AISAYA 9:1-6

Àwọn àwòrán ẹsẹ fún AISAYA 9:1-6

AISAYA 9:1-6 - Ṣugbọn kò ní sí ìṣúdudu fún ẹni tí ó wà ninu ìnira. Ní ìgbà àtijọ́, ó sọ ilẹ̀ Sebuluni ati ilẹ̀ Nafutali di yẹpẹrẹ, ṣugbọn nígbà ìkẹyìn yóo ṣe ilẹ̀ àwọn tí ó ń gbé apá ọ̀nà òkun lógo, títí lọ dé òdìkejì odò Jọdani, ati Galili níbi tí àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè mìíràn ń gbé.
Àwọn tí ń rìn ninu òkùnkùn ti rí ìmọ́lẹ̀ ńlá.
Ìmọ́lẹ̀ sì ti tàn sí àwọn tí ń gbé ninu òkùnkùn biribiri.
Ó ti bukun orílẹ̀-èdè náà.
Ó ti fi kún ayọ̀ wọn;
wọ́n ń yọ̀ níwájú rẹ̀, bí ayọ̀ ìgbà ìkórè.
Bí inú àwọn eniyan ti máa ń dùn nígbà tí wọ́n bá ń pín ìkógun.
Nítorí pé ó ti ṣẹ́ àjàgà tí ó wọ̀ wọ́n lọ́rùn,
ati ọ̀pá tí wọn fí ń ru ẹrù sí èjìká,
ati kùmọ̀ àwọn tí ń fìyà jẹ wọ́n.
Ó ti ṣẹ́ wọn, bí ìgbà tí ó ṣẹ́ ti àwọn ará Midiani.
Gbogbo bàtà àwọn ológun, tí ń kilẹ̀ lójú ogun,
ati gbogbo ẹ̀wù tí wọ́n ti yí mọ́lẹ̀ ninu ẹ̀jẹ̀ ni a óo dáná sun,
iná yóo sì jó wọn run.
Nítorí a bí ọmọ kan fún wa,
a fún wa ní ọmọkunrin kan.
Òun ni yóo jọba lórí wa.
A óo máa pè é ní Ìyanu, Olùdámọ̀ràn,
Ọlọrun alágbára, Baba ayérayé,
Ọmọ-Aládé alaafia.AISAYA 9:1-6 - Ṣugbọn kò ní sí ìṣúdudu fún ẹni tí ó wà ninu ìnira. Ní ìgbà àtijọ́, ó sọ ilẹ̀ Sebuluni ati ilẹ̀ Nafutali di yẹpẹrẹ, ṣugbọn nígbà ìkẹyìn yóo ṣe ilẹ̀ àwọn tí ó ń gbé apá ọ̀nà òkun lógo, títí lọ dé òdìkejì odò Jọdani, ati Galili níbi tí àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè mìíràn ń gbé.
Àwọn tí ń rìn ninu òkùnkùn ti rí ìmọ́lẹ̀ ńlá.
Ìmọ́lẹ̀ sì ti tàn sí àwọn tí ń gbé ninu òkùnkùn biribiri.
Ó ti bukun orílẹ̀-èdè náà.
Ó ti fi kún ayọ̀ wọn;
wọ́n ń yọ̀ níwájú rẹ̀, bí ayọ̀ ìgbà ìkórè.
Bí inú àwọn eniyan ti máa ń dùn nígbà tí wọ́n bá ń pín ìkógun.
Nítorí pé ó ti ṣẹ́ àjàgà tí ó wọ̀ wọ́n lọ́rùn,
ati ọ̀pá tí wọn fí ń ru ẹrù sí èjìká,
ati kùmọ̀ àwọn tí ń fìyà jẹ wọ́n.
Ó ti ṣẹ́ wọn, bí ìgbà tí ó ṣẹ́ ti àwọn ará Midiani.
Gbogbo bàtà àwọn ológun, tí ń kilẹ̀ lójú ogun,
ati gbogbo ẹ̀wù tí wọ́n ti yí mọ́lẹ̀ ninu ẹ̀jẹ̀ ni a óo dáná sun,
iná yóo sì jó wọn run.
Nítorí a bí ọmọ kan fún wa,
a fún wa ní ọmọkunrin kan.
Òun ni yóo jọba lórí wa.
A óo máa pè é ní Ìyanu, Olùdámọ̀ràn,
Ọlọrun alágbára, Baba ayérayé,
Ọmọ-Aládé alaafia.