Ṣé o kò tíì mọ̀, o kò sì tíì gbọ́ pé Ọlọrun ayérayé ni OLUWA, Ẹlẹ́dàá gbogbo ayé. Kì í rẹ̀ ẹ́, bẹ́ẹ̀ ni agara kì í dá a. Àwámárìídìí ni òye rẹ̀. A máa fún aláàárẹ̀ ní okun. A sì máa fún ẹni tí kò lágbára ní agbára. Yóo rẹ àwọn ọ̀dọ́ pàápàá, agara óo sì dá wọn, àwọn ọdọmọkunrin yóo tilẹ̀ ṣubú lulẹ̀ patapata. Ṣugbọn àwọn tí ó bá dúró de OLUWA yóo máa gba agbára kún agbára. Wọn óo máa fi ìyẹ́ fò lọ sókè bí ẹyẹ idì. Wọn óo máa sáré, agara kò ní dá wọn; wọn óo máa rìn, kò sì ní rẹ̀ wọ́n.
Kà AISAYA 40
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: AISAYA 40:28-31
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò