Jer 22:13-17
Jer 22:13-17 Bibeli Mimọ (YBCV)
Egbe ni fun ẹniti o kọ́ ilẹ rẹ̀, ti kì iṣe nipa ododo, ati iyẹwu rẹ̀, ti kì iṣe nipa ẹ̀tọ́: ti o lò iṣẹ ọwọ aladugbo rẹ̀ lọfẹ, ti kò fi ere iṣẹ rẹ̀ fun u. Ti o wipe, emi o kọ ile ti o ni ibò fun ara mi, ati iyẹwu nla, ti o ke oju ferese fun ara rẹ̀, ti o fi igi kedari bò o, ti o si fi ajẹ̀ kùn u. Iwọ o ha jọba, nitori iwọ fi igi kedari dije? baba rẹ kò ha jẹ, kò ha mu? o si ṣe idajọ ati ododo, nitorina o dara fun u. O dajọ ọ̀ran talaka ati alaini; o dara fun u: bi ãti mọ̀ mi kọ́ eyi? li Oluwa wi. Ṣugbọn oju rẹ̀ ati ọkàn rẹ kì iṣe fun ohunkohun bikoṣe ojukokoro rẹ, ati lati ta ẹ̀jẹ alaiṣẹ silẹ, ati lati ṣe ininilara ati agbara.
Jer 22:13-17 Yoruba Bible (YCE)
Ẹni tí ó ń fi aiṣododo kọ́ ilé rẹ̀ gbé, tí ó ń fi ọ̀nà èrú kọ́ òrùlé rẹ̀. Tí ó mú ọmọ ẹnìkejì rẹ̀ sìn lọ́fẹ̀ẹ́, láìsan owó iṣẹ́ rẹ̀ fún un. Ègbé ni fún ẹni tí ó wí pé, “N óo kọ́ ilé ńlá fún ara mi, ilé tí ó ní yàrá ńláńlá lókè rẹ̀.” Ó bá yọ àwọn fèrèsé sí i lẹ́gbẹ̀ẹ́. Ó fi igi kedari bo ara ògiri rẹ̀, ó wá fi ọ̀dà pupa kùn ún. Ṣé ilé kedari tí o kọ́ ni ó sọ ọ́ di ọba? Wo baba rẹ, ṣé kò rí jẹ ni, tabi kò rí mu? Ṣebí ó ṣe ẹ̀tọ́ ati òdodo, ṣebí ó sì dára fún un. Ẹjọ́ ẹ̀tọ́ níí dá fún talaka ati aláìní, ohun gbogbo sì ń lọ dáradára. Ṣebí èyí ni à ń pè ní kí eniyan mọ OLUWA? OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀. Ṣugbọn níbi èrè aiṣododo nìkan ni ojú ati ọkàn yín ń wà, níbi kí ẹ máa pa aláìṣẹ̀, kí ẹ máa ni eniyan lára, kí ẹ sì máa hùwà ìkà.
Jer 22:13-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Ègbé ni fún ẹni tí a kọ́ ààfin rẹ̀ lọ́nà àìṣòdodo, àti àwọn yàrá òkè rẹ̀ lọ́nà àìtọ́ tí ó mú kí àwọn ará ìlú rẹ ṣiṣẹ́ lásán láìsan owó iṣẹ́ wọn fún wọn. Ó wí pé, ‘Èmi ó kọ́ ààfin ńlá fún ara mi àwọn yàrá òkè tí ó fẹ̀, ojú fèrèsé rẹ̀ yóò tóbi.’ A ó sì fi igi kedari bò ó, a ó fi ohun aláwọ̀ pupa ṣe é ní ọ̀ṣọ́. “Ìwọ ó ha jẹ ọba kí ìwọ kí ó lè ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ igi kedari? Baba rẹ kò ha ní ohun jíjẹ àti mímu? Ó ṣe ohun tí ó tọ́ àti òdodo, nítorí náà ó dára fún un. Ó gbèjà òtòṣì àti aláìní, ohun gbogbo sì dára fún un. Bí a ti mọ̀ mí kọ́ ni èyí?” ni OLúWA wí. “Ṣùgbọ́n ojú rẹ àti ọkàn rẹ wà lára èrè àìṣòótọ́ láti ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ ìnilára àti ìlọ́nilọ́wọ́gbà.”