Yípadà ìwọ Israẹli sí OLúWA Ọlọ́run rẹ. Ẹ̀ṣẹ̀ rẹ ló fa ìparun rẹ! Ẹ gba ọ̀rọ̀ OLúWA gbọ́, kí ẹ sì yípadà sí OLúWA. Ẹ sọ fún un pé: “Darí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá kí o sì fi oore-ọ̀fẹ́ gbà wá, kí àwa kí ó lè fi ètè wa sán an fún ọ Asiria kò le gbà wá là; A kò ní í gorí ẹṣin ogun A kò sì ní tún sọ ọ́ mọ́ láé ‘Àwọn ni òrìṣà wa sí àwọn ohun tí ó fi ọwọ́ wa ṣe; nítorí pé lọ́dọ̀ rẹ ni àwọn aláìní baba tí ń rí àánú.’ “Èmi wo àgàbàgebè wọn sàn, Èmi ó sì fẹ́ràn wọn, lọ́fẹ̀ẹ́, nítorí ìbínú mi ti yípadà kúrò lọ́dọ̀ wọn. Èmi o dàbí ìrì sí Israẹli wọn o sì yọ ìtànná bi ewéko lílì Bi kedari ti Lebanoni yóò si ta gbòǹgbò Àṣẹ̀ṣẹ̀yọ ẹ̀ka rẹ̀ yóò dàgbà, Dídán ẹwà yóò rẹ̀ dànù bí igi olifi Òórùn rẹ yóò sì dàbí igi kedari ti Lebanoni. Àwọn ènìyàn yóò tún padà gbé lábẹ́ òjijì rẹ̀. Yóò rúwé bi ọkà. Yóò sì yọ ìtànná bi àjàrà, òórùn rẹ yóò dàbí ti wáìnì Lebanoni.
Kà Hosea 14
Feti si Hosea 14
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Hosea 14:1-7
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò