AISAYA 66:12-13

AISAYA 66:12-13 YCE

Nítorí OLUWA ní: “N óo tú ibukun sórí rẹ̀, bí ìgbà tí odò bá ń ṣàn. N óo da ọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè lé e lọ́wọ́, bí odò tí ò ṣàn kọjá bèbè. Yóo dà yín sẹ́gbẹ̀ẹ́ bí ọmọ tí ń mu ọmú, ẹ óo máa ṣeré lórí orúnkún rẹ̀. N óo rẹ̀ yín lẹ́kún bí ọmọ tí ìyá rẹ̀ rẹ̀ lẹ́kún, bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe tù yín ninu ní Jerusalẹmu.