JOBU 29:7-17

JOBU 29:7-17 YCE

Nígbà tí mo lọ sí ẹnubodè ìlú, tí mo jókòó ní gbàgede, tí àwọn ọdọmọkunrin bá rí mi, wọn á bìlà sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, àwọn àgbà á sì dìde dúró; àwọn ìjòyè á dákẹ́ rọ́rọ́, wọn á fi ọwọ́ bo ẹnu wọn. Àwọn olórí á panumọ́, ahọ́n wọn á lẹ̀ mọ́ wọn lẹ́nu. Àwọn tí wọ́n gbọ́ nípa mi, ń pè mí ní ẹni ibukun, àwọn tí wọ́n rí mi ń kan sáárá sí mi. Nítorí pé mò ń ran àwọn aláìní tí ń ké lọ́wọ́, ati àwọn aláìníbaba tí wọn kò ní olùrànlọ́wọ́. Ìre àwọn tí ń kú lọ mọ́ mi, mo sì mú kí opó kọrin ayọ̀. Mo fi òdodo bora bí aṣọ, ìdájọ́ òtítọ́ dàbí ẹ̀wù ati adé mi. Mo jẹ́ ojú fún afọ́jú, ati ẹsẹ̀ fún arọ. Mo jẹ́ baba fún talaka, mo gba ẹjọ́ àlejò rò. Mo ṣẹ́ ẹni ibi lápá, mo gba ẹni tí ó mú sílẹ̀.