Job 29:7-17
Job 29:7-17 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí mo lọ sí ẹnubodè ìlú, tí mo jókòó ní gbàgede, tí àwọn ọdọmọkunrin bá rí mi, wọn á bìlà sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, àwọn àgbà á sì dìde dúró; àwọn ìjòyè á dákẹ́ rọ́rọ́, wọn á fi ọwọ́ bo ẹnu wọn. Àwọn olórí á panumọ́, ahọ́n wọn á lẹ̀ mọ́ wọn lẹ́nu. Àwọn tí wọ́n gbọ́ nípa mi, ń pè mí ní ẹni ibukun, àwọn tí wọ́n rí mi ń kan sáárá sí mi. Nítorí pé mò ń ran àwọn aláìní tí ń ké lọ́wọ́, ati àwọn aláìníbaba tí wọn kò ní olùrànlọ́wọ́. Ìre àwọn tí ń kú lọ mọ́ mi, mo sì mú kí opó kọrin ayọ̀. Mo fi òdodo bora bí aṣọ, ìdájọ́ òtítọ́ dàbí ẹ̀wù ati adé mi. Mo jẹ́ ojú fún afọ́jú, ati ẹsẹ̀ fún arọ. Mo jẹ́ baba fún talaka, mo gba ẹjọ́ àlejò rò. Mo ṣẹ́ ẹni ibi lápá, mo gba ẹni tí ó mú sílẹ̀.
Job 29:7-17 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbati mo jade là arin ilu lọ si ẹnu ibode, nigbati mo tẹ ìtẹ mi ni igboro. Nigbana ni awọn ọdọmọkunrin ri mi, nwọn si sapamọ́, awọn àgba dide duro. Awọn ọmọ-alade dakẹ ọ̀rọ sisọ, nwọn a si fi ọwọ wọn le ẹnu. Awọn ọlọla dakẹ, ahọn wọn si lẹmọ èrigi ẹnu wọn. Nitoripe eti gbọ́ ti emi, a si sure fun mi, oju si ri mi, on a jẹri mi. Nitoriti mo gba talaka ti nsọkun, ati alainibaba, ati alaini oluranlọwọ. Isure ẹniti o fẹrẹ iṣegbe wa si ori mi, emi si mu aiya opo kọrin fun ayọ̀. Emi si mu ododo wọ̀, o si bò mi lara; idajọ mi dabi aṣọ igunwa ati ade ọba. Mo ṣe oju fun afọju, ati ẹsẹ̀ fun amọkún. Mo ṣe baba fun talaka, ati ọ̀ran ti emi kò mọ̀, mo wadi rẹ̀ ri. Mo si ká ehin ẹ̀rẹkẹ enia buburu, mo si ja ohun ọdẹ na kuro li ehin rẹ̀.
Job 29:7-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Nígbà tí mo jáde la àárín ìlú lọ sí ẹnu ibodè, nígbà tí mo tẹ́ ìtẹ́ mi ní ìgboro, Nígbà náà ni àwọn ọmọkùnrin rí mi, wọ́n sì sápamọ́, àwọn àgbà dìde dúró ní ẹsẹ̀ wọn; Àwọn ọmọ-aládé dákẹ́ ọ̀rọ̀ sísọ, wọn a sì fi ọwọ́ wọn lé ẹnu; Àwọn ọlọ́lá dákẹ́, ahọ́n wọn sì lẹ̀ mọ́ èrìgì ẹnu wọn. Nígbà tí etí gbọ́, ó sì súre fún mi, àti nígbà tí ojú sì rí mi, ó jẹ́rìí mi; Nítorí mo gbà tálákà tí n fẹ́ ìrànlọ́wọ́, àti aláìní baba tí kò sí olùrànlọ́wọ́ fún un Ẹni tí ó ń kìlọ̀ súre fún mi, èmi sì mú àyà opó kọrin fún ayọ̀. Èmi sì mú òdodo wọ̀ bí aṣọ, ẹ̀tọ́ mi dàbí aṣọ ìgúnwà àti adé ọba. Mo ṣe ojú fún afọ́jú mo sì ṣe ẹsẹ̀ fún amúnkùn ún. Mo ṣe baba fún tálákà, mo ṣe ìwádìí ọ̀ràn àjèjì tí èmi kò mọ̀ rí. Mo sì ká eyín ẹ̀rẹ̀kẹ́ ènìyàn búburú, mo sì já ohun ọdẹ náà kúrò ní eyín rẹ̀.