OLUWA bá Jeremaya wolii sọ̀rọ̀ nípa Filistini kí Farao tó ṣẹgun Gasa, Ó ní,
“Wò ó, omi kan ń ru bọ̀ láti ìhà àríwá,
yóo di àgbàrá tí ó lágbára;
yóo ya bo ilẹ̀ yìí ati gbogbo ohun tí ó wà lórí rẹ̀,
yóo ya bo ìlú yìí pẹlu, ati àwọn tí wọn ń gbé inú rẹ̀.
Àwọn eniyan yóo kígbe: gbogbo àwọn ará ìlú yóo sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn.