Nítorí náà, ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA wí,
ẹ̀yin oníyẹ̀yẹ́ eniyan,
tí ẹ̀ ń ṣe àkóso àwọn eniyan wọnyi ní Jerusalẹmu.
Nítorí ẹ wí pé:
“A ti bá ikú dá majẹmu,
a sì ti bá ibojì ṣe àdéhùn.
Nígbà tí jamba bá ń bọ̀,
kò ní dé ọ̀dọ̀ wa;
nítorí a ti fi irọ́ ṣe ibi ìsádi wa,
a sì ti fi èké ṣe ibi ààbò.”
Nítorí náà OLUWA Ọlọrun sọ pé,
“Wò ó! Èmi yóo ri òkúta ìpìlẹ̀ ilé kan mọ́lẹ̀ ní Sioni,
yóo jẹ́ òkúta tí ó lágbára,
òkúta igun ilé iyebíye, tí ó ní ìpìlẹ̀ tí ó dájú:
Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà á gbọ́, ojú kò níí kán an.
Ìdájọ́ ẹ̀tọ́ ni n óo fi ṣe okùn ìwọnlẹ̀,
òdodo ni n óo fi ṣe ìwọ̀n ògiri.”
Òjò àdàpọ̀ mọ́ yìnyín yóo gbá ibi ààbò irọ́ dànù,
omi yóo sì bo ibi tí wọ́n sápamọ́ sí.
Majẹmu tí ẹ bá ikú dá yóo wá di òfo,
àdéhùn yín pẹlu ibojì yóo sì di asán.
Nígbà tí jamba bá ń ṣẹlẹ̀ káàkiri,
yóo máa dé ba yín.
Gbogbo ìgbà tí ó bá ti ń ṣẹlẹ̀
ni yóo máa ba yín tí yóo máa gba yín lọ.
Yóo máa ṣẹlẹ̀ láàárọ̀,
yóo sì máa ṣẹlẹ̀ tọ̀sán-tòru.
Ẹ̀rù yóo ba eniyan,
tí eniyan bá mọ ìtumọ̀ ìkìlọ̀ náà.
Ibùsùn kò ní na eniyan tán.
Bẹ́ẹ̀ ni aṣọ ìbora kò ní fẹ̀ tó eniyan bora.
Nítorí pé OLUWA yóo dìde
bí ó ti ṣe ní òkè Firasi,
yóo bínú bí ó ti bínú ní àfonífojì Gibeoni.
Yóo ṣe ohun tí ó níí ṣe,
ohun tí yóo ṣe yóo jọni lójú;
yóo ṣe iṣẹ́ rẹ̀
iṣẹ́ rẹ̀ yóo ṣe àjèjì.
Nítorí náà ẹ má ṣe yẹ̀yẹ́,
kí á má baà so ẹ̀wọ̀n yín le.
Nítorí mo ti gbọ́ ìkéde ìparun,
tí OLUWA àwọn ọmọ ogun pinnu láti mú wá sórí ilẹ̀ ayé.
Ẹ fetí sílẹ̀ kí ẹ gbọ́ ohùn mi,
ẹ tẹ́tí sílẹ̀ kí ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi,
ṣé ẹni tí ń kọ ilẹ̀ tí ó fẹ́ gbin ohun ọ̀gbìn
lè máa kọ ọ́ lọ láì dáwọ́ dúró?
Àbí ó lè máa kọ ebè lọ láì ní ààlà?
Ṣugbọn bí ó bá ti tọ́jú oko rẹ̀ tán,
ṣé kò ní fọ́n èso dili ati èso Kumini sinu rẹ̀,
kí ó gbin alikama lẹ́sẹẹsẹ;
kí ó gbin ọkà baali sí ibi tí ó yẹ,
kí ó sì gbin oríṣìí ọkà mìíràn sí ààlà oko rẹ̀?
Yóo ṣe iṣẹ́ rẹ̀ létòlétò bí ó ti yẹ,
nítorí pé Ọlọrun rẹ̀ ní ń kọ́ ọ.
Àgbẹ̀ kì í fi òkúta ńlá ṣẹ́ ẹ̀gúsí,
bẹ́ẹ̀ ni kò ní fi kùmọ̀, lu kumini.
Ọ̀pá ni wọ́n fí ń lu ẹ̀gúsí;
igi lásán ni wọ́n fí ń lu kumini.
Ǹjẹ́ eniyan a máa fi kùmọ̀ lọ ọkà alikama tí wọ́n fi ń ṣe burẹdi?
Rárá, ẹnìkan kì í máa pa ọkà títí kí ó má dáwọ́ dúró.
Bó ti wù kí eniyan fi ẹṣin yí ẹ̀rọ ìpakà lórí ọkà alikama tó,
ẹ̀rọ ìpakà kò lè lọ ọkà kúnná.
Ọ̀dọ̀ OLUWA àwọn ọmọ ogun ni ìmọ̀ yìí ti ń wá pẹlu,
ìmọ̀ràn rẹ̀ yani lẹ́nu;
ọgbọ́n rẹ̀ ni ó sì ga jùlọ.