Nitori bayi li Oluwa wi, Kiyesi i, emi o nà alafia si i bi odò, ati ogo awọn Keferi bi odò ṣiṣàn: nigbana li ẹnyin o mu ọmú, a o dà nyin si ẹgbẹ́ rẹ̀, a o si ma gbe nyin jo lori ẽkún rẹ̀.
Gẹgẹ bi ẹniti iya rẹ̀ ntù ninu, bẹ̃ni emi o tù nyin ninu; a o si tù nyin ninu ni Jerusalemu.