Isa 66:12-13
Isa 66:12-13 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitori bayi li Oluwa wi, Kiyesi i, emi o nà alafia si i bi odò, ati ogo awọn Keferi bi odò ṣiṣàn: nigbana li ẹnyin o mu ọmú, a o dà nyin si ẹgbẹ́ rẹ̀, a o si ma gbe nyin jo lori ẽkún rẹ̀. Gẹgẹ bi ẹniti iya rẹ̀ ntù ninu, bẹ̃ni emi o tù nyin ninu; a o si tù nyin ninu ni Jerusalemu.
Isa 66:12-13 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí OLUWA ní: “N óo tú ibukun sórí rẹ̀, bí ìgbà tí odò bá ń ṣàn. N óo da ọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè lé e lọ́wọ́, bí odò tí ò ṣàn kọjá bèbè. Yóo dà yín sẹ́gbẹ̀ẹ́ bí ọmọ tí ń mu ọmú, ẹ óo máa ṣeré lórí orúnkún rẹ̀. N óo rẹ̀ yín lẹ́kún bí ọmọ tí ìyá rẹ̀ rẹ̀ lẹ́kún, bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe tù yín ninu ní Jerusalẹmu.

Isa 66:12-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí báyìí ni OLúWA wí: “Èmi yóò fún un ní àlàáfíà gẹ́gẹ́ bí odò àti ọrọ̀ orílẹ̀-èdè gẹ́gẹ́ bí ìṣàn omi; ẹ̀yin yóò mu ọmú, a ó sì gbé yín ní apá rẹ̀ a ó bá yín ṣeré ní orúkún rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ìyá ti í tu ọmọ rẹ̀ nínú, bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò tù yín nínú a ó sì tù yín nínú lórí Jerusalẹmu.”