JEREMAYA 29

29
Lẹta Jeremaya sí Àwọn Tí Ogun Kó Lọ sí Babiloni
1Jeremaya wolii kọ ìwé kan ranṣẹ láti Jerusalẹmu, ó kọ ọ́ sí àwọn àgbààgbà láàrin àwọn tí a kó ní ìgbèkùn; ati sí àwọn alufaa ati àwọn wolii, ati gbogbo àwọn eniyan tí Nebukadinesari kó ní ìgbèkùn lọ sí Babiloni, láti Jerusalẹmu. 2Ṣáájú àkókò yìí, ọba Jehoiakini ati ìyá ọba ti kúrò ní Jerusalẹmu, pẹlu àwọn ìwẹ̀fà ati àwọn ìjòyè Juda ati ti Jerusalẹmu, ati àwọn oníṣẹ́ ọwọ́ ati àwọn oníṣẹ́-ọnà. 3Ó fi ìwé náà rán Elasa, ọmọ Ṣafani ati Gemaraya, ọmọ Hilikaya: àwọn tí Sedekaya, ọba Juda, rán lọ sọ́dọ̀ Nebukadinesari, ọba Babiloni.#2A. Ọba 24:12-16; 2Kron 36:10
4Ó ní, “OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní kí n sọ fún gbogbo àwọn tí a ti kó ní ìgbèkùn láti Jerusalẹmu lọ sí Babiloni pé, 5‘Ẹ máa kọ́ ilé kí ẹ sì máa gbé inú wọn, ẹ máa dá oko kí ẹ sì máa jẹ èso wọn. 6Ẹ máa gbé iyawo kí ẹ bímọ lọkunrin ati lobinrin. Ẹ máa fẹ́ iyawo fún àwọn ọmọ yín, kí ẹ sì fi àwọn ọmọ yín fún ọkọ, kí wọn lè máa bímọ lọkunrin ati lobinrin. Ẹ máa pọ̀ sí i, ẹ má sì dínkù. 7Ẹ máa wá alaafia ìlú tí mo ko yín lọ, ẹ máa gbadura sí OLUWA fún un, nítorí pé ninu alaafia rẹ̀ ni ẹ̀yin náà yóo ti ní alaafia. 8Nítorí èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli sọ pé kí ẹ má jẹ́ kí àwọn wolii ati àwọn tí wọn ń woṣẹ́ láàrin yín tàn yín jẹ, kí ẹ má sì fetí sí àlá tí wọn ń lá; 9nítorí pé àsọtẹ́lẹ̀ èké ni wọ́n ń sọ fun yín ní orúkọ mi, n kò rán wọn níṣẹ́.’
10“Nígbà tí aadọrin ọdún Babiloni bá pé, n óo mójú tó ọ̀rọ̀ yín, n óo mú ìlérí mi ṣẹ fun yín, n óo sì ko yín pada sí ibí yìí. 11Nítorí pé mo mọ èrò tí mò ń gbà si yín, èrò alaafia ni, kì í ṣe èrò ibi. N óo mú kí ọjọ́ ọ̀la dára fun yín, n óo sì fun yín ní ìrètí.#2Kron 36:21; Jer 25:11; Dan 9:2 12Ẹ óo ké pè mí, ẹ óo gbadura sí mi, n óo sì gbọ́ adura yín. 13Ẹ óo wá mi, ẹ óo sì rí mi, bí ẹ bá fi tọkàntọkàn wá mi. 14Ẹ óo rí mi, n óo dá ire yín pada, n óo ko yín jọ láti gbogbo orílẹ̀-èdè ati láti gbogbo ibi tí mo ti le yín lọ; n óo sì ko yín pada sí ibi tí mo ti le yín kúrò lọ sí ìgbèkùn. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.#Diut 4:29; Ọgb 6:12-13
15“Nítorí ẹ wí pé, ‘OLUWA ti gbé àwọn wolii dìde fun wa ní Babiloni.’ 16Nípa ti ọba tí ó jókòó lórí ìtẹ́ Dafidi, ati gbogbo àwọn tí ń gbé ìlú yìí, àní àwọn ará yín tí wọn kò ba yín lọ sí ìgbèkùn, 17OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, ‘N óo rán ogun, ìyàn ati àjàkálẹ̀ àrùn sí wọn, n óo sì ṣe wọ́n bí èso ọ̀pọ̀tọ́ tí ó bàjẹ́ tóbẹ́ẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò lè jẹ ẹ́.’ 18Ó ní, ‘N óo fi ogun, ìyàn ati àjàkálẹ̀ àrùn bá wọn jà, òun óo sì sọ wọ́n di àríbẹ̀rù fún gbogbo orílẹ̀-èdè ayé. Wọn yóo di ẹni ègún, àríbẹ̀rù, àrípòṣé ati ẹni ẹ̀sín láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tí mo lé wọn lọ. 19Nítorí pé wọn kò fetí sí ọ̀rọ̀ tí mo rán àwọn iranṣẹ mi, àwọn wolii, láti sọ fún wọn nígbà gbogbo. 20Ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA sọ, gbogbo ẹ̀yin tí OLUWA kó ní ìgbèkùn láti Jerusalẹmu lọ sí Babiloni.’
21“Ohun tí OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli sọ nípa Ahabu ọmọ Jehoiakini, ati Sedekaya ọmọ Maaseaya, tí wọn ń forúkọ mi sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké fun yín ni pé: òun óo fi wọ́n lé Nebukadinesari ọba Babiloni lọ́wọ́, yóo sì pa wọ́n lójú yín. 22Gbogbo àwọn ará Juda tí wọ́n wà ní ìgbèkùn ní Babiloni yóo máa fi ọ̀rọ̀ wọn ṣépè fún eniyan pé: ‘OLUWA yóo ṣe ọ́ bíi Sedekaya ati Ahabu tí ọba Babiloni sun níná,’ 23nítorí pé wọ́n ti hùwà òmùgọ̀ ní Israẹli, wọ́n bá aya àwọn aládùúgbò wọn ṣe àgbèrè, wọ́n fi orúkọ òun sọ ọ̀rọ̀ èké tí òun kò fún wọn láṣẹ láti sọ. OLUWA ní òun nìkan ni òun mọ ohun tí wọ́n ṣe; òun sì ni ẹlẹ́rìí.”
Ìwé Tí Ṣemaaya Kọ
24OLUWA ní kí n sọ fún Ṣemaaya tí ń gbé Nehelamu pé, 25“Èmi, OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní, nítorí ìwé tí o fi orúkọ ara rẹ kọ sí gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n wà ní Jerusalẹmu, ati sí Sefanaya alufaa, ọmọ Maaseaya, ati sí gbogbo àwọn alufaa, pé:
26“Èmi OLUWA ti fi ìwọ Sefanaya jẹ alufaa dípò Jehoiada tí ó jẹ́ alufaa tẹ́lẹ̀ rí, ati pé mo ní kí o máa ṣe alabojuto gbogbo àwọn wèrè tí wọn ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní ilé èmi OLUWA, kí o sì máa kan ààbà mọ́ wọn ní ẹsẹ̀, kí o máa fi okùn sí wọn lọ́rùn. 27Kí ló dé tí o kò bá Jeremaya ará Anatoti tí ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ fun yín wí. 28Nítorí ó ti ranṣẹ sí wa ní Babiloni pé a á pẹ́ níbí, nítorí náà kí á kọ́lé, kí á máa gbé inú rẹ̀, kí á dá oko, kí á sì máa jẹ èso rẹ̀.”
29Sefanaya Alufaa ka ìwé náà sí etí Jeremaya wolii. 30OLUWA bá sọ fún Jeremaya pé, 31“Ranṣẹ sí gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní ìgbèkùn wí pé ohun tí OLUWA wí nípa Ṣemaaya ará Nehelamu ni pé: nítorí pé Ṣemaaya sọ àsọtẹ́lẹ̀ tí òun kò rán an, ó sì mú kí ẹ gbẹ́kẹ̀lé ọ̀rọ̀ èké, 32òun OLUWA óo fìyà jẹ Ṣemaaya ará Nehelamu náà ati ìran rẹ̀; kò ní sí ẹnikẹ́ni tí yóo wà láàyè láàrin àwọn eniyan rẹ̀ láti fojú rí nǹkan rere tí n óo ṣe fún àwọn eniyan mi, nítorí ó ti sọ̀rọ̀ ọ̀tẹ̀ sí OLUWA.”

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

JEREMAYA 29: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa