Joh 8:42-47
Joh 8:42-47 Bibeli Mimọ (YBCV)
Jesu wi fun wọn pe, Ibaṣepe Ọlọrun ni Baba nyin, ẹnyin iba fẹran mi: nitoriti emi ti ọdọ Ọlọrun jade, mo si wá: bẹ̃li emi kò si wá fun ara mi, ṣugbọn on li o rán mi. Ẽtiṣe ti ède mi kò fi yé nyin? nitori ẹ ko le gbọ́ ọ̀rọ mi ni. Ti eṣu baba nyin li ẹnyin iṣe, ifẹkufẹ baba nyin li ẹ si nfẹ ṣe. Apania li on iṣe lati atetekọṣe, ko si duro ni otitọ; nitoriti kò si otitọ ninu rẹ̀. Nigbati o ba nṣeke, ninu ohun tirẹ̀ li o nsọ, nitori eke ni, ati baba eke. Ṣugbọn nitori emi sọ otitọ fun nyin, ẹ kò si gbà mi gbọ́. Tani ninu nyin ti o ti idá mi li ẹbi ẹ̀ṣẹ? Bi mo ba nsọ otitọ ẽṣe ti ẹnyin kò fi gbà mi gbọ́? Ẹniti iṣe ti Ọlọrun, a ma gbọ́ ọ̀rọ Ọlọrun: nitori eyi li ẹnyin kò ṣe gbọ, nitori ẹnyin kì iṣe ti Ọlọrun.
Joh 8:42-47 Yoruba Bible (YCE)
Jesu wí fún wọn pé, “Ìbá jẹ́ pé Ọlọrun ni baba yín, ẹ̀ bá fẹ́ràn mi, nítorí ọ̀dọ̀ Ọlọrun ni mo ti wá. Nítorí kì í ṣe èmi ni mo rán ara mi wá, ṣugbọn òun ni ó rán mi. Nítorí kí ni ohun tí mò ń sọ fun yín kò fi ye yín? Ìdí rẹ̀ ni pé ara yín kò lè gba ọ̀rọ̀ mi. Láti ọ̀dọ̀ èṣù baba yín, ni ẹ ti wá. Ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ baba yín ni ẹ ń fẹ́ ṣe. Òun ní tirẹ̀, apànìyàn ni láti ìbẹ̀rẹ̀, ara rẹ̀ kọ òtítọ́ nítorí kò sí òtítọ́ ninu rẹ̀. Nígbà tí ó bá sọ̀rọ̀, irọ́ ni ó ń pa. Ọ̀rọ̀ ti ara rẹ̀ ní ń sọ. Òpùrọ́ ni, òun sì ni baba irọ́. Ṣugbọn nítorí pe òtítọ́ ni mò ń sọ, ẹ kò gbà mí gbọ́. Ta ni ninu yín tí ó ká ẹ̀ṣẹ̀ mọ́ mi lọ́wọ́ rí? Bí mo bá ń sọ òtítọ́, kí ló dé tí ẹ kò fi gbà mí gbọ́? Ẹni tí ó bá jẹ́ ti Ọlọrun yóo gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Ìdí tí ẹ kò fi gbọ́ ni èyí, nítorí ẹ kì í ṣe ẹni Ọlọrun.”
Joh 8:42-47 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Jesu wí fún wọn pé, “Ìbá ṣe pé Ọlọ́run ni Baba yín, ẹ̀yin ìbá fẹ́ràn mi: nítorí tí èmi ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run jáde, mo sì wá; bẹ́ẹ̀ ni èmi kò sì wá fún ara mi, ṣùgbọ́n òun ni ó rán mi. Èéṣe tí èdè mi kò fi yé yín? Nítorí ẹ kò lè gbọ́ ọ̀rọ̀ mi. Ti èṣù baba yin ni ẹ̀yin jẹ́, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ baba yín ni ẹ sì ń fẹ́ ṣe. Apànìyàn ni òun jẹ́ láti àtètèkọ́ṣe, kò sì dúró nínú òtítọ́; nítorí tí kò sí òtítọ́ nínú rẹ̀. Nígbà tí ó bá ń ṣèké, nínú ohun tirẹ̀ ni ó ń sọ nítorí èké ni, àti baba èké. Ṣùgbọ́n nítorí tí èmi ń sọ òtítọ́ fún yín, ẹ̀yin kò sì gbà mí gbọ́. Ta ni nínú yín tí ó ti dá mi lẹ́bi ẹ̀ṣẹ̀? Bí mo bá ń ṣọ òtítọ́, èéṣe tí ẹ̀yin kò fi gbà mí gbọ́? Ẹni tí ń ṣe ti Ọlọ́run, a máa gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: nítorí èyí ni ẹ̀yin kò ṣe gbọ́, nítorí ẹ̀yin kì í ṣe ti Ọlọ́run.”