OLUWA, Olùràpadà rẹ, Ẹni Mímọ́ Israẹli, ní, “Èmi ni OLUWA Ọlọrun rẹ, tí ń kọ́ ọ ní ohun tí yóo ṣe ọ́ ní anfaani, tí ń darí rẹ, sí ọ̀nà tí ó yẹ kí o gbà. “Ìbá jẹ́ pé o ti fetí sí òfin mi, alaafia rẹ ìbá máa ṣàn bí odò, òdodo rẹ ìbá lágbára bi ìgbì omi òkun. Àwọn ọmọ rẹ ìbá pọ̀ bí iyanrìn, arọmọdọmọ rẹ ìbá pọ̀ bí erùpẹ̀ ilẹ̀ tí kò lóǹkà. Orúkọ wọn kì bá tí parẹ́ títí ayé, bẹ́ẹ̀ ni kì bá tí parun lae níwájú mi.” Ẹ jáde kúrò ní Babiloni, ẹ sá kúrò ní Kalidea, ẹ sọ ọ́ pẹlu ayọ̀, ẹ kéde rẹ̀, ẹ máa ròyìn rẹ̀ lọ títí dè òpin ayé, pé “OLUWA ti ra Jakọbu iranṣẹ rẹ̀ pada.” Òùngbẹ kò gbẹ wọ́n, nígbà tí ó mú wọn la inú aṣálẹ̀ kọjá, ó tú omi jáde fún wọn láti inú àpáta, ó la àpáta, omi sì tú jáde. OLUWA sọ pé, “Kò sí alaafia fún àwọn eniyan burúkú.”
Kà AISAYA 48
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: AISAYA 48:17-22
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò