JOHANU 12:1-7

JOHANU 12:1-7 YCE

Nígbà tí Àjọ̀dún Ìrékọjá ku ọjọ́ mẹfa, Jesu lọ sí Bẹtani níbi tí Lasaru wà, ẹni tí ó kú, tí Jesu jí dìde. Wọ́n se àsè kan fún un níbẹ̀. Mata ń ṣe ètò gbígbé oúnjẹ kalẹ̀; Lasaru wà ninu àwọn tí ó ń bá Jesu jẹun. Nígbà náà ni Maria dé, ó mú ìgò kékeré kan lọ́wọ́. Ojúlówó òróró ìpara kan, olówó iyebíye ni ó wà ninu ìgò náà. Ó bá tú òróró yìí sí Jesu lẹ́sẹ̀, ó ń fi irun orí rẹ̀ nù ún. Òórùn òróró náà bá gba gbogbo ilé. Judasi Iskariotu, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ẹni tí yóo fi í lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́, sọ pé, “Kí ló dé tí a kò ta òróró yìí ní nǹkan bí ọọdunrun (300) owó fadaka, kí á pín in fún àwọn talaka?” Kì í ṣe nítorí pé ó bìkítà fún àwọn talaka ni ó ṣe sọ bẹ́ẹ̀; nítorí pé ó jẹ́ olè ni. Òun ni akápò; a máa jí ninu owó tí wọn bá fi pamọ́. Jesu dá a lóhùn pé, “Fi í sílẹ̀! Jẹ́ kí ó fi pamọ́ di ọjọ́ ìsìnkú mi.

Àwọn fídíò fún JOHANU 12:1-7