JOHANU 7:1-30

JOHANU 7:1-30 YCE

Lẹ́yìn èyí, Jesu ń lọ káàkiri ní ilẹ̀ Galili nítorí kò fẹ́ máa káàkiri ilẹ̀ Judia mọ́, nítorí àwọn Juu ń wá ọ̀nà láti pa á. Ó fẹ́rẹ̀ tó àkókò àjọ̀dún àwọn Juu nígbà tí wọn ń ṣe Àjọ̀dún Ìpàgọ́ ní aṣálẹ̀. Àwọn arakunrin Jesu sọ fún un pé, “Kúrò níhìn-ín kí o lọ sí Judia, kí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ lè rí iṣẹ́ tí ò ń ṣe, nítorí kò sí ẹni tíí fi ohun tí ó bá ń ṣe pamọ́, bí ó bá fẹ́ kí àwọn eniyan mọ òun. Tí o bá ń ṣe nǹkan wọnyi, fi ara rẹ han aráyé.” (Àwọn arakunrin rẹ̀ kò gbà á gbọ́ ni wọ́n ṣe sọ bẹ́ẹ̀.) Jesu dá wọn lóhùn pé, “Àkókò tí ó wọ̀ fún mi kò ì tíì tó, ìgbà gbogbo ni ó wọ̀ fún ẹ̀yin. Ayé kò lè kórìíra yín, èmi ni wọ́n kórìíra, nítorí ẹ̀rí mi lòdì sí wọn nítorí pé iṣẹ́ wọn burú. Ẹ̀yin ẹ máa lọ sí ibi àjọ̀dún, èmi kò ní lọ sí ibi àjọ̀dún yìí nítorí àkókò tí ó wọ̀ fún mi kò ì tíì tó.” Nígbà tí ó wí báyìí tán, ó tún dúró ní ilẹ̀ Galili. Lẹ́yìn tí àwọn arakunrin Jesu ti lọ sí ibi àjọ̀dún náà, òun náà wá lọ. Ṣugbọn, kò lọ ní gbangba, yíyọ́ ni ó yọ́ lọ. Àwọn Juu bẹ̀rẹ̀ sí wá a níbi àjọ̀dún náà, wọ́n ń bèèrè pé, “Níbo ni ó wà?” Oríṣìíríṣìí ọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ ni àwọn eniyan ń sọ nípa rẹ̀. Àwọn kan ń sọ pé, “Eniyan rere ni.” Ṣugbọn àwọn mìíràn ń sọ pé, “Rárá o, ó ń tan àwọn eniyan jẹ ni.” Ṣugbọn wọn kò sọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ ní gbangba nítorí wọ́n bẹ̀rù àwọn Juu. Nígbà tí àjọ̀dún ti fẹ́rẹ̀ kọjá ìdajì, Jesu lọ sí Tẹmpili, ó ń kọ́ àwọn eniyan lẹ́kọ̀ọ́. Ẹnu ya àwọn Juu, wọ́n ń sọ pé, “Báwo ni eléyìí ti ṣe mọ ìwé tó báyìí nígbà tí kò lọ sí ilé-ìwé?” Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀kọ́ tèmi kì í ṣe ti ara mi, ti ẹni tí ó rán mi níṣẹ́ ni. Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ ṣe ìfẹ́ Ọlọrun, olúwarẹ̀ yóo mọ̀ bí ẹ̀kọ́ yìí bá jẹ́ ti Ọlọrun, tabi bí ó bá jẹ́ pé ti ara mi ni mò ń sọ. Ẹni tí ó bá ń sọ̀rọ̀ ti ara rẹ̀ ń wá ògo ti ara rẹ̀. Ṣugbọn ẹni tí ó bá ń wá ògo ẹni tí ó rán an níṣẹ́ jẹ́ olóòótọ́, kò sí aiṣododo ninu rẹ̀. Mo ṣebí Mose ti fun yín ní Òfin? Sibẹ kò sí ẹnìkan ninu yín tí ó ń ṣe ohun tí òfin wí. Nítorí kí ni ẹ ṣe ń wá ọ̀nà láti pa mí?” Àwọn eniyan dá a lóhùn pé, “Nǹkan kọ lù ọ́! Ta ni ń wá ọ̀nà láti pa ọ́?” Jesu dá wọn lóhùn pé, “Mo ṣe iṣẹ́ kan, ẹnu ya gbogbo yín. Nítorí pé Mose fun yín ní òfin ìkọlà, ẹ̀ ń kọlà fún eniyan ní Ọjọ́ Ìsinmi. Ṣugbọn òfin yìí kò bẹ̀rẹ̀ pẹlu Mose, àwọn baba-ńlá wa ni ó dá a sílẹ̀. Ẹ̀yin ń kọ ilà ní Ọjọ́ Ìsinmi kí ẹ má baà rú òfin Mose, ẹ wá ń bínú sí mi nítorí mo wo eniyan sàn ní Ọjọ́ Ìsinmi! Ẹ má wo ojú eniyan ṣe ìdájọ́, ṣugbọn ẹ máa ṣe ìdájọ́ ẹ̀tọ́.” Àwọn kan ninu àwọn ará Jerusalẹmu bẹ̀rẹ̀ sí sọ pé, “Ẹni tí wọ́n fẹ́ pa kọ́ yìí? Wò ó bí ó ti ń sọ̀rọ̀ ní gbangba tí wọn kò sì sọ ohunkohun sí i. Àbí àwọn aláṣẹ ti mọ̀ dájú pé òun ni Mesaya ni? Ṣugbọn eléyìí kò lè jẹ́ Mesaya, nítorí a mọ ibi tí ó ti wá. Nígbà tí Mesaya bá dé, ẹnikẹ́ni kò ní mọ ibi tí ó ti wá.” Ni Jesu bá kígbe sókè bí ó ti ń kọ́ àwọn eniyan ninu Tẹmpili. Ó ní, “Òtítọ́ ni pe ẹ mọ̀ mí, ẹ sì mọ ibi tí mo ti wá. Ṣugbọn kì í ṣe èmi ni mo rán ara mi wá, olóòótọ́ ni ẹni tí ó rán mi, tí ẹ̀yin kò mọ̀. Èmi mọ̀ ọ́n, nítorí láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni mo ti wá, òun ni ó sì rán mi níṣẹ́.” Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí wá ọ̀nà láti mú un, ṣugbọn ẹnikẹ́ni kò fi ọwọ́ kàn án nítorí àkókò rẹ̀ kò ì tíì tó.

Àwọn Fídíò tó Jẹmọ́ ọ