Ẹ pada tọ OLUWA Ọlọrun yín lọ, ẹ̀yin ọmọ Israẹli, nítorí pé ẹ ti kọsẹ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín. Ẹ pada sọ́dọ̀ OLUWA, kí ẹ sọ pé, “Mú ẹ̀ṣẹ̀ wa kúrò, gba ohun tí ó dára a óo sì máa yìn ọ́ lógo. Asiria kò lè gbà wá là, bẹ́ẹ̀ ni a kò ní gun ẹṣin; a kò sì ní pe oriṣa, tíí ṣe iṣẹ́ ọwọ́ wa, ní Ọlọrun wa mọ́. OLUWA, ìwọ ni ò ń ṣàánú fún ọmọ tí kò lẹ́nìkan.” Ọlọrun ní, “N óo gba ìwà aiṣootọ lọ́wọ́ wọn, n óo fẹ́ wọn tọkàntọkàn, nítorí n kò bínú sí wọn mọ́. Bí ìrì ni n óo máa sẹ̀ sí Israẹli, ẹwà rẹ̀ yóo yọ bí òdòdó lílì, gbòǹgbò rẹ̀ yóo sì múlẹ̀ bíi gbòǹgbò igi kedari Lẹbanoni. Àwọn ẹ̀ka rẹ̀ yóo tàn kálẹ̀; ẹwà rẹ̀ yóo yọ bíi ti igi olifi, òórùn rẹ̀ yóo sì dàbí ti igi Lẹbanoni. Wọn óo pada sábẹ́ ààbò mi, wọn óo rúwé bí igi inú ọgbà; wọn óo sì tanná bí àjàrà, òórùn wọn óo dàbí ti waini Lẹbanoni.
Kà HOSIA 14
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: HOSIA 14:1-7
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò