Isa 9:1-6
Isa 9:1-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
ṢUGBỌN iṣuju na kì yio wà nibiti wahalà mbẹ nisisiyi, gẹgẹ bi ìgba iṣãju ti mu itìju wá si ilẹ Sebuloni ati ilẹ Naftali, bẹ̃ni ìgba ikẹhin yio mu ọla wá si ọ̀na okun, niha ẹkùn Jordani, Galili awọn orilẹ-ède. Awọn enia ti nrin li okùnkun ri imọlẹ nla: awọn ti ngbe ilẹ ojiji ikú, lara wọn ni imọlẹ mọ́ si. Iwọ ti mu orilẹ-ède nì bi si i pupọ̀pupọ̀, iwọ si sọ ayọ̀ di pupọ̀ fun u: nwọn nyọ̀ niwaju rẹ gẹgẹ bi ayọ̀ ikore, ati gẹgẹ bi enia iti yọ̀ nigbati nwọn npin ikogun. Nitori iwọ ṣẹ́ ajàga-irú rẹ̀, ati ọpá ejika rẹ̀, ọgọ aninilara rẹ̀, gẹgẹ bi li ọjọ Midiani. Nitori gbogbo ihamọra awọn ologun ninu irọkẹ̀kẹ, ati aṣọ ti a yi ninu ẹ̀jẹ, yio jẹ fun ijoná ati igi iná. Nitori a bi ọmọ kan fun wa, a fi ọmọkunrin kan fun wa: ijọba yio si wà li ejika rẹ̀: a o si ma pe orukọ rẹ̀ ni Iyanu, Oludamọ̀ran, Ọlọrun Alagbara, Baba Aiyeraiye, Ọmọ-Alade Alafia.
Isa 9:1-6 Yoruba Bible (YCE)
Ṣugbọn kò ní sí ìṣúdudu fún ẹni tí ó wà ninu ìnira. Ní ìgbà àtijọ́, ó sọ ilẹ̀ Sebuluni ati ilẹ̀ Nafutali di yẹpẹrẹ, ṣugbọn nígbà ìkẹyìn yóo ṣe ilẹ̀ àwọn tí ó ń gbé apá ọ̀nà òkun lógo, títí lọ dé òdìkejì odò Jọdani, ati Galili níbi tí àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè mìíràn ń gbé. Àwọn tí ń rìn ninu òkùnkùn ti rí ìmọ́lẹ̀ ńlá. Ìmọ́lẹ̀ sì ti tàn sí àwọn tí ń gbé ninu òkùnkùn biribiri. Ó ti bukun orílẹ̀-èdè náà. Ó ti fi kún ayọ̀ wọn; wọ́n ń yọ̀ níwájú rẹ̀, bí ayọ̀ ìgbà ìkórè. Bí inú àwọn eniyan ti máa ń dùn nígbà tí wọ́n bá ń pín ìkógun. Nítorí pé ó ti ṣẹ́ àjàgà tí ó wọ̀ wọ́n lọ́rùn, ati ọ̀pá tí wọn fí ń ru ẹrù sí èjìká, ati kùmọ̀ àwọn tí ń fìyà jẹ wọ́n. Ó ti ṣẹ́ wọn, bí ìgbà tí ó ṣẹ́ ti àwọn ará Midiani. Gbogbo bàtà àwọn ológun, tí ń kilẹ̀ lójú ogun, ati gbogbo ẹ̀wù tí wọ́n ti yí mọ́lẹ̀ ninu ẹ̀jẹ̀ ni a óo dáná sun, iná yóo sì jó wọn run. Nítorí a bí ọmọ kan fún wa, a fún wa ní ọmọkunrin kan. Òun ni yóo jọba lórí wa. A óo máa pè é ní Ìyanu, Olùdámọ̀ràn, Ọlọrun alágbára, Baba ayérayé, Ọmọ-Aládé alaafia.
Isa 9:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Síbẹ̀síbẹ̀, kò ní sí ìpòrúru kankan mọ́ fún àwọn tí ó wà nínú ìbànújẹ́. Nígbà kan rí ó rẹ ilẹ̀ Sebuluni sílẹ̀ àti ilẹ̀ Naftali pẹ̀lú, ṣùgbọ́n ní ọjọ́ iwájú, yóò bu ọ̀wọ̀ fún Galili ti àwọn aláìkọlà, ní ọ̀nà Òkun, ní ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ Jordani. Àwọn ènìyàn tí ń rìn nínú òkùnkùn ti rí ìmọ́lẹ̀ ńlá; Lórí àwọn tí ń gbé nínú ilẹ̀ òjìji ikú, ní ara wọn ni ìmọ́lẹ̀ mọ́ sí. Ìwọ ti sọ orílẹ̀-èdè di ńlá; wọ́n sì yọ̀ níwájú rẹ gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn ti í yọ ayọ̀ ìkórè, gẹ́gẹ́ bí ènìyàn ti í yọ̀ nígbà tí à ń pín ìkógun. Nítorí gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ tí a ṣẹ́gun Midiani, ìwọ ti fọ́ ọ túútúú àjàgà ti ń pa wọ́n lẹ́rù, ọ̀pá tí ó dábùú èjìká wọn, ọ̀gọ aninilára wọn. Gbogbo bàtà jagunjagun tí a ti lò lójú ogun àti gbogbo ẹ̀wù tí a yí nínú ẹ̀jẹ̀, ni yóò wà fún ìjóná, àti ohun èlò iná dídá. Nítorí a bí ọmọ kan fún wa, a fi ọmọkùnrin kan fún wa, ìjọba yóò sì wà ní èjìká rẹ̀. A ó sì máa pè é ní: Ìyanu Olùdámọ̀ràn, Ọlọ́run Alágbára Baba ayérayé, Ọmọ ọba aládé Àlàáfíà.