HOSIA 4

4
OLUWA Fi Ẹ̀sùn Kan Israẹli
1Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ OLUWA, ẹ̀yin ọmọ Israẹli; OLUWA fi ẹ̀sùn kan gbogbo àwọn tí wọn ń gbé ilẹ̀ Israẹli pé, “Kò sí òtítọ́, tabi àánú, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ìmọ̀ Ọlọrun ní ilẹ̀ náà, 2àfi ìbúra èké ati irọ́ pípa; ìpànìyàn, olè jíjà ati àgbèrè ni ó pọ̀ láàrin wọn. Wọ́n ń yẹ àdéhùn, wọ́n ń paniyan léraléra. 3Nítorí náà, ilẹ̀ náà ń ṣọ̀fọ̀, gbogbo àwọn tí wọn ń gbé ibẹ̀ ń jìyà, àwọn ẹranko, àwọn ẹyẹ, ati àwọn ẹja sì ń ṣègbé.”
Ọlọrun Fi Ẹ̀sùn Kan Àwọn Alufaa
4Ọlọrun ní, Kí ẹnikẹ́ni má ṣe jiyàn, ẹ kò sì gbọdọ̀ ka ẹ̀sùn sí ẹnikẹ́ni lẹ́sẹ̀, nítorí pé ẹ̀yin alufaa gan-an ni mò ń fi ẹ̀sùn kàn. 5Nítorí ẹ óo fẹsẹ̀ kọ lojumọmọ, ẹ̀yin wolii pàápàá yóo kọsẹ̀ lóru, n óo sì pa Israẹli, ìyá yín run. 6Àwọn eniyan mi ń ṣègbé nítorí àìsí ìmọ̀; nítorí pé ẹ̀yin alufaa ti kọ ìmọ̀ mi sílẹ̀, èmi náà yóo kọ̀ yín ní alufaa mi. Nítorí pé ẹ ti gbàgbé òfin Ọlọrun yín, èmi náà yóo gbàgbé àwọn ọmọ yín.
7“Bí ẹ̀yin alufaa ti ń pọ̀ sí i, ni ẹ̀ṣẹ̀ yín náà ń pọ̀ sí i, n óo yí ògo wọn pada sí ìtìjú. 8Ẹ̀ ń fi ẹ̀ṣẹ̀ àwọn eniyan mi wá oúnjẹ fún ara yín, ẹ sì ń mú kí wọ́n máa dá ẹ̀ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀ 9Ìyà kan náà ni ẹ̀yin alufaa ati àwọn eniyan yóo jẹ, n óo jẹ yín níyà nítorí ìwà burúkú yín, n óo sì gbẹ̀san lára yín nítorí ìṣe yín. 10Ẹ óo máa jẹun, ṣugbọn ẹ kò ní yó; Ẹ óo máa ṣe àgbèrè ẹ̀sìn, ṣugbọn ẹ kò ní pọ̀ sí i; nítorí ẹ ti kọ èmi Ọlọrun sílẹ̀ ẹ sì yipada sí ìwà ìbọkúbọ.”
OLUWA Kọ Ìbọ̀rìṣà
11OLUWA ní, “Ọtí waini ati waini tuntun ti ra àwọn eniyan mi níyè. 12Wọ́n ń wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ igi gbígbẹ́, ọ̀pá wọn ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún wọn. Ẹ̀mí àgbèrè ẹ̀sìn ti mú wọn ṣáko, wọ́n ti kọ Ọlọrun wọn sílẹ̀ láti máa bọ ìbọkúbọ. 13Wọ́n ń rúbọ lórí òkè gíga, wọ́n ń sun turari lórí òkè kéékèèké, ati lábẹ́ igi oaku, ati igi populari ati igi terebinti, nítorí òjìji abẹ́ wọn tutù. Nítorí náà ni àwọn ọmọbinrin yín ṣe di aṣẹ́wó, àwọn aya yín sì di alágbèrè. 14Ṣugbọn n kò ní jẹ àwọn ọmọbinrin yín níyà nígbà tí wọ́n bá ń ṣe aṣẹ́wó, tabi kí n jẹ àwọn aya yín níyà nígbà tí wọ́n bá ṣe àgbèrè; nítorí pé, àwọn ọkunrin yín pàápàá ń bá àwọn aṣẹ́wó lòpọ̀, wọ́n sì ń bá àwọn aṣẹ́wó ilé oriṣa rúbọ. Àwọn tí wọn kò bá ní ìmọ̀ yóo sì parun.
15“Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ò ń ṣe àgbèrè ẹ̀sìn, ìwọ Israẹli, má kó ẹ̀bi bá Juda. Má wọ Giligali lọ bọ̀rìṣà, má sì gòkè lọ sí Betafeni, má sì lọ búra níbẹ̀ pé, ‘Bí OLUWA tí ń bẹ.’ 16Israẹli ń ṣe agídí bí ọ̀dọ́ mààlúù tí ó ya olóríkunkun; ṣe OLUWA lè máa bọ́ wọn bí aguntan nisinsinyii lórí pápá tí ó tẹ́jú. 17Ìbọ̀rìṣà ti wọ Efuraimu lẹ́wù, ẹ fi wọ́n sílẹ̀. 18Ẹgbẹ́ ọ̀mùtí ni wọ́n, wọ́n fi ara wọn fún ìwà àgbèrè, ìtìjú yá wọn lára ju ògo lọ. 19Afẹ́fẹ́ yóo gbá wọn lọ, ojú ìsìn ìbọ̀rìṣà wọn yóo sì tì wọ́n.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

HOSIA 4: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀