JEREMAYA 47
47
Iṣẹ́ tí OLUWA Rán sí Àwọn Ará Filistia
1OLUWA bá Jeremaya wolii sọ̀rọ̀ nípa Filistini kí Farao tó ṣẹgun Gasa, 2Ó ní,
“Wò ó, omi kan ń ru bọ̀ láti ìhà àríwá,
yóo di àgbàrá tí ó lágbára;
yóo ya bo ilẹ̀ yìí ati gbogbo ohun tí ó wà lórí rẹ̀,
yóo ya bo ìlú yìí pẹlu, ati àwọn tí wọn ń gbé inú rẹ̀.
Àwọn eniyan yóo kígbe: gbogbo àwọn ará ìlú yóo sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn.
3Nígbà tí pátákò ẹsẹ̀ ẹṣin bá ń dún,
tí àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ bá ń sáré,
tí ẹsẹ̀ àwọn kẹ̀kẹ́ ogun sì ń pariwo,
Àwọn baba kò ní lè wo àwọn ọmọ wọn lẹ́yìn pé kí àwọn fà wọ́n,
nítorí pé ọwọ́ wọn yóo rọ;
4nítorí ọjọ́ tí ń bọ̀, tí yóo jẹ́ ọjọ́ ìparun gbogbo àwọn ará Filistia,
ọjọ́ tí a óo run gbogbo àwọn olùrànlọ́wọ́ tí ó kù fún Tire ati Sidoni.
Nítorí pé OLUWA yóo pa àwọn ará Filistia run,
àwọn tí wọ́n kù ní etí òkun ní Kafitori.
5Ìbànújẹ́ ti dé bá Gasa, Aṣikeloni ti parun.
Ẹ̀yin tí ẹ kù lára àwọn ọmọ Anakimu, ẹ óo ti fi ìbànújẹ́ ṣá ara yín lọ́gbẹ́ pẹ́ tó?
6Ẹ̀yin ń bèèrè pé, ‘Ìwọ idà OLUWA,
yóo ti pẹ́ tó kí o tó sinmi?
Pada sinu àkọ̀ rẹ, máa sinmi kí o sì dúró jẹ́ẹ́.’
7Ṣugbọn idà OLUWA ṣe lè dákẹ́ jẹ́ẹ́, nígbà tí Oluwa fún un ní iṣẹ́ láti ṣe?#Ais 14:9-31; Isi 25:15-17; Joẹl 3:4-8; Amos 1:6-8; Sef 2:4-7; Sak 9:5-7
OLUWA ti pàṣẹ fún un láti kọlu Aṣikeloni, ati àwọn ìlú etí òkun.”
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
JEREMAYA 47: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010