ÀWỌN ADÁJỌ́ 16

16
Samsoni ní Ìlú Gasa
1Ní ọjọ́ kan, Samsoni lọ sí ìlú Gasa, ó rí obinrin aṣẹ́wó kan níbẹ̀, ó bá wọlé tọ̀ ọ́ lọ. 2Àwọn kan bá lọ sọ fún àwọn ará Gasa pé Samsoni wà níbẹ̀. Wọ́n yí ilé náà po, wọ́n sì ba dè é níbi ẹnu ọ̀nà bodè ìlú ní gbogbo òru ọjọ́ náà. Wọ́n dákẹ́ rọ́rọ́, wọ́n ní, “Ẹ jẹ́ kí á dúró títí di ìdájí kí á tó pa á.” 3Ṣugbọn Samsoni sùn títí di ọ̀gànjọ́ òru. Ní òru náà, ó gbéra, ó gbá ìlẹ̀kùn ẹnu ọ̀nà bodè ìlú náà mú ati àwọn òpó rẹ̀ mejeeji, ó sì fà á tu pẹlu irin ìdábùú rẹ̀, ó gbé wọn lé èjìká, ó sì rù wọ́n lọ sí orí òkè kan tí ó wà ní iwájú Heburoni.
Samsoni ati Delila
4Lẹ́yìn èyí, Samsoni rí obinrin kan tí ó wù ú ní àfonífojì Soreki, ó sì fẹ́ ẹ. Delila ni orúkọ obinrin náà. 5Àwọn ọba Filistia wá sọ́dọ̀ obinrin yìí, wọ́n ní, “Tan ọkọ rẹ, kí o sì mọ àṣírí agbára rẹ̀, ati ọ̀nà tí a fi lè kápá rẹ̀; kí á lè dì í lókùn kí á sì ṣẹgun rẹ̀. Ẹnìkọ̀ọ̀kan wa yóo sì fún ọ ní ẹẹdẹgbẹfa (1,100) owó fadaka.”
6Delila bá pe Samsoni, ó ní, “Jọ̀wọ́, sọ àṣírí agbára rẹ fún mi, ati bí eniyan ṣe lè so ọ́ lókùn kí eniyan sì kápá rẹ.”
7Samsoni dá a lóhùn pé, “Bí wọ́n bá fi awọ tí wọ́n fi ń ṣe ọrun, tí kò tíì gbẹ meje dè mí, yóo rẹ̀ mí, n óo sì dàbí àwọn ọkunrin yòókù.”
8Àwọn ọba Filistini bá kó awọ tí wọ́n fi ń ṣe ọrun, titun, meje, tí kò tíì gbẹ, fún Delila, ó sì fi so Samsoni. 9Ó ti fi àwọn eniyan pamọ́ sinu yàrá inú. Ó bá pe Samsoni, ó ní, “Samsoni àwọn ará Filistia dé.” Ṣugbọn Samsoni já awọ ọrun náà bí ìgbà tí iná já fọ́nrán òwú lásán. Wọn kò sì mọ àṣírí agbára rẹ̀.
10Delila tún wí fún Samsoni pé, “Ò ń fi mí ṣe ẹlẹ́yà, o sì ń purọ́ fún mi. Jọ̀wọ́ sọ bí eniyan ṣe le dè ọ́ lókùn fún mi.”
11Ó dá a lóhùn pé, “Tí wọ́n bá fi okùn titun, tí wọn kò tíì lò rí dè mí, yóo rẹ̀ mí, n óo sì dàbí àwọn ọkunrin yòókù.”
12Delila bá mú okùn titun, ó fi dè é, ó sì wí fún un pé, “Samsoni, àwọn ará Filistia dé!” Àwọn tí wọ́n sápamọ́ sì wà ninu yàrá inú. Ṣugbọn Samsoni fa okùn náà já bí ẹni pé fọ́nrán òwú kan ni.
13Delila tún wí fún Samsoni pé, “Sibẹsibẹ o ṣì tún ń fi mí ṣe ẹlẹ́yà, o tún ń purọ́ fún mi. Sọ fún mi bí eniyan ṣe lè gbé ọ dè.”
Ó dá a lóhùn pé, “Bí o bá di ìdì irun meje tí ó wà lórí mi, mọ́ igi òfì, tí o sì dì í papọ̀, yóo rẹ̀ mi, n óo sì dàbí àwọn ọkunrin yòókù.”
14Nítorí náà, nígbà tí ó sùn, Delila mú ìdì irun mejeeje tí ó wà lórí rẹ̀, ó lọ́ ọ mọ́ igi òfì, ó sì fi èèkàn kàn án mọ́lẹ̀, ó bá pè é, ó ní, “Samsoni! Àwọn Filistini dé.” Ṣugbọn nígbà tí ó jí láti ojú oorun rẹ̀, ó fa èèkàn ati igi òfì náà tu.
15Delila tún sọ fún un pé, “Báwo ni o ṣe lè wí pé o nífẹ̀ẹ́ mí, nígbà tí ọkàn rẹ kò sí lọ́dọ̀ mi. O ti fi mí ṣe ẹlẹ́yà nígbà mẹta, o kò sì sọ àṣírí agbára ńlá rẹ fún mi.” 16Nígbà tí Delila bẹ̀rẹ̀ sí yọ ọ́ lẹ́nu lemọ́lemọ́, tí ó sì ń rọ̀ ọ́ lojoojumọ, ọ̀rọ̀ náà sú Samsoni patapata. 17Ó bá tú gbogbo ọkàn rẹ̀ palẹ̀ fún Delila, ó ní, “Ẹnìkan kò fi abẹ kàn mí lórí rí, nítorí pé Nasiri Ọlọrun ni mí láti inú ìyá mi wá. Bí wọ́n bá fá irun mi, agbára mi yóo fi mí sílẹ̀, yóo rẹ̀ mí n óo sì dàbí àwọn ọkunrin yòókù.”
18Nígbà tí Delila rí i pé ó ti tú gbogbo ọkàn rẹ̀ palẹ̀ fún òun, ó ranṣẹ pe àwọn ọba Filistini, ó ní, “Ẹ tún wá lẹ́ẹ̀kan sí i, nítorí pé ó ti sọ gbogbo inú rẹ̀ fún mi.” Àwọn ọba Filistini maraarun bá wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n mú owó náà lọ́wọ́. 19Delila mú kí Samsoni sùn lórí ẹsẹ̀ rẹ̀, ó bá pe ọkunrin kan pé kí ó fá ìdì irun mejeeje tí ó wà ní orí Samsoni. Ó bá bẹ̀rẹ̀ sí jẹ ẹ́ níyà, agbára rẹ̀ sì fi í sílẹ̀. 20Ó wí fún un pé, “Samsoni! Àwọn ará Filistia ti dé.” Samsoni bá jí láti ojú oorun, ó ní, “N óo lọ bí mo ti máa ń ṣe tẹ́lẹ̀, n óo sì gba ara mi lọ́wọ́ wọn.” Kò mọ̀ pé OLUWA ti fi òun sílẹ̀. 21Àwọn Filistini bá kì í mọ́lẹ̀, wọ́n yọ ojú rẹ̀, wọ́n mú un wá sí ìlú Gasa, wọ́n sì fi ẹ̀wọ̀n idẹ dè é. Wọ́n ní kí ó máa lọ àgbàdo ninu ilé ẹ̀wọ̀n. 22Ṣugbọn irun orí rẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ sí kún lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti fá a.
Ikú Samsoni
23Ní ọjọ́ kan, àwọn ọba Filistini kó ara wọn jọ láti rú ẹbọ ńlá kan sí Dagoni, oriṣa wọn, ati láti ṣe àríyá pé oriṣa wọn ni ó fi Samsoni ọ̀tá wọn lé wọn lọ́wọ́. 24Nígbà tí àwọn eniyan rí i, wọ́n yin oriṣa wọn; wọ́n ní, “Oriṣa wa ti fi ọ̀tá wa lé wa lọ́wọ́, ẹni tí ó sọ ilẹ̀ wa di ahoro tí ó sì pa ọpọlọpọ ninu wa.” 25Nígbà tí inú wọn dùn, wọ́n ní, “Ẹ pe Samsoni náà wá, kí ó wá dá wa lára yá.” Wọ́n pe Samsoni jáde láti inú ilé ẹ̀wọ̀n, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí dá wọn lára yá. Wọ́n mú un lọ sí ààrin òpó mejeeji pé kí ó dúró níbẹ̀. 26Samsoni bá bẹ ọdọmọkunrin tí ó mú un lọ́wọ́, ó ní, “Jẹ́ kí n fi ọwọ́ kan àwọn òpó tí gbogbo ilé yìí gbé ara lé kí n lè fara tì wọ́n.” 27Ilé náà kún fún ọpọlọpọ eniyan, lọkunrin ati lobinrin; gbogbo àwọn ọba ilẹ̀ Filistini ni wọ́n wà níbẹ̀. Lórí òrùlé nìkan, àwọn tí wọ́n wà níbẹ̀ tó ẹgbẹẹdogun (3,000) eniyan, lọkunrin ati lobinrin tí wọn ń wo Samsoni níbi tí ó ti ń dá wọn lára yá.
28Samsoni bá ké pe OLUWA, ó ní, “OLUWA Ọlọrun, jọ̀wọ́, ranti mi, kí o sì fún mi lágbára lẹ́ẹ̀kan péré sí i, jọ̀wọ́ Ọlọrun mi, kí n lè gbẹ̀san lára àwọn Filistini fún ọ̀kan ninu ojú mi mejeeji.” 29Samsoni bá gbá àwọn òpó mejeeji tí ó wà láàrin, tí ilé náà gbára lé mú, ó gbé ọwọ́ ọ̀tún lé ọ̀kan, ó gbé ọwọ́ òsì lé ekeji, ó sì fi gbogbo agbára rẹ̀ tì wọ́n. 30Ó wí pé, “Jẹ́ kí èmi náà kú pẹlu àwọn ará Filistia.” Ó bá bẹ̀rẹ̀ pẹlu gbogbo agbára rẹ̀. Ilé náà sì wó lu gbogbo àwọn ọba Filistini ati gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n wà ninu rẹ̀. Nítorí náà, iye eniyan tí ó pa nígbà tí òun náà yóo fi kú, ju àwọn tí ó pa nígbà tí ó wà láàyè lọ.
31Àwọn arakunrin rẹ̀, ati gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀ bá wá gbé òkú rẹ̀, wọ́n lọ sin ín sáàrin Sora ati Eṣitaolu ninu ibojì Manoa, baba rẹ̀. Ogún ọdún ni ó fi ṣe aṣiwaju ní Israẹli.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ÀWỌN ADÁJỌ́ 16: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀