HOSIA 5

5
1“Ẹ gbọ́, ẹ̀yin alufaa! Ẹ tẹ́tí sílẹ̀, ẹ̀yin ọmọ Israẹli ati ẹ̀yin ìdílé ọba! Ẹ̀yin ni ìdájọ́ náà dé bá; nítorí ẹ dàbí tàkúté ní Misipa, ati bí àwọ̀n tí a ta sílẹ̀ lórí òkè Tabori. 2Wọ́n ti gbẹ́ kòtò jíjìn ní ìlú Ṣitimu; ṣugbọn n óo jẹ wọ́n níyà. 3Mo mọ Efuraimu, bẹ́ẹ̀ ni Israẹli kò ṣàjèjì sí mi; nisinsinyii, ìwọ Efuraimu ti ṣe àgbèrè ẹ̀sìn, Israẹli sì ti di aláìmọ́.”
Ìkìlọ̀ Hosia nípa Ìwà Ìbọ̀rìṣà
4Gbogbo ibi tí wọn ń ṣe, kò jẹ́ kí wọ́n lè pada sọ́dọ̀ Ọlọrun wọn, nítorí pé ọkàn wọn kún fún ẹ̀mí àgbèrè, wọn kò sì mọ OLUWA. 5Ìgbéraga Israẹli hàn kedere lójú rẹ̀; Efuraimu yóo kọsẹ̀, yóo sì ṣubú ninu ìwà burúkú rẹ̀, Juda náà yóo ṣubú pẹlu wọn. 6Wọn yóo mú mààlúù ati aguntan wá, láti fi wá ojurere OLUWA, ṣugbọn wọn kò ní rí i; nítorí pé, ó ti fi ara pamọ́ fún wọn. 7Wọ́n ti hùwà aiṣootọ sí OLUWA; nítorí pé wọ́n ti bí ọmọ àjèjì. Oṣù tuntun ni yóo run àtàwọn, àtoko wọn.
Ogun láàrin Juda ati Israẹli
8Ẹ fọn fèrè ní Gibea, ẹ fọn fèrè ogun ní Rama, ẹ pariwo ogun ní Betafeni, ogun dé o, ẹ̀yin ará Bẹnjamini! 9Efuraimu yóo di ahoro ní ọjọ́ ìjìyà; mo ti fi ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ dájúdájú hàn, láàrin àwọn ẹ̀yà Israẹli.
10OLUWA wí pé: “Àwọn olórí ní Juda dàbí àwọn tí wọn ń yí ààlà ilẹ̀ pada, n óo da ibinu mi sórí wọn, bí ẹni da omi. 11Ìyà ń jẹ Efuraimu, ìdájọ́ ìparun sì ti dé bá a, nítorí pé, ó ti pinnu láti máa tẹ̀lé ohun asán. 12Nítorí náà, mo dàbí kòkòrò ajẹnirun sí Efuraimu, ati bí ìdíbàjẹ́ sí Juda.
13“Nígbà tí Efuraimu rí àìsàn rẹ̀, tí Juda sì rí ọgbẹ́ rẹ̀, Efuraimu sá tọ Asiria lọ, ó sì ranṣẹ sí ọba ńlá ibẹ̀. Ṣugbọn kò lè wo àìsàn Israẹli tabi kí ó wo ọgbẹ́ rẹ̀ sàn. 14Bíi kinniun ni n óo rí sí Efuraimu, n óo sì fò mọ́ Juda bí ọ̀dọ́ kinniun. Èmi fúnra mi ni n óo fà wọ́n ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, n óo sì kúrò níbẹ̀. N óo kó wọn lọ, kò sì ní sí ẹni tí yóo lè gbà wọ́n sílẹ̀.
15“N óo pada sí ibùgbé mi títí wọn yóo fi mọ ẹ̀bi wọn, tí wọn yóo sì máa wá mi nígbà tí ojú bá pọ́n wọn.”

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

HOSIA 5: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀