Joh 7:1-30

Joh 7:1-30 Bibeli Mimọ (YBCV)

LẸHIN nkan wọnyi Jesu nrìn ni Galili: nitoriti kò fẹ rìn ni Judea, nitori awọn Ju nwá ọ̀na ati pa a. Ajọ awọn Ju ti iṣe ajọ ìpagọ́, sunmọ etile tan. Nitorina awọn arakunrin rẹ̀ wi fun u pe, Lọ kuro nihinyi, ki o si lọ si Judea, ki awọn ọmọ-ẹhin rẹ pẹlu ki o le ri iṣẹ rẹ ti iwọ nṣe. Nitoripe kò si ẹnikẹni ti iṣe ohunkohun nikọ̀kọ, ti on tikararẹ̀ si nfẹ ki a mọ̀ on ni gbangba. Bi iwọ ba nṣe nkan wọnyi, fi ara rẹ hàn fun araiye. Nitoripe awọn arakunrin rẹ̀ kò tilẹ gbà a gbọ́. Nigbana ni Jesu wi fun wọn pe, Akokò temi kò ti ide: ṣugbọn akokò ti nyin ni imura tan nigbagbogbo. Aiye kò le korira nyin; ṣugbọn emi li o korira, nitoriti mo jẹri gbe e pe, iṣẹ rẹ̀ buru. Ẹnyin ẹ gòke lọ si ajọ yi: emi kì yio ti igoke lọ si ajọ yi; nitoriti akokò temi kò ti ide. Nigbati o ti sọ nkan wọnyi fun wọn tan, o duro ni Galili sibẹ̀. Ṣugbọn nigbati awọn arakunrin rẹ̀ gòke lọ tan, nigbana li on si gòke lọ si ajọ na pẹlu, kì iṣe ni gbangba, ṣugbọn bi ẹnipe nikọ̀kọ. Nigbana li awọn Ju si nwá a kiri nigba ajọ, wipe, Nibo li o wà? Kikùn pipọ si wà larin awọn ijọ enia nitori rẹ̀: nitori awọn kan wipe, Enia rere ni iṣe: awọn miran wipe, Bẹ̃kọ; ṣugbọn o ntàn enia jẹ ni. Ṣugbọn kò si ẹnikan ti o sọ̀rọ rẹ̀ ni gbangba nitori ìbẹru awọn Ju. Nigbati ajọ de arin Jesu gòke lọ si tẹmpili o si nkọ́ni. Ẹnu si yà awọn Ju, nwọn wipe, ọkunrin yi ti ṣe mọ̀ iwe, nigbati ko kọ́ ẹ̀kọ́? Nitorina Jesu da wọn lohùn, o si wipe, Ẹkọ́ mi ki iṣe temi, bikoṣe ti ẹniti o rán mi. Bi ẹnikẹni ba fẹ lati ṣe ifẹ rẹ̀, yio mọ̀ niti ẹkọ́ na, bi iba ṣe ti Ọlọrun, tabi bi emi ba nsọ ti ara mi. Ẹniti nsọ̀ ti ara rẹ̀ nwá ogo ara rẹ̀: ṣugbọn ẹniti nwá ogo ẹniti o rán a, on li olõtọ, kò si si aiṣododo ninu rẹ̀. Mose kò ha fi ofin fun yin, kò si ẹnikẹni ninu nyin ti o pa ofin na mọ́? Ẽṣe ti ẹnyin fi nwá ọ̀na lati pa mi? Ijọ enia dahùn nwọn si wipe, Iwọ li ẹmi èṣu: tani nwá ọ̀na lati pa ọ? Jesu dahùn o si wi fun wọn pe, Kìki iṣẹ àmi kan ni mo ṣe, ẹnu si yà gbogbo nyin. Nitori eyi ni Mose fi ìkọlà fun nyin (kì iṣe nitoriti iṣe ti Mose, ṣugbọn ti awọn baba); nitorina ẹ si nkọ enia ni ilà li ọjọ isimi. Bi enia ba ngbà ikọla li ọjọ isimi, ki a ma bà rú ofin Mose, ẹ ha ti ṣe mbinu si mi, nitori mo mu enia kan larada ṣáṣa li ọjọ isimi? Ẹ máṣe idajọ nipa ode ara, ṣugbọn ẹ mã ṣe idajọ ododo. Nigbana li awọn kan ninu awọn ara Jerusalemu wipe, Ẹniti nwọn nwá ọ̀na ati pa kọ́ yi? Si wo o, o nsọrọ ni gbangba, nwọn kò si wi nkankan si i. Awọn olori ha mọ̀ nitõtọ pe, eyi ni Kristi na? Ṣugbọn awa mọ̀ ibi ti ọkunrin yi gbé ti wá: ṣugbọn nigbati Kristi ba de, kò si ẹniti yio mọ̀ ibiti o gbé ti wà. Nigbana ni Jesu kigbe ni tẹmpili bi o ti nkọ́ni, wipe, Ẹnyin mọ̀ mi, ẹ si mọ̀ ibiti mo ti wá: emi ko si wá fun ara mi, ṣugbọn olõtọ li ẹniti o rán mi, ẹniti ẹnyin kò mọ̀. Ṣugbọn emi mọ̀ ọ: nitoripe lọdọ rẹ̀ ni mo ti wá, on li o si rán mi. Nitorina nwọn nwá ọ̀na ati mú u: ṣugbọn kò si ẹnikan ti o gbé ọwọ́ le e, nitoriti wakati rẹ̀ kò ti ide.

Joh 7:1-30 Yoruba Bible (YCE)

Lẹ́yìn èyí, Jesu ń lọ káàkiri ní ilẹ̀ Galili nítorí kò fẹ́ máa káàkiri ilẹ̀ Judia mọ́, nítorí àwọn Juu ń wá ọ̀nà láti pa á. Ó fẹ́rẹ̀ tó àkókò àjọ̀dún àwọn Juu nígbà tí wọn ń ṣe Àjọ̀dún Ìpàgọ́ ní aṣálẹ̀. Àwọn arakunrin Jesu sọ fún un pé, “Kúrò níhìn-ín kí o lọ sí Judia, kí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ lè rí iṣẹ́ tí ò ń ṣe, nítorí kò sí ẹni tíí fi ohun tí ó bá ń ṣe pamọ́, bí ó bá fẹ́ kí àwọn eniyan mọ òun. Tí o bá ń ṣe nǹkan wọnyi, fi ara rẹ han aráyé.” (Àwọn arakunrin rẹ̀ kò gbà á gbọ́ ni wọ́n ṣe sọ bẹ́ẹ̀.) Jesu dá wọn lóhùn pé, “Àkókò tí ó wọ̀ fún mi kò ì tíì tó, ìgbà gbogbo ni ó wọ̀ fún ẹ̀yin. Ayé kò lè kórìíra yín, èmi ni wọ́n kórìíra, nítorí ẹ̀rí mi lòdì sí wọn nítorí pé iṣẹ́ wọn burú. Ẹ̀yin ẹ máa lọ sí ibi àjọ̀dún, èmi kò ní lọ sí ibi àjọ̀dún yìí nítorí àkókò tí ó wọ̀ fún mi kò ì tíì tó.” Nígbà tí ó wí báyìí tán, ó tún dúró ní ilẹ̀ Galili. Lẹ́yìn tí àwọn arakunrin Jesu ti lọ sí ibi àjọ̀dún náà, òun náà wá lọ. Ṣugbọn, kò lọ ní gbangba, yíyọ́ ni ó yọ́ lọ. Àwọn Juu bẹ̀rẹ̀ sí wá a níbi àjọ̀dún náà, wọ́n ń bèèrè pé, “Níbo ni ó wà?” Oríṣìíríṣìí ọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ ni àwọn eniyan ń sọ nípa rẹ̀. Àwọn kan ń sọ pé, “Eniyan rere ni.” Ṣugbọn àwọn mìíràn ń sọ pé, “Rárá o, ó ń tan àwọn eniyan jẹ ni.” Ṣugbọn wọn kò sọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ ní gbangba nítorí wọ́n bẹ̀rù àwọn Juu. Nígbà tí àjọ̀dún ti fẹ́rẹ̀ kọjá ìdajì, Jesu lọ sí Tẹmpili, ó ń kọ́ àwọn eniyan lẹ́kọ̀ọ́. Ẹnu ya àwọn Juu, wọ́n ń sọ pé, “Báwo ni eléyìí ti ṣe mọ ìwé tó báyìí nígbà tí kò lọ sí ilé-ìwé?” Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀kọ́ tèmi kì í ṣe ti ara mi, ti ẹni tí ó rán mi níṣẹ́ ni. Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ ṣe ìfẹ́ Ọlọrun, olúwarẹ̀ yóo mọ̀ bí ẹ̀kọ́ yìí bá jẹ́ ti Ọlọrun, tabi bí ó bá jẹ́ pé ti ara mi ni mò ń sọ. Ẹni tí ó bá ń sọ̀rọ̀ ti ara rẹ̀ ń wá ògo ti ara rẹ̀. Ṣugbọn ẹni tí ó bá ń wá ògo ẹni tí ó rán an níṣẹ́ jẹ́ olóòótọ́, kò sí aiṣododo ninu rẹ̀. Mo ṣebí Mose ti fun yín ní Òfin? Sibẹ kò sí ẹnìkan ninu yín tí ó ń ṣe ohun tí òfin wí. Nítorí kí ni ẹ ṣe ń wá ọ̀nà láti pa mí?” Àwọn eniyan dá a lóhùn pé, “Nǹkan kọ lù ọ́! Ta ni ń wá ọ̀nà láti pa ọ́?” Jesu dá wọn lóhùn pé, “Mo ṣe iṣẹ́ kan, ẹnu ya gbogbo yín. Nítorí pé Mose fun yín ní òfin ìkọlà, ẹ̀ ń kọlà fún eniyan ní Ọjọ́ Ìsinmi. Ṣugbọn òfin yìí kò bẹ̀rẹ̀ pẹlu Mose, àwọn baba-ńlá wa ni ó dá a sílẹ̀. Ẹ̀yin ń kọ ilà ní Ọjọ́ Ìsinmi kí ẹ má baà rú òfin Mose, ẹ wá ń bínú sí mi nítorí mo wo eniyan sàn ní Ọjọ́ Ìsinmi! Ẹ má wo ojú eniyan ṣe ìdájọ́, ṣugbọn ẹ máa ṣe ìdájọ́ ẹ̀tọ́.” Àwọn kan ninu àwọn ará Jerusalẹmu bẹ̀rẹ̀ sí sọ pé, “Ẹni tí wọ́n fẹ́ pa kọ́ yìí? Wò ó bí ó ti ń sọ̀rọ̀ ní gbangba tí wọn kò sì sọ ohunkohun sí i. Àbí àwọn aláṣẹ ti mọ̀ dájú pé òun ni Mesaya ni? Ṣugbọn eléyìí kò lè jẹ́ Mesaya, nítorí a mọ ibi tí ó ti wá. Nígbà tí Mesaya bá dé, ẹnikẹ́ni kò ní mọ ibi tí ó ti wá.” Ni Jesu bá kígbe sókè bí ó ti ń kọ́ àwọn eniyan ninu Tẹmpili. Ó ní, “Òtítọ́ ni pe ẹ mọ̀ mí, ẹ sì mọ ibi tí mo ti wá. Ṣugbọn kì í ṣe èmi ni mo rán ara mi wá, olóòótọ́ ni ẹni tí ó rán mi, tí ẹ̀yin kò mọ̀. Èmi mọ̀ ọ́n, nítorí láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni mo ti wá, òun ni ó sì rán mi níṣẹ́.” Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí wá ọ̀nà láti mú un, ṣugbọn ẹnikẹ́ni kò fi ọwọ́ kàn án nítorí àkókò rẹ̀ kò ì tíì tó.

Joh 7:1-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí Jesu ń rìn ní Galili: nítorí tí kò fẹ́ rìn ní Judea, nítorí àwọn Júù ń wá a láti pa. Àjọ àwọn Júù tí í ṣe àjọ àgọ́ súnmọ́ etílé tan. Nítorí náà, àwọn arákùnrin rẹ̀ wí fún un pé, “Lọ kúrò níhìn-ín-yìí, kí o sì lọ sí Judea, kí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ pẹ̀lú lè fi iṣẹ́ rẹ hàn fún aráyé. Nítorí pé kò sí ẹnikẹ́ni tí í ṣe ohunkóhun níkọ̀kọ̀, tí òun tìkára rẹ̀ sì ń fẹ́ kí a mọ òun ní gbangba. Bí ìwọ bá ń ṣe nǹkan wọ̀nyí, fi ara rẹ hàn fún aráyé.” Nítorí pé àwọn arákùnrin rẹ̀ pàápàá kò tilẹ̀ gbà á gbọ́. Nítorí náà ni Jesu wí fún wọn pé, “Àkókò gan an fún mi kò tí ì dé; fún ẹ̀yin, gbogbo àkókò ni ó dára fún yín. Ayé kò lè kórìíra yín; ṣùgbọ́n èmi ni ó kórìíra, nítorí tí mo jẹ́rìí gbé é pé, iṣẹ́ rẹ̀ burú. Ẹ̀yin ẹ gòkè lọ sí àjọ yìí: èmi kì yóò tí ì gòkè lọ sí àjọ yìí; nítorí tí àkókò mi kò ì tí ì dé.” Nígbà tí ó ti sọ nǹkan wọ̀nyí fún wọn tan, ó dúró ní Galili síbẹ̀. Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn arákùnrin rẹ̀ gòkè lọ tan, nígbà náà ni òun sì gòkè lọ sí àjọ náà pẹ̀lú, kì í ṣe ní gbangba, ṣùgbọ́n bí ẹni pé níkọ̀kọ̀. Nígbà náà ni àwọn Júù sì ń wá a kiri nígbà àjọ wí pé, “Níbo ni ó wà?” Ìkùnsínú púpọ̀ sì wà láàrín àwọn ìjọ ènìyàn nítorí rẹ̀: nítorí àwọn kan wí pé, “Ènìyàn rere ní í ṣe.” Àwọn mìíràn wí pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́, ṣùgbọ́n òun ń tan ènìyàn jẹ ni.” Ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan tí ó sọ̀rọ̀ rẹ̀ ní gbangba nítorí ìbẹ̀rù àwọn Júù. Nígbà tí àjọ dé àárín; Jesu gòkè lọ sí tẹmpili ó sì ń kọ́ni. Ẹnu sì ya àwọn Júù, wọ́n wí pé, “Ọkùnrin yìí ti ṣe mọ ìwé, nígbà tí kò kọ́ ẹ̀kọ́?” Jesu dáhùn, ó sì wí pé, “Ẹ̀kọ́ mi kì í ṣe tèmi, bí kò ṣe ti ẹni tí ó rán mi. Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀ yóò mọ̀ ní ti ẹ̀kọ́ náà, bí ìbá ṣe ti Ọlọ́run, tàbí bí èmi bá sọ ti ara mi. Ẹni tí ń sọ ti ara rẹ̀ ń wá ògo ara rẹ̀: ṣùgbọ́n ẹni tí ń wá ògo ẹni tí ó rán an, òun ni olóòtítọ́, kò sì sí àìṣòdodo nínú rẹ̀. Mose kò ha fi òfin fún yín, kò sí ẹnikẹ́ni nínú yín tí ó pa òfin náà mọ́? Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń wá ọ̀nà láti pa mí?” Ìjọ ènìyàn dáhùn, wọ́n sì wí pé, “Ìwọ ní ẹ̀mí èṣù: Ta ni ń wá ọ̀nà láti pa ọ́?” Jesu dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Kìkì iṣẹ́ ààmì kan ni mo ṣe, ẹnu sì ya gbogbo yín. Síbẹ̀, nítorí pé Mose fi ìkọlà fún yín (kò tilẹ̀ kúkú wá láti ọ̀dọ̀ Mose bí kò ṣe láti ọ̀dọ̀ àwọn baba ńlá yín); nítorí náà ẹ sì ń kọ ènìyàn ní ilà ní ọjọ́ ìsinmi. Bí ènìyàn bá ń gba ìkọlà ní ọjọ́ ìsinmi, kí a má ba à rú òfin Mose, ẹ ha ti ṣe ń bínú sí mi, nítorí mo mú ènìyàn kan láradá ní ọjọ́ ìsinmi? Ẹ má ṣe ìdájọ́ nípa ti ara, ṣùgbọ́n ẹ máa ṣe ìdájọ́ òdodo.” Nígbà náà ni àwọn kan nínú àwọn ará Jerusalẹmu wí pé, “ẹni tí wọ́n ń wá ọ̀nà láti pa kọ́ yìí? Sì wò ó, ó ń sọ̀rọ̀ ní gbangba, wọn kò sì wí nǹkan kan sí i. Àwọn olórí ha mọ̀ nítòótọ́ pé, èyí ni Kristi náà? Ṣùgbọ́n àwa mọ ibi tí ọkùnrin yí gbé ti wá: ṣùgbọ́n nígbà tí Kristi bá dé, kò sí ẹni tí yóò mọ ibi tí ó gbé ti wá.” Nígbà náà ni Jesu kígbe ní tẹmpili bí ó ti ń kọ́ni, wí pé, “Ẹ̀yin mọ̀ mí, ẹ sì mọ ibi tí mo ti wá: èmi kò sì wá fún ara mi, ṣùgbọ́n olóòtítọ́ ni ẹni tí ó rán mi, ẹni tí ẹ̀yin kò mọ̀. Ṣùgbọ́n èmi mọ̀ ọ́n: nítorí pé lọ́dọ̀ rẹ̀ ni mo ti wá, òun ni ó rán mi.” Nítorí náà wọ́n ń wá ọ̀nà à ti mú un: ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan tí ó gbé ọwọ́ lé e, nítorí tí wákàtí rẹ̀ kò tí ì dé.