AISAYA 47

47
Ìdájọ́ lórí Babiloni
1Sọ̀kalẹ̀ kí o jókòó ninu eruku, ìwọ Babiloni.
Jókòó ní ilẹ̀ẹ́lẹ̀, láìsí ìtẹ́-ọba,
ìwọ ọmọbinrin Kalidea.
A kò ní pè ọ́ ní ẹlẹgẹ́ ati aláfẹ́ mọ́.
2Gbé ọlọ kí o máa lọ ọkà,
ṣí aṣọ ìbòjú rẹ kúrò,
ká aṣọ rẹ sókè, kí o ṣí ẹsẹ̀ rẹ sílẹ̀,
kí o sì la odò kọjá.
3A óo tú ọ sí ìhòòhò,
a óo sì rí ìtìjú rẹ.
N óo gbẹ̀san,
n kò sì ní dá ẹnìkan kan sí.
4Olùràpadà wa, tí ń jẹ́ OLUWA àwọn ọmọ ogun, ni Ẹni Mímọ́ Israẹli.
5OLUWA wí nípa Kalidea pé:
“Jókòó kí o dákẹ́ jẹ́ẹ́, kí o sì wọ inú òkùnkùn lọ,
ìwọ ọmọbinrin Kalidea.
Nítorí a kò ní pè ọ́ ní ayaba àwọn orílẹ̀-èdè mọ́.
6Inú bí mi sí àwọn eniyan mi,
mo sì sọ nǹkan ìní mi di ohun ìríra.
Mo fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́,
o kò ṣàánú wọn.
O di àjàgà wúwo rẹ mọ́ àwọn arúgbó lọ́rùn.
7O sọ pé ìwọ ni o óo máa jẹ́ ayaba títí lae,
nítorí náà o kò kó àwọn nǹkan wọnyi lékàn,
o kò sì ranti ìgbẹ̀yìn wọn.
8“Nítorí náà, gbọ́ nisinsinyii, ìwọ tí o fẹ́ràn afẹ́ ayé,
tí o jókòó láìléwu,
tí ò ń sọ lọ́kàn rẹ pé,
‘Èmi nìkan ni mo wà,
kò sí ẹlòmíràn lẹ́yìn mi.
N kò ní di opó,
bẹ́ẹ̀ ni n kò ní ṣòfò ọmọ.’
9Ọ̀fọ̀ mejeeji ni yóo ṣe ọ́ lójijì,#Ifi 18:7-8
lọ́jọ́ kan náà: o óo ṣòfò ọmọ, o óo sì di opó,
ibi yìí yóo dé bá ọ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́.
Ò báà lóṣó, kí o lájẹ̀ẹ́,
kí àfọ̀ṣẹ rẹ sì múná jù bẹ́ẹ̀ lọ.
10“Ọkàn rẹ balẹ̀ ninu iṣẹ́ ibi rẹ,
o ní ẹnìkan kò rí ọ.
Ọgbọ́n ati ìmọ̀ rẹ mú ọ ṣìnà,
ò ń sọ ní ọkàn rẹ pé, ‘Èmi nìkan ní mo wà.
Kò sí ẹlòmíràn lẹ́yìn mi.’
11Ṣugbọn ibi yóo dé bá ọ,
tí o kò ní lè dáwọ́ rẹ̀ dúró;
àjálù yóo dé bá ọ,
tí o kò ní lè ṣe ètùtù rẹ̀;
ìparun yóo dé bá ọ lójijì,
tí o kò ní mọ nǹkankan nípa rẹ̀.
12Múra sí àfọ̀ṣẹ rẹ,
sì múra si oṣó ṣíṣẹ́ jọ,
tí o ti dáwọ́ lé láti kékeré,
bóyá o óo tilẹ̀ yege,
tabi bóyá o sì lè dẹ́rùba eniyan.
13Ọpọlọpọ ìmọ̀ràn tí wọn fún ọ ti sú ọ;
jẹ́ kí wọn dìde nílẹ̀ kí wọ́n gbà ọ́ wàyí,
àwọn tí ó ń wojú ọ̀run,
ati àwọn awòràwọ̀;
tí wọn ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ sí ọ,
nígbà tí oṣù bá ti lé.
14“Wò ó! Wọ́n dàbí àgékù koríko,
iná ni yóo jó wọn ráúráú,
wọn kò sì ní lè gba ara wọn kalẹ̀, ninu ọ̀wọ́ iná.
Eléyìí kì í ṣe iná tí eniyan ń yá,
kì í ṣe iná tí eniyan lè jókòó níwájú rẹ̀.
15Bẹ́ẹ̀ ni àwọn tí ẹ jọ ń ṣiṣẹ́ pọ̀ rí sí ọ,#Ais 13:1–14:23; Jer 50:1–51:64
àwọn tí ẹ ti jọ ń ṣòwò pọ̀ láti ìgbà èwe rẹ.
Olukuluku wọn ti ṣìnà lọ,
kò sí ẹni tí yóo gbà ọ́ sílẹ̀.”

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

AISAYA 47: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀