Jesu wí fún wọn pé, “Ìbá jẹ́ pé Ọlọrun ni baba yín, ẹ̀ bá fẹ́ràn mi, nítorí ọ̀dọ̀ Ọlọrun ni mo ti wá. Nítorí kì í ṣe èmi ni mo rán ara mi wá, ṣugbọn òun ni ó rán mi. Nítorí kí ni ohun tí mò ń sọ fun yín kò fi ye yín? Ìdí rẹ̀ ni pé ara yín kò lè gba ọ̀rọ̀ mi. Láti ọ̀dọ̀ èṣù baba yín, ni ẹ ti wá. Ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ baba yín ni ẹ ń fẹ́ ṣe. Òun ní tirẹ̀, apànìyàn ni láti ìbẹ̀rẹ̀, ara rẹ̀ kọ òtítọ́ nítorí kò sí òtítọ́ ninu rẹ̀. Nígbà tí ó bá sọ̀rọ̀, irọ́ ni ó ń pa. Ọ̀rọ̀ ti ara rẹ̀ ní ń sọ. Òpùrọ́ ni, òun sì ni baba irọ́. Ṣugbọn nítorí pe òtítọ́ ni mò ń sọ, ẹ kò gbà mí gbọ́. Ta ni ninu yín tí ó ká ẹ̀ṣẹ̀ mọ́ mi lọ́wọ́ rí? Bí mo bá ń sọ òtítọ́, kí ló dé tí ẹ kò fi gbà mí gbọ́? Ẹni tí ó bá jẹ́ ti Ọlọrun yóo gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Ìdí tí ẹ kò fi gbọ́ ni èyí, nítorí ẹ kì í ṣe ẹni Ọlọrun.”
Kà JOHANU 8
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: JOHANU 8:42-47
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò