí pé bí o ti wí yìí, bẹ́ẹ̀ kọ́ lọ̀rọ̀ rí.
Ọlọrun ju eniyan lọ.
13Kí ló dé tí ò ń fi ẹ̀sùn kàn án
pé kò ní fèsì kankan sí ọ̀rọ̀ rẹ?
14Nítorí Ọlọrun sọ̀rọ̀ bákan, ó tún tún un sọ bámìíràn,
ṣugbọn kò sí ẹni tí ó yé.
15Ninu àlá, lójú ìran ní ààrin òru,
nígbà tí eniyan bá sun oorun àsùnwọra, lórí ibùsùn wọn,
16Ọlọrun a máa ṣí wọn létí,
a máa kìlọ̀ fún wọn, a sì máa dẹ́rùbà wọ́n,
17kí ó lè dá wọn lẹ́kun ìṣe wọn,
kí ó lè gba ìgbéraga lọ́wọ́ wọn;
18kí ó lè yọ ọkàn eniyan kúrò ninu ọ̀fìn ìparun,
kí ó má baà kú ikú idà.
19“OLUWA a máa fi ìrora jẹ eniyan níyà lórí ibùsùn rẹ̀;
a sì máa kó ìnira bá egungun rẹ̀.
20Tóbẹ́ẹ̀ tí ẹnu rẹ̀ yóo kọ oúnjẹ,
oúnjẹ àdídùn óo sì rùn sí i.
21Eniyan á rù hangangan,
wọn a sì fẹ́rẹ̀ lè máa ka egungun rẹ̀.
22Ọkàn rẹ̀ á súnmọ́ ibojì,
ẹ̀mí rẹ̀ a sì súnmọ́ àwọn iranṣẹ ikú.#Job 4:13
23Bí angẹli kan bá wà pẹlu rẹ̀,
tí ó wà fún un bí onídùúró,
àní, ọ̀kan láàrin ẹgbẹrun,
tí yóo sọ ohun tí ó tọ́ fún un,
24tí yóo ṣàánú rẹ̀, tí yóo sì wí pé,
‘Ẹ gbà á sílẹ̀, ẹ má jẹ́ kí ó lọ sinu ibojì,
mo ti rí ìràpadà kan dípò rẹ̀.’
25Jẹ́ kí àwọ̀ rẹ̀ jọ̀lọ̀ bí ara ọmọde,
kí agbára rẹ̀ sì pada dàbí ti ìgbà ọ̀dọ́;
26nígbà náà eniyan óo gbadura sí Ọlọrun,
Ọlọrun óo sì gbọ́ adura rẹ̀.
Eniyan óo wá fi ayọ̀ wá siwaju Ọlọrun,
yóo sì ròyìn ìgbàlà Ọlọrun fún gbogbo aráyé
27Yóo wá sọ gbangba níwájú àwọn eniyan pé,
‘Mo ti ṣẹ̀, mo sì ti yí ẹ̀tọ́ po,
ṣugbọn Ọlọrun kò jẹ mí níyà ẹ̀ṣẹ̀ mi.
28Ó ti ra ọkàn mi pada kúrò lọ́wọ́ isà òkú,
mo sì wà láàyè.’
29“Wò ó, Ọlọrun a máa ṣe nǹkan wọnyi léraléra fún eniyan,
lẹẹmeji tabi lẹẹmẹta,
30láti lè gba ọkàn rẹ̀ là lọ́wọ́ ikú,
kí ó lè wà láàyè.
31“Gbọ́, ìwọ Jobu, farabalẹ̀,
dákẹ́ kí o lè gbọ́ ohun tí n óo sọ.
32Bí o bá ní ohunkohun láti sọ, dá mi lóhùn;
sọ̀rọ̀, nítorí pé mo fẹ́ dá ọ láre ni.
33Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, tẹ́tí sí mi;
farabalẹ̀, n óo sì kọ́ ọ lọ́gbọ́n.”

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

JOBU 33: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀