JOHANU 1:29-51

JOHANU 1:29-51 YCE

Ní ọjọ́ keji, Johanu rí Jesu tí ó ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó ní, “Wo ọ̀dọ́ aguntan Ọlọrun, tí ó kó ẹ̀ṣẹ̀ aráyé lọ. Òun ni mo sọ nípa rẹ̀ pé, ‘Ẹnìkan ń bọ̀ lẹ́yìn mi, ẹni tí ó jù mí lọ, nítorí ó ti wà kí á tó bí mi.’ Èmi alára kò mọ̀ ọ́n, ṣugbọn kí á lè fi í han Israẹli ni mo ṣe wá, tí mò ń fi omi ṣe ìwẹ̀mọ́.” Johanu tún jẹ́rìí pé, “Mo ti rí Ẹ̀mí tí ó sọ̀kalẹ̀ bí àdàbà láti ọ̀run tí ó bà lé e, tí ó sì ń bá a gbé. Èmi alára kò mọ̀ ọ́n, ṣugbọn ẹni tí ó rán mi láti máa ṣe ìrìbọmi ti sọ fún mi pé, ẹni tí mo bá rí tí Ẹ̀mí bá sọ̀kalẹ̀ lé lórí, tí ó bá ń bá a gbé, òun ni ẹni tí ó ń fi Ẹ̀mí Mímọ́ ṣe ìwẹ̀mọ́. Mo ti rí i, mo wá ń jẹ́rìí pé òun ni Ọmọ Ọlọrun.” Ní ọjọ́ keji, bí Johanu ati àwọn meji ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ti tún dúró, ó tẹjú mọ́ Jesu bí ó ti ń kọjá lọ, ó ní, “Wo ọ̀dọ́ aguntan Ọlọrun.” Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn meji náà gbọ́, wọ́n tẹ̀lé Jesu. Nígbà tí Jesu yipada, tí ó rí wọn tí wọn ń tẹ̀lé òun, ó bi wọn pé, “Kí ni ẹ̀ ń wá?” Wọ́n ní, “Rabi, níbo ni ò ń gbé?” (Ìtumọ̀ “Rabi” ni “Olùkọ́ni.”) Ó ní, “Ẹ ká lọ, ẹ óo sì rí i.” Wọ́n bá bá a lọ, wọ́n rí ibi tí ó ń gbé. Wọ́n dúró lọ́dọ̀ rẹ̀ ní ọjọ́ náà, nítorí ó ti tó bí nǹkan agogo mẹrin ìrọ̀lẹ́. Ọ̀kan ninu àwọn meji tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ Johanu, tí ó tẹ̀lé Jesu ni Anderu arakunrin Simoni Peteru. Lẹsẹkẹsẹ, Anderu rí Simoni arakunrin rẹ̀, ó sọ fún un pé, “Àwa ti rí Mesaya!” (Ìtumọ̀ “Mesaya” ni “Kristi.”) Ó bá mú un lọ sọ́dọ̀ Jesu. Jesu tẹjú mọ́ ọn, ó ní, “Ìwọ ni Simoni ọmọ Johanu; Kefa ni a óo máa pè ọ́.” (Ìtumọ̀ “Kefa” ni “àpáta”, “Peteru” ni ní èdè Giriki.) Ní ọjọ́ keji, bí Jesu ti fẹ́ máa lọ sí ilẹ̀ Galili, ó rí Filipi. Ó sọ fún un pé, “Máa tẹ̀lé mi.” Ará Bẹtisaida, ìlú Anderu ati ti Peteru, ni Filipi. Filipi wá rí Nataniẹli, ó wí fún un pé, “Àwa ti rí ẹni tí Mose kọ nípa rẹ̀ ninu Ìwé Òfin, tí àwọn wolii tún kọ nípa rẹ̀, Jesu ọmọ Josẹfu ará Nasarẹti.” Nataniẹli bi í pé, “Ṣé nǹkan rere kan lè ti Nasarẹti wá?” Filipi dá a lóhùn pé, “Wá wò ó.” Jesu rí Nataniẹli bí ó ti ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sọ nípa rẹ̀ pé, “Wo ọmọlúwàbí, ọmọ Israẹli tí kò ní ẹ̀tàn ninu.” Nataniẹli bi í pé, “Níbo ni o ti mọ̀ mí?” Jesu dá a lóhùn pé, “Kí Filipi tó pè ọ́, nígbà tí o wà ní abẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́, mo ti rí ọ.” Nataniẹli wí fún un pé, “Olùkọ́ni, ìwọ ni ọmọ Ọlọrun, ìwọ ni ọba Israẹli.” Jesu wí fún un pé, “Nítorí mo wí fún ọ pé mo rí ọ ní abẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ ni o ṣe gbàgbọ́? Ìwọ yóo rí ohun tí ó jù yìí lọ.” Ó tún wí fún un pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, ẹ óo rí ọ̀run tí yóo pínyà, ẹ óo wá rí àwọn angẹli Ọlọrun tí wọn óo máa gòkè, tí wọn óo tún máa sọ̀kalẹ̀ sórí Ọmọ-Eniyan.”

Àwọn Fídíò tó Jẹmọ́ ọ