Joh 12:1-7
Joh 12:1-7 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí Àjọ̀dún Ìrékọjá ku ọjọ́ mẹfa, Jesu lọ sí Bẹtani níbi tí Lasaru wà, ẹni tí ó kú, tí Jesu jí dìde. Wọ́n se àsè kan fún un níbẹ̀. Mata ń ṣe ètò gbígbé oúnjẹ kalẹ̀; Lasaru wà ninu àwọn tí ó ń bá Jesu jẹun. Nígbà náà ni Maria dé, ó mú ìgò kékeré kan lọ́wọ́. Ojúlówó òróró ìpara kan, olówó iyebíye ni ó wà ninu ìgò náà. Ó bá tú òróró yìí sí Jesu lẹ́sẹ̀, ó ń fi irun orí rẹ̀ nù ún. Òórùn òróró náà bá gba gbogbo ilé. Judasi Iskariotu, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ẹni tí yóo fi í lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́, sọ pé, “Kí ló dé tí a kò ta òróró yìí ní nǹkan bí ọọdunrun (300) owó fadaka, kí á pín in fún àwọn talaka?” Kì í ṣe nítorí pé ó bìkítà fún àwọn talaka ni ó ṣe sọ bẹ́ẹ̀; nítorí pé ó jẹ́ olè ni. Òun ni akápò; a máa jí ninu owó tí wọn bá fi pamọ́. Jesu dá a lóhùn pé, “Fi í sílẹ̀! Jẹ́ kí ó fi pamọ́ di ọjọ́ ìsìnkú mi.
Joh 12:1-7 Bibeli Mimọ (YBCV)
NITORINA nigbati ajọ irekọja kù ijọ mẹfa, Jesu wá si Betani, nibiti Lasaru wà, ẹniti o ti kú, ti Jesu ji dide kuro ninu okú. Nwọn si se ase-alẹ fun u nibẹ: Marta si nṣe iranṣẹ: ṣugbọn Lasaru jẹ ọkan ninu awọn ti o joko nibi tabili pẹlu rẹ̀. Nigbana ni Maria mu ororo ikunra nardi, oṣuwọn litra kan, ailabùla, olowo iyebiye, o si nfi kùn Jesu li ẹsẹ, o si nfi irun ori rẹ̀ nù ẹsẹ rẹ̀ nù: ile si kún fun õrùn ikunra na. Nigbana li ọkan ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, Judasi Iskariotu, ọmọ Simoni, ẹniti yio fi i hàn, wipe, Ẽṣe ti a kò tà ororo ikunra yi ni ọ̃durun owo idẹ ki a si fifun awọn talakà? Ṣugbọn o wi eyi, ki iṣe nitoriti o náni awọn talakà; ṣugbọn nitoriti iṣe olè, on li o si ni àpo, a si ma gbé ohun ti a fi sinu rẹ̀. Nigbana ni Jesu wipe, Ẹ jọwọ rẹ̀, o ṣe e silẹ dè ọjọ sisinku mi.
Joh 12:1-7 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí Àjọ̀dún Ìrékọjá ku ọjọ́ mẹfa, Jesu lọ sí Bẹtani níbi tí Lasaru wà, ẹni tí ó kú, tí Jesu jí dìde. Wọ́n se àsè kan fún un níbẹ̀. Mata ń ṣe ètò gbígbé oúnjẹ kalẹ̀; Lasaru wà ninu àwọn tí ó ń bá Jesu jẹun. Nígbà náà ni Maria dé, ó mú ìgò kékeré kan lọ́wọ́. Ojúlówó òróró ìpara kan, olówó iyebíye ni ó wà ninu ìgò náà. Ó bá tú òróró yìí sí Jesu lẹ́sẹ̀, ó ń fi irun orí rẹ̀ nù ún. Òórùn òróró náà bá gba gbogbo ilé. Judasi Iskariotu, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ẹni tí yóo fi í lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́, sọ pé, “Kí ló dé tí a kò ta òróró yìí ní nǹkan bí ọọdunrun (300) owó fadaka, kí á pín in fún àwọn talaka?” Kì í ṣe nítorí pé ó bìkítà fún àwọn talaka ni ó ṣe sọ bẹ́ẹ̀; nítorí pé ó jẹ́ olè ni. Òun ni akápò; a máa jí ninu owó tí wọn bá fi pamọ́. Jesu dá a lóhùn pé, “Fi í sílẹ̀! Jẹ́ kí ó fi pamọ́ di ọjọ́ ìsìnkú mi.
Joh 12:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí náà, nígbà tí àjọ ìrékọjá ku ọjọ́ mẹ́fà, Jesu wá sí Betani, níbi tí Lasaru wà, ẹni tí ó ti kú, tí Jesu jí dìde kúrò nínú òkú. Wọ́n sì ṣe àsè alẹ́ fún un níbẹ̀: Marta sì ń ṣe ìránṣẹ́: ṣùgbọ́n Lasaru Jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn tí ó jókòó níbi tábìlì rẹ̀. Nígbà náà ni Maria mú òróró ìkunra nadi, òṣùwọ̀n lítà kan, àìlábùlà, olówó iyebíye, ó sì ń fi kun Jesu ní ẹsẹ̀, ó sì ń fi irun orí rẹ̀ nu ẹsẹ̀ rẹ̀ nù. Ilé sì kún fún òórùn ìkunra náà. Nígbà náà ni ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, Judasi Iskariotu, ọmọ Simoni ẹni tí yóò fi í hàn, wí pé, “Èéṣe tí a kò ta òróró ìkunra yìí ní ọ̀ọ́dúnrún owó idẹ kí a sì fi fún àwọn tálákà?” Ṣùgbọ́n ó wí èyí, kì í ṣe nítorí tí ó náání àwọn tálákà; ṣùgbọ́n nítorí tí ó jẹ́ olè, òun ni ó ni àpò, a sì máa jí ohun tí a fi sínú rẹ̀ láti fi ran ara rẹ lọ́wọ́. Nígbà náà ni Jesu wí pé, “Ẹ fi í sílẹ̀, ó ṣe é sílẹ̀ de ọjọ́ ìsìnkú mi.