AISAYA 44:1-8

AISAYA 44:1-8 YCE

OLUWA ní: “Ṣugbọn nisinsinyii, ẹ̀yin ọmọ Jakọbu iranṣẹ mi ẹ̀yin ọmọ Israẹli, àyànfẹ́ mi. Ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA, Ẹlẹ́dàá yín wí, ẹni tí ó ṣẹ̀dá yín láti inú oyún, tí yóo sì ràn yín lọ́wọ́: Ẹ má bẹ̀rù ẹ̀yin ọmọ Jakọbu, iranṣẹ mi, Jeṣuruni, ẹni tí mo yàn. “N óo tú omi sórí ilẹ̀ tí òùngbẹ ń gbẹ n óo sì ṣe odò sórí ilẹ̀ gbígbẹ. N óo tú ẹ̀mí mi sórí àwọn ọmọ yín, n óo da ibukun mi sórí arọmọdọmọ yín, wọn óo rúwé bíi koríko inú omi àní, bíi igi wilo lẹ́bàá odò tí ń ṣàn. “Ẹnìkan yóo wí pé, ‘OLUWA ló ni mí.’ Ẹnìkejì yóo pe ara rẹ̀ ní orúkọ Jakọbu. Ẹlòmíràn yóo kọ ‘Ti OLUWA ni’ sí apá rẹ̀ yóo máa fi orúkọ Israẹli ṣe àpèjá orúkọ rẹ̀.” Gbọ́ ohun tí OLUWA, ọba Israẹli ati Olùràpadà rẹ̀ wí, OLUWA àwọn ọmọ ogun, ó ní, “Èmi ni ẹni ìbẹ̀rẹ̀ ati ẹni òpin; lẹ́yìn mi, kò sí Ọlọrun mìíràn. Ta ni ó dàbí mi? Kí olúwarẹ̀ sọ̀rọ̀ kí ó kéde rẹ̀ níwájú mi. Ẹni tí ó bá ti kéde láti ìbẹ̀rẹ̀, nípa àwọn nǹkan tí yóo ṣẹlẹ̀, kí wọn sọ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ fún wa. Má bẹ̀rù, má sì fòyà. Ṣebí mo ti sọ fún ọ tipẹ́, mo ti kéde rẹ̀, ìwọ sì ni ẹlẹ́rìí mi: Ǹjẹ́ Ọlọrun mìíràn wà lẹ́yìn mi? Kò tún sí àpáta kan mọ́, n kò mọ ọ̀kan kan.”