JEREMAYA 22:13-17

JEREMAYA 22:13-17 YCE

Ẹni tí ó ń fi aiṣododo kọ́ ilé rẹ̀ gbé, tí ó ń fi ọ̀nà èrú kọ́ òrùlé rẹ̀. Tí ó mú ọmọ ẹnìkejì rẹ̀ sìn lọ́fẹ̀ẹ́, láìsan owó iṣẹ́ rẹ̀ fún un. Ègbé ni fún ẹni tí ó wí pé, “N óo kọ́ ilé ńlá fún ara mi, ilé tí ó ní yàrá ńláńlá lókè rẹ̀.” Ó bá yọ àwọn fèrèsé sí i lẹ́gbẹ̀ẹ́. Ó fi igi kedari bo ara ògiri rẹ̀, ó wá fi ọ̀dà pupa kùn ún. Ṣé ilé kedari tí o kọ́ ni ó sọ ọ́ di ọba? Wo baba rẹ, ṣé kò rí jẹ ni, tabi kò rí mu? Ṣebí ó ṣe ẹ̀tọ́ ati òdodo, ṣebí ó sì dára fún un. Ẹjọ́ ẹ̀tọ́ níí dá fún talaka ati aláìní, ohun gbogbo sì ń lọ dáradára. Ṣebí èyí ni à ń pè ní kí eniyan mọ OLUWA? OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀. Ṣugbọn níbi èrè aiṣododo nìkan ni ojú ati ọkàn yín ń wà, níbi kí ẹ máa pa aláìṣẹ̀, kí ẹ máa ni eniyan lára, kí ẹ sì máa hùwà ìkà.