JEREMAYA 18
18
Jeremaya nílé Amọ̀kòkò
1OLUWA bá Jeremaya sọ̀rọ̀, ó ní: 2“Dìde, lọ sí ilé amọ̀kòkò, níbẹ̀ ni óo ti gbọ́ ọ̀rọ̀ tí mo fẹ́ bá ọ sọ.” 3Mo bá lọ sí ilé amọ̀kòkò. Mo bá a tí ó ń mọ ìkòkò kan lórí òkúta tí wọn fi ń mọ ìkòkò. 4Ìkòkò tí ó ń fi amọ̀ mọ bàjẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀, ó bá fi amọ̀ náà mọ ìkòkò mìíràn, tí ó wù ú.
5OLUWA bá sọ fún mi pé, 6“Ẹ̀yin ilé Israẹli, ṣé n kò lè ṣe yín bí amọ̀kòkò yìí ti ṣe ìkòkò tí ó mọ ni? Bí amọ̀ ti rí lọ́wọ́ amọ̀kòkò ni ẹ rí lọ́wọ́ mi, ẹ̀yin ilé Israẹli. 7Bí mo bá sọ pé n óo fa orílẹ̀-èdè kan, tabi ìjọba kan tu, n óo wó o lulẹ̀, n óo sì pa á run, 8bí orílẹ̀-èdè ọ̀hún bá yipada kúrò ninu ìwà burúkú rẹ̀, n óo dá ibi tí mo ti fẹ́ ṣe sí i tẹ́lẹ̀ dúró. 9Bí mo bá sọ pé n óo gbé orílẹ̀-èdè kan dìde, n óo sì fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀; 10bí ó bá ṣe nǹkan burúkú lójú mi, tí kò gbọ́ràn sí mi lẹ́nu, n óo dá nǹkan rere tí mo ti fẹ́ ṣe fún un dúró. 11Nítorí náà, sọ fún àwọn ará Juda ati àwọn tí wọn ń gbé Jerusalẹmu pé, èmi OLUWA ní, mò ń pète ibi kan si yín, mo sì ń pinnu rẹ̀ lọ́wọ́ báyìí, kí olukuluku yín yipada kúrò ninu ibi tí ó ń ṣe; kí ẹ sì tún ìwà ati ìṣe yín ṣe. 12Ṣugbọn wọ́n ń wí pé, ‘Rárá o, OLUWA kàn ń sọ tirẹ̀ ni, tinú wa ni a óo ṣe, olukuluku yóo máa lo agídí ọkàn rẹ̀.’ ”
Àwọn Eniyan náà kọ OLUWA Sílẹ̀
13Nítorí náà OLUWA ní,
“Ẹ bèèrè láàrin gbogbo orílẹ̀-èdè,
bí ẹnikẹ́ni bá gbọ́ irú rẹ̀ rí.
Israẹli ti ṣe ohun tó burú gan-an.
14Ṣé yìnyín òkè Lẹbanoni a máa dà ní pàlàpálá Sirioni?#18:14 Ìtumọ̀ Sirioni ni ‘orí pápá’ ní èdè Heberu.
Àbí omi tútù tí máa ń ṣàn láti inú òkè rẹ̀ a máa gbẹ?
15Ṣugbọn àwọn eniyan mi ti gbàgbé mi,
wọ́n ń sun turari sí oriṣa èké.
Wọ́n ti kọsẹ̀ ní ojú ọ̀nà àtijọ́ tí wọn ń tọ̀,
wọ́n ti yà sí ọ̀nà ojúgbó tí kì í ṣe ojú ọ̀nà tààrà.
16Wọ́n sọ ilẹ̀ wọn di ohun ẹ̀rù ati ohun àrípòṣé títí lae.
Gbogbo àwọn tí wọn bá gba ibẹ̀ kọjá ni ẹ̀rù yóo máa bà,
tí wọn yóo sì máa mi orí.
17N óo fọ́n wọn ká níwájú ọ̀tá bí ẹ̀fúùfù ìlà oòrùn.
Ẹ̀yìn ni n óo kọ sí wọn lọ́jọ́ àjálù,
wọn kò ní rí ojú mi.”
Wọ́n Gbìmọ̀ Ibi sí Jeremaya
18Wọ́n bá dáhùn pé, “Ẹ wá, kí á gbìmọ̀ ibi sí Jeremaya, nítorí pé òfin kò ní parun lọ́dọ̀ àwọn alufaa, ìmọ̀ràn kò ní tán lọ́dọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n, ọ̀rọ̀ Ọlọrun kò sì ní ṣàì máa wà lẹ́nu àwọn wolii. Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á fi ọ̀rọ̀ ẹnu wa pa á, ẹ má sì jẹ́ kí á fetí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀ kankan.”
19Mo bá gbadura pe,
“Tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ mi, OLUWA,
kí o sì gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi.
20Ṣé ibi ni eniyan fi í san rere?
Sibẹ wọ́n ti wa kòtò sílẹ̀ fún mi.
Ranti bí mo ti dúró níwájú rẹ tí mo sọ ọ̀rọ̀ wọn ní rere,
kí o baà lè yí ibinu rẹ pada lórí wọn.
21Nítorí náà ìyàn ni kí ó pa àwọn ọmọ wọn,
kí ogun pa wọ́n,
kí àwọn aya wọn di aláìlọ́mọ ati opó,
kí àjàkálẹ̀ àrùn pa àwọn ọmọkunrin wọn,
kí idà ọ̀tá sì pa àwọn ọ̀dọ̀ wọn lójú ogun.
22Kí igbe ẹkún ó sọ ninu ilé wọn,
nígbà tí o bá mú àwọn apanirun wá sórí wọn lójijì;
nítorí pé wọ́n wa kòtò láti mú mi,
wọ́n dẹ tàkúté sílẹ̀ fún mi.
23OLUWA, gbogbo àbá tí wọn ń dá ni o mọ̀,
o mọ gbogbo ète tí wọn ń pa láti pa mí.
Má dárí ìwà ibi wọn jì wọ́n,
má sì pa ẹ̀ṣẹ̀ wọn rẹ́ níwájú rẹ.
Jẹ́ kí wọn ṣubú níwájú rẹ,
nígbà tí inú bá ń bí ọ ni kí o bá wọn wí.”
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
JEREMAYA 18: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010