Isa 44:1-8
Isa 44:1-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
ṢUGBỌN nisisiyi, gbọ́, iwọ Jakobu iranṣẹ mi, ati Israeli ẹniti mo ti yàn: Bayi ni Oluwa wi, ẹniti o dá ọ, ti o mọ ọ lati inu wá, ti yio si ràn ọ lọwọ; Má bẹ̀ru, iwọ Jakobu, iranṣẹ mi; ati iwọ Jeṣuruni ti mo ti yàn. Nitori emi o dà omi lu ẹniti ongbẹ ngbẹ, ati iṣàn-omi si ilẹ gbigbẹ: emi o dà ẹmi mi si iru rẹ, ati ibukun mi si iru-ọmọ rẹ. Nwọn o si hù soke lãrin koriko, bi igi willo leti ipadò. Ọkan yio wipe, ti Oluwa li emi, omiran yio si pe ara rẹ̀ nipa orukọ Jakobu; omiran yio si fi ọwọ́ rẹ̀ kọ pe, on ni ti Oluwa, yio si pe apele rẹ̀ nipa orukọ Israeli. Bayi ni Oluwa wi, Ọba Israeli, ati Olurapada rẹ, Oluwa awọn ọmọ-ogun; Emi ni ẹni-ikini, ati ẹni-ikẹhin; ati lẹhin mi ko si Ọlọrun kan. Tani yio si pè bi emi, ti yio si sọ ọ ti yio si tò o lẹsẹ-ẹsẹ fun mi, lati igbati mo ti yàn awọn enia igbani? ati nkan wọnni ti mbọ̀, ti yio si ṣẹ, ki nwọn fi hàn fun wọn. Ẹ má bẹ̀ru, ẹ má si foyà; emi ko ha ti mu nyin gbọ́ lati igba na wá, nkò ha si ti sọ ọ? ẹnyin na ni ẹlẹri mi. Ọlọrun kan mbẹ lẹhin mi bi? kò si Apata kan, emi ko mọ̀ ọkan.
Isa 44:1-8 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA ní: “Ṣugbọn nisinsinyii, ẹ̀yin ọmọ Jakọbu iranṣẹ mi ẹ̀yin ọmọ Israẹli, àyànfẹ́ mi. Ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA, Ẹlẹ́dàá yín wí, ẹni tí ó ṣẹ̀dá yín láti inú oyún, tí yóo sì ràn yín lọ́wọ́: Ẹ má bẹ̀rù ẹ̀yin ọmọ Jakọbu, iranṣẹ mi, Jeṣuruni, ẹni tí mo yàn. “N óo tú omi sórí ilẹ̀ tí òùngbẹ ń gbẹ n óo sì ṣe odò sórí ilẹ̀ gbígbẹ. N óo tú ẹ̀mí mi sórí àwọn ọmọ yín, n óo da ibukun mi sórí arọmọdọmọ yín, wọn óo rúwé bíi koríko inú omi àní, bíi igi wilo lẹ́bàá odò tí ń ṣàn. “Ẹnìkan yóo wí pé, ‘OLUWA ló ni mí.’ Ẹnìkejì yóo pe ara rẹ̀ ní orúkọ Jakọbu. Ẹlòmíràn yóo kọ ‘Ti OLUWA ni’ sí apá rẹ̀ yóo máa fi orúkọ Israẹli ṣe àpèjá orúkọ rẹ̀.” Gbọ́ ohun tí OLUWA, ọba Israẹli ati Olùràpadà rẹ̀ wí, OLUWA àwọn ọmọ ogun, ó ní, “Èmi ni ẹni ìbẹ̀rẹ̀ ati ẹni òpin; lẹ́yìn mi, kò sí Ọlọrun mìíràn. Ta ni ó dàbí mi? Kí olúwarẹ̀ sọ̀rọ̀ kí ó kéde rẹ̀ níwájú mi. Ẹni tí ó bá ti kéde láti ìbẹ̀rẹ̀, nípa àwọn nǹkan tí yóo ṣẹlẹ̀, kí wọn sọ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ fún wa. Má bẹ̀rù, má sì fòyà. Ṣebí mo ti sọ fún ọ tipẹ́, mo ti kéde rẹ̀, ìwọ sì ni ẹlẹ́rìí mi: Ǹjẹ́ Ọlọrun mìíràn wà lẹ́yìn mi? Kò tún sí àpáta kan mọ́, n kò mọ ọ̀kan kan.”
Isa 44:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Ṣùgbọ́n gbọ́ nísinsin yìí, ìwọ Jakọbu ìránṣẹ́ mi àti Israẹli, ẹni tí mo ti yàn. Ohun tí OLúWA wí nìyìí ẹni tí ó dá ọ, ẹni tí ó ti mọ̀ ọ́n láti inú ìyá rẹ wá, àti ẹni tí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ pẹ̀lú: Má ṣe bẹ̀rù, ìwọ Jakọbu, ìránṣẹ́ mi, Jeṣuruni ẹni tí mo ti yàn. Nítorí èmi yóò da omi sí ilẹ̀ tí ń pòǹgbẹ àti àwọn odò ní ilẹ̀ gbígbẹ; Èmi yóò tú Ẹ̀mí mi sí ara àwọn ọmọ rẹ, àti ìbùkún mi sórí àwọn àrọ́mọdọ́mọ rẹ. Wọn yóò dàgbàsókè gẹ́gẹ́ bí i koríko nínú pápá oko tútù, àti gẹ́gẹ́ bí igi Poplari létí odò tí ń sàn. Ọ̀kan yóò wí pé, ‘Èmi jẹ́ ti OLúWA’; òmíràn yóò pe ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí orúkọ Jakọbu; bẹ́ẹ̀ ni òmíràn yóò kọ ọ́ sí ọwọ́ rẹ̀, ‘Ti OLúWA,’ yóò sì máa jẹ́ orúkọ náà Israẹli. OLúWA “Ohun tí OLúWA wí nìyìí ọba Israẹli àti Olùdáǹdè, àní OLúWA àwọn ọmọ-ogun: Èmi ni ẹni àkọ́kọ́ àti ẹni ìgbẹ̀yìn, lẹ́yìn mi kò sí Ọlọ́run kan. Ta ni ó dàbí ì mi? Jẹ́ kí o kéde rẹ̀. Jẹ́ kí ó wí kí ó sì gbé síwájú mi Kí ni ó ti ṣẹlẹ̀ láti ìgbà tí mo fi ìdí àwọn ènìyàn ìṣẹ̀ǹbáyé kalẹ̀, àti kí ni ohun tí ń sì ń bọ̀ bẹ́ẹ̀ ni, jẹ́ kí ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ ohun tí ń bọ̀ wá. Má ṣe wárìrì, má ṣe bẹ̀rù. Ǹjẹ́ èmi kò ti kéde èyí tí mo sì ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ tipẹ́tipẹ́? Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi. Ǹjẹ́ Ọlọ́run kan ha ń bẹ lẹ́yìn mi? Bẹ́ẹ̀ kọ́, kò sí àpáta mìíràn; Èmi kò mọ ọ̀kankan.”