AISAYA 46

46
1“Oriṣa Bẹli tẹríba, oriṣa Nebo doríkodò.
Orí àwọn ẹran ọ̀sìn ati mààlúù ni àwọn oriṣa wọn wà.
Àwọn nǹkan tí ẹ̀ ń rù kiri wá di ẹrù, tí àwọn ẹranko tí ó ti rẹ̀ ń rù.
2Àwọn mejeeji jọ tẹríba, wọ́n jọ doríkodò,
wọn ò lè gba àwọn ẹrù wọn kalẹ̀.
Àwọn pàápàá yóo lọ sí ìgbèkùn.
3“Ẹ tẹ́tí sí mi, ẹ̀yin ará ilé Jakọbu,
ati gbogbo ará ilé Israẹli tí ó ṣẹ́kù;
ẹ̀yin tí mo pọ̀n láti ọjọ́ tí wọ́n ti bi yín,
tí mo sì gbé láti inú oyún.
4Èmi náà ni, títí di ọjọ́ ogbó yín,
n óo gbé yín títí tí ẹ óo fi hewú lórí.
Èmi ni mo da yín, n óo sì máa tọ́jú yín,
n óo máa gbé yín, n óo sì gbà yín là.
5“Ta ni ẹ óo fi mí wé?
Ta ni ẹ óo fi díwọ̀n mi?
Ta ni ẹ lè fi wé mi, kí á lè jọ jẹ́ bákan náà?
6Àwọn kan ń kó ọpọlọpọ wúrà jáde ninu àpò,
wọ́n sì ń wọn fadaka lórí ìwọ̀n.
Wọ́n sanwó ọ̀yà fún alágbẹ̀dẹ wúrà, ó bá wọn fi dá oriṣa.
Wọ́n wá ń foríbalẹ̀ fún un, wọ́n ń sìn ín.
7Wọn á gbé e lé èjìká wọn,
wọn á gbé e sípò rẹ̀, á sì dúró kabẹ̀.
Kò ní le kúrò níbẹ̀ lọ sí ibìkankan.
Bí eniyan bá ké pè é, kò lè gbọ́,
kò lè yọ eniyan ninu ìṣòro rẹ̀.
8“Ẹ ranti èyí, kí ẹ dà á rò,
ẹ fi ọkàn rò ó, ẹ̀yin ẹlẹ́ṣẹ̀.
9Ẹ ranti àwọn nǹkan ti àtijọ́,
nítorí pé èmi ni Ọlọrun, kò sí Ọlọrun mìíràn mọ́.
Èmi ni Ọlọrun, kò sí ẹni tí ó dà bí mi.
10Láti ìbẹ̀rẹ̀ ni èmi tíí sọ ohun tí ó gbẹ̀yìn.
Láti ìgbà àtijọ́,
ni mo tí ń sọ àwọn nǹkan tí kò ì tíì ṣẹlẹ̀.
Èmi a máa sọ pé: ‘Àbá mi yóo ṣẹ,
n óo sì mú ìpinnu mi ṣẹ.’
11Mo pe idì láti ìlà oòrùn,
mo sì ti pe ẹni tí yóo mú àbá mi ṣẹ láti ilẹ̀ òkèèrè wá.
Mo ti sọ̀rọ̀, n óo sì mú un ṣẹ,
mo ti ṣe ìpinnu, n óo sì ṣe é.
12“Ẹ fetí sí mi, ẹ̀yin aláìgbọràn, ẹ̀yin tí ẹ jìnnà sí ìgbàlà.
13Mo mú ìdáǹdè mi wá sí tòsí, kò jìnnà mọ́,
ìgbàlà mi kò ní pẹ́ dé.
N óo fi ìgbàlà mi sí Sioni, fún Israẹli, ògo mi.”

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

AISAYA 46: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀