Isa 28:14-29

Isa 28:14-29 Bibeli Mimọ (YBCV)

Nitorina ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa, ẹnyin ẹlẹgàn, ti nṣe akoso awọn enia yi ti mbẹ ni Jerusalemu. Nitori ẹnyin ti wipe, Awa ti ba ikú dá majẹmu, a si ti ba ipò-okú mulẹ: nigbati pàṣan gigun yio là a já, kì yio de ọdọ wa: nitori awa ti fi eké ṣe ãbo wa, ati labẹ irọ́ li awa ti fi ara wa pamọ: Nitorina bayi li Oluwa Jehofah wi, pe, Kiyesi i, emi gbe okuta kan kalẹ ni Sioni fun ipilẹ, okuta ti a dán wò, okuta igun-ile iyebiye, ipilẹ ti o daju: ẹniti o gbagbọ kì yio sá. Idajọ li emi o fi le ẹsẹ pẹlu, ati ododo li emi o fi lé òṣuwọn: yinyín yio gbá ãbo eke lọ, omi o si kún bò ibi isasi mọlẹ. Majẹmu nyin ti ẹ ba ikú dá li a o sọ di asan, imulẹ nyin pẹlu ipò-okú kì yio duro; nigbati paṣán gigun yio rekọja; nigbana ni on o tẹ̀ nyin mọlẹ. Niwọn igbati o ba jade lọ ni yio mu nyin: nitori ni gbogbo owurọ ni yio rekọja, li ọsan ati li oru: kiki igburo rẹ̀ yio si di ijaiyà. Nitori akete kuru jù eyiti enia le nà ara rẹ̀ si, ati ìbora kò ni ibò to eyi ti on le fi bò ara rẹ̀. Nitori Oluwa yio dide bi ti oke Perasimu, yio si binu gẹgẹ bi ti afonifoji Gibeoni, ki o ba le ṣe iṣẹ rẹ̀, iṣẹ àrà rẹ̀; yio si mu iṣe rẹ̀ ṣẹ, ajeji iṣe rẹ̀. Njẹ nitorina, ẹ máṣe jẹ ẹlẹgàn, ki a má ba sọ ìde nyin di lile; nitori emi ti gbọ́ iparun lati ọdọ Oluwa, Oluwa awọn ọmọ-ogun wá, ti o ti pinnu lori gbogbo ilẹ. Ẹ fetisilẹ, ẹ si gbọ́ ohùn mi: ẹ tẹtilelẹ, ẹ si gbọ́ ọ̀rọ mi. Gbogbo ọjọ ni agbẹ̀ ha nroko lati gbìn? on o ha ma tú, a si ma fọ́ ilẹ rẹ̀ bi? Nigbati on ti tẹ́ ojú rẹ̀ tan, on kò ha nfunrugbìn dili, ki o si fọn irugbìn kummini ka, ki o si gbìn alikama lẹsẹ-ẹsẹ, ati barle ti a yàn, ati spelti nipò rẹ̀? Nitori Ọlọrun rẹ̀ kọ́ ọ lati ni oye, o tilẹ kọ́ ọ. Nitori a kò fi ohun-elò pakà dili, bẹ̃ni a kì iyí kẹkẹ́ kiri lori kummini; ṣugbọn ọpá li a ifi pa dili jade, ọgọ li a si fi lù kummini. Akara agbado li a lọ̀; on kò le ma pa a titi, bẹ̃ni kò fi kẹkẹ́-ẹrù fọ́ ọ, bẹ̃ni kì ifi awọn ẹlẹṣin rẹ̀ tẹ̀ ẹ. Eyi pẹlu ti ọdọ Oluwa awọn ọmọ-ogun wá, ẹniti o kún fun iyanu ni ìmọ, ti o tayọ ni iṣe.

Isa 28:14-29 Yoruba Bible (YCE)

Nítorí náà, ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA wí, ẹ̀yin oníyẹ̀yẹ́ eniyan, tí ẹ̀ ń ṣe àkóso àwọn eniyan wọnyi ní Jerusalẹmu. Nítorí ẹ wí pé: “A ti bá ikú dá majẹmu, a sì ti bá ibojì ṣe àdéhùn. Nígbà tí jamba bá ń bọ̀, kò ní dé ọ̀dọ̀ wa; nítorí a ti fi irọ́ ṣe ibi ìsádi wa, a sì ti fi èké ṣe ibi ààbò.” Nítorí náà OLUWA Ọlọrun sọ pé, “Wò ó! Èmi yóo ri òkúta ìpìlẹ̀ ilé kan mọ́lẹ̀ ní Sioni, yóo jẹ́ òkúta tí ó lágbára, òkúta igun ilé iyebíye, tí ó ní ìpìlẹ̀ tí ó dájú: Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà á gbọ́, ojú kò níí kán an. Ìdájọ́ ẹ̀tọ́ ni n óo fi ṣe okùn ìwọnlẹ̀, òdodo ni n óo fi ṣe ìwọ̀n ògiri.” Òjò àdàpọ̀ mọ́ yìnyín yóo gbá ibi ààbò irọ́ dànù, omi yóo sì bo ibi tí wọ́n sápamọ́ sí. Majẹmu tí ẹ bá ikú dá yóo wá di òfo, àdéhùn yín pẹlu ibojì yóo sì di asán. Nígbà tí jamba bá ń ṣẹlẹ̀ káàkiri, yóo máa dé ba yín. Gbogbo ìgbà tí ó bá ti ń ṣẹlẹ̀ ni yóo máa ba yín tí yóo máa gba yín lọ. Yóo máa ṣẹlẹ̀ láàárọ̀, yóo sì máa ṣẹlẹ̀ tọ̀sán-tòru. Ẹ̀rù yóo ba eniyan, tí eniyan bá mọ ìtumọ̀ ìkìlọ̀ náà. Ibùsùn kò ní na eniyan tán. Bẹ́ẹ̀ ni aṣọ ìbora kò ní fẹ̀ tó eniyan bora. Nítorí pé OLUWA yóo dìde bí ó ti ṣe ní òkè Firasi, yóo bínú bí ó ti bínú ní àfonífojì Gibeoni. Yóo ṣe ohun tí ó níí ṣe, ohun tí yóo ṣe yóo jọni lójú; yóo ṣe iṣẹ́ rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ yóo ṣe àjèjì. Nítorí náà ẹ má ṣe yẹ̀yẹ́, kí á má baà so ẹ̀wọ̀n yín le. Nítorí mo ti gbọ́ ìkéde ìparun, tí OLUWA àwọn ọmọ ogun pinnu láti mú wá sórí ilẹ̀ ayé. Ẹ fetí sílẹ̀ kí ẹ gbọ́ ohùn mi, ẹ tẹ́tí sílẹ̀ kí ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, ṣé ẹni tí ń kọ ilẹ̀ tí ó fẹ́ gbin ohun ọ̀gbìn lè máa kọ ọ́ lọ láì dáwọ́ dúró? Àbí ó lè máa kọ ebè lọ láì ní ààlà? Ṣugbọn bí ó bá ti tọ́jú oko rẹ̀ tán, ṣé kò ní fọ́n èso dili ati èso Kumini sinu rẹ̀, kí ó gbin alikama lẹ́sẹẹsẹ; kí ó gbin ọkà baali sí ibi tí ó yẹ, kí ó sì gbin oríṣìí ọkà mìíràn sí ààlà oko rẹ̀? Yóo ṣe iṣẹ́ rẹ̀ létòlétò bí ó ti yẹ, nítorí pé Ọlọrun rẹ̀ ní ń kọ́ ọ. Àgbẹ̀ kì í fi òkúta ńlá ṣẹ́ ẹ̀gúsí, bẹ́ẹ̀ ni kò ní fi kùmọ̀, lu kumini. Ọ̀pá ni wọ́n fí ń lu ẹ̀gúsí; igi lásán ni wọ́n fí ń lu kumini. Ǹjẹ́ eniyan a máa fi kùmọ̀ lọ ọkà alikama tí wọ́n fi ń ṣe burẹdi? Rárá, ẹnìkan kì í máa pa ọkà títí kí ó má dáwọ́ dúró. Bó ti wù kí eniyan fi ẹṣin yí ẹ̀rọ ìpakà lórí ọkà alikama tó, ẹ̀rọ ìpakà kò lè lọ ọkà kúnná. Ọ̀dọ̀ OLUWA àwọn ọmọ ogun ni ìmọ̀ yìí ti ń wá pẹlu, ìmọ̀ràn rẹ̀ yani lẹ́nu; ọgbọ́n rẹ̀ ni ó sì ga jùlọ.

Isa 28:14-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nítorí náà, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ OLúWA, ẹ̀yin ẹlẹ́gàn, tí ń jẹ ọba lórí àwọn ènìyàn wọ̀nyí ní Jerusalẹmu. Ẹ fọ́n pé, “Àwa ti bá ikú mulẹ̀, pẹ̀lú ibojì ni àwa ti jọ ṣe àdéhùn. Nígbà tí ìbáwí gbígbóná fẹ́ kọjá, kò le kàn wá lára, nítorí a ti fi irọ́ ṣe ààbò o wa àti àìṣòótọ́ ibi ìpamọ́ wa.” Nítorí náà, báyìí ni OLúWA Olódùmarè wí: “Kíyèsi i, èmi gbé òkúta kan lélẹ̀ ní Sioni, òkúta tí a dánwò, òkúta igun ilé iyebíye fún ìpìlẹ̀ tí ó dájú; ẹnikẹ́ni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé kì yóò ní ìfòyà. Èmi yóò fi ìdájọ́ ṣe okùn òṣùwọ̀n àti òdodo òjé òṣùwọ̀n; yìnyín yóò gbá ààbò yín dànù àti irọ́, omi yóò sì kún bo gbogbo ibi tí ẹ ń fi ara pamọ́ sí mọ́lẹ̀. Májẹ̀mú yín tí ẹ bá ikú dá ni a ó fa igi lé; àdéhùn yín pẹ̀lú ibojì ni kì yóò dúró. Nígbà tí ìbínú gbígbóná náà bá fẹ́ kọjá, a ó ti ipa rẹ̀ lù yín bolẹ̀. Nígbàkúgbà tí ó bá ti wá ni yóò máa gbé ọ lọ, ni àràárọ̀, ní ọ̀sán àti ní òru, ni yóò máa fẹ́ kọjá lọ.” Ìmòye ọ̀rọ̀-ìmọ̀ yìí yóò máa mú ìpayà ńlá wá. Ibùsùn kúrú púpọ̀ fún ìnara lé lórí, ìbora kò fẹ̀ tó láti yí ara yín ká. OLúWA yóò dìde sókè gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ní òkè Peraṣimu yóò ru ara rẹ̀ sókè gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ní Àfonífojì Gibeoni— láti ṣe iṣẹ́ rẹ̀, abàmì iṣẹ́ ẹ rẹ̀, yóò ṣe iṣẹ́ rẹ̀, àní àjèjì iṣẹ́ rẹ̀. Ní ìsinsin yìí ẹ dákẹ́ ẹlẹ́yà ṣíṣe, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ ìdè e yín yóò le sí i; OLúWA, àní OLúWA àwọn ọmọ-ogun ti sọ fún mi nípa àṣẹ ìparun ti ó ti pa lórí gbogbo ilẹ̀ náà. Tẹ́tí kí o sì gbọ́ ohùn mi, fi ara balẹ̀ kí o sì gbọ́ ohun tí mo sọ. Nígbà tí àgbẹ̀ kan bá tu ilẹ̀ láti gbìn yóò ha máa tulẹ̀ títí bi? Ǹjẹ́ yóò ha máa tu ilẹ̀ kí ó sì máa jọ̀ ọ́ títí lọ bí? Nígbà tí òun bá ti tẹ́ ojú ilẹ̀ rẹ̀ pẹrẹsẹ òun kò ha ń fúnrúgbìn dílì kí ó sì fúnrúgbìn kummini ká? Kí ó sì gbin alikama lẹ́sẹẹsẹ, barle tí a yàn, àti spelti ní ipò rẹ̀? Ọlọ́run rẹ̀ tọ́ ọ ṣọ́nà ó sì kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ ní ọ̀nà tó tọ́. Nítorí a kò fi ohun èlò ìpakà dili, bẹ́ẹ̀ ni a kì í yí kẹ̀kẹ́ ẹrù kiri lórí kummini; ṣùgbọ́n ọ̀pá ni a fi ń pa dili jáde, ọ̀gọ ni a sì lu kummini. A gbọdọ̀ lọ ìyẹ̀fun kí a tó ṣe àkàrà; bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkan kì í máa pa á lọ títí láé. Bí ó tilẹ̀ yí ẹsẹ̀ kẹ̀kẹ́ ìpakà a rẹ̀ lórí i rẹ̀, àwọn ẹṣin rẹ̀ kò le lọ̀ ọ́. Gbogbo èyí pẹ̀lú ti ọ̀dọ̀ OLúWA àwọn ọmọ-ogun wá, oníyanu ní ìmọ̀ràn àti ológo ní ọgbọ́n.