ÀWỌN ADÁJỌ́ 15
15
1Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, ní àkókò ìkórè ọkà, Samsoni mú ọmọ ewúrẹ́ kan, ó lọ bẹ iyawo rẹ̀ wò. Nígbà tí ó dé ibẹ̀, ó ní, “Mo fẹ́ wọlé lọ bá iyawo mi ninu yàrá.”
Ṣugbọn baba iyawo rẹ̀ kò jẹ́ kí ó wọlé lọ bá a. 2Baba iyawo rẹ̀ wí fún un pé, “Mo rò pé lóòótọ́ ni o kórìíra iyawo rẹ, nítorí náà, mo ti fi fún ẹni tí ó jẹ́ ọrẹ rẹ tímọ́tímọ́, ninu àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ. Ṣé ìwọ náà rí i pé àbúrò rẹ̀ lẹ́wà jù ú lọ, jọ̀wọ́ fẹ́ ẹ dípò rẹ̀.”
3Samsoni dáhùn pé, “Bí mo bá ṣe àwọn ará Filistia ní ibi ní àkókò yìí, n kò ní jẹ̀bi wọn.” 4Samsoni bá lọ, ó mú ọọdunrun (300) kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ láàyè, ó wá ìtùfù, ó sì so àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ náà ní ìrù pọ̀ ní meji meji, ó fi ìtùfù sí ààrin ìrù wọn. 5Ó ṣáná sí àwọn ìtùfù náà, ó sì tú àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ náà sílẹ̀ ninu oko ọkà àwọn ará Filistia. Àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ yìí bá tan iná ran gbogbo ìtí ọkà ati àwọn ọkà tí ó wà ní òòró ati gbogbo ọgbà olifi wọn; gbogbo wọn sì jóná ráúráú. 6Àwọn ará Filistia bá bẹ̀rẹ̀ sí bèèrè pé, “Ta ni ó dán irú èyí wò?” Wọ́n dá wọn lóhùn pé, “Samsoni, ọkọ ọmọ ará Timna ni; nítorí pé àna rẹ̀ fi iyawo rẹ̀ fún ọ̀rẹ́ rẹ̀.” Àwọn ará Filistia bá lọ dáná sun iyawo náà ati baba rẹ̀.
7Samsoni bá sọ fún wọn pé, “Bí ó bá jẹ́ pé bí ẹ óo ti ṣe nìyí n óo gbẹ̀san lára yín, lẹ́yìn náà, n óo fi yín sílẹ̀.” 8Samsoni pa ọpọlọpọ ninu wọn. Ó kúrò níbẹ̀, ó sì lọ ń gbé inú ihò àpáta kan tí ó wà ní Etamu.
Samsoni Ṣẹgun Àwọn Ará Filistia
9Àwọn ará Filistia bá kógun wá sí Juda, wọ́n sì kọlu ìlú Lehi. 10Àwọn ọkunrin Juda bá bèèrè pé, “Kí ló dé tí ẹ fi gbógun tì wá?”
Wọ́n dá wọn lóhùn pé, “Samsoni ni a wá mú; ohun tí ó ṣe sí wa ni àwa náà fẹ́ ṣe sí i.” 11Ẹgbẹẹdogun (3,000) ọkunrin Juda lọ bá Samsoni ní ibi ihò àpáta tí ó wà ní Etamu, wọ́n sọ fún un pé, “Ṣé o kò mọ̀ pé àwọn ará Filistia ni wọ́n ń ṣe àkóso wa ni? Irú kí ni o ṣe sí wa yìí?”
Ó dá wọn lóhùn pé, “Oró tí wọ́n dá mi ni mo dá wọn.”
12Wọ́n dá a lóhùn pé, “A wá láti dì ọ́ tọwọ́ tẹsẹ̀ kí á sì gbé ọ lọ fún àwọn ará Filistia ni.”
Samsoni dá wọn lóhùn, ó ní, “Ẹ búra fún mi pé ẹ̀yin tìkara yín kò ní pa mí.”
13Wọ́n dá a lóhùn pé, “Rárá, àwa óo dì ọ́, a óo sì gbé ọ lé wọn lọ́wọ́ ni, a kò ní pa ọ́ rárá.” Wọ́n bá mú okùn titun meji, wọ́n fi dì í, wọ́n sì gbé e jáde láti inú ihò àpáta náà.
14Nígbà tí ó dé Lehi, àwọn Filistia wá hó pàdé rẹ̀. Ẹ̀mí OLUWA bà lé Samsoni tagbára tagbára, okùn tí wọ́n fi dè é sì já bí ìgbà tí iná ràn mọ́ fọ́nrán òwú. Gbogbo ìdè tí wọ́n fi dè é já kúrò ní ọwọ́ rẹ̀. 15Ó rí egungun páárì ẹ̀rẹ̀kẹ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ pa, ó mú un, ó sì fi pa ẹgbẹrun ninu àwọn ará Filistia. 16Samsoni bá dáhùn pé,
“Páárì ẹ̀rẹ̀kẹ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ni mo fi pa wọ́n jọ bí òkítì,
Egungun ẹ̀rẹ̀kẹ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ni mo fi pa ẹgbẹrun eniyan.”
17Lẹ́yìn tí ó wí báyìí tán, ó ju egungun ẹ̀rẹ̀kẹ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà sílẹ̀, wọ́n sì sọ ibẹ̀ ní Ramati Lehi.
18Òùngbẹ bá bẹ̀rẹ̀ sí gbẹ ẹ́ gidigidi, ó sì gbadura sí OLUWA, ó ní, “Ìwọ ni o ran èmi iranṣẹ rẹ lọ́wọ́ láti ṣẹgun lónìí, ṣugbọn ṣé òùngbẹ ni yóo wá gbẹ mí pa, tí n óo fi bọ́ sí ọwọ́ àwọn aláìkọlà wọnyi?” 19Ọlọrun bá la ibi ọ̀gbun kan tí ó wà ní Lehi, omi sì bẹ̀rẹ̀ sí jáde láti inú ọ̀gbun náà. Lẹ́yìn tí ó mu omi tán, ojú rẹ̀ wálẹ̀, nítorí náà, wọ́n sọ ibẹ̀ ní Enhakore. Enhakore yìí sì wà ní Lehi títí di òní olónìí.
20Samsoni ṣe aṣiwaju ní Israẹli ní àkókò àwọn Filistini fún ogún ọdún.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
ÀWỌN ADÁJỌ́ 15: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010