HOSIA 14
14
Ẹ̀bẹ̀ Hosia fún Israẹli
1Ẹ pada tọ OLUWA Ọlọrun yín lọ, ẹ̀yin ọmọ Israẹli, nítorí pé ẹ ti kọsẹ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín. 2Ẹ pada sọ́dọ̀ OLUWA, kí ẹ sọ pé, “Mú ẹ̀ṣẹ̀ wa kúrò, gba ohun tí ó dára a óo sì máa yìn ọ́ lógo. 3Asiria kò lè gbà wá là, bẹ́ẹ̀ ni a kò ní gun ẹṣin; a kò sì ní pe oriṣa, tíí ṣe iṣẹ́ ọwọ́ wa, ní Ọlọrun wa mọ́. OLUWA, ìwọ ni ò ń ṣàánú fún ọmọ tí kò lẹ́nìkan.”
OLUWA Ṣèlérí Ìgbé-Ayé Titun fún Israẹli
4Ọlọrun ní,
“N óo gba ìwà aiṣootọ lọ́wọ́ wọn,
n óo fẹ́ wọn tọkàntọkàn,
nítorí n kò bínú sí wọn mọ́.
5Bí ìrì ni n óo máa sẹ̀ sí Israẹli,
ẹwà rẹ̀ yóo yọ bí òdòdó lílì,
gbòǹgbò rẹ̀ yóo sì múlẹ̀ bíi gbòǹgbò igi kedari Lẹbanoni.
6Àwọn ẹ̀ka rẹ̀ yóo tàn kálẹ̀;
ẹwà rẹ̀ yóo yọ bíi ti igi olifi,
òórùn rẹ̀ yóo sì dàbí ti igi Lẹbanoni.
7Wọn óo pada sábẹ́ ààbò mi,
wọn óo rúwé bí igi inú ọgbà;
wọn óo sì tanná bí àjàrà,
òórùn wọn óo dàbí ti waini Lẹbanoni.
8Efuraimu yóo sọ pé, ‘kí ni mo ní ṣe pẹlu àwọn oriṣa?’
Nítorí èmi ni n óo máa gbọ́ adura rẹ̀,
tí n óo sì máa tọ́jú rẹ̀.
Mo dàbí igi sipirẹsi tí kì í wọ́wé tòjò tẹ̀ẹ̀rùn.
Lọ́dọ̀ mi ni èso rẹ̀ ti ń wá.”
Ọ̀rọ̀ Ìparí
9Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbọ́n, kí ó mọ àwọn nǹkan wọnyi; kí òye rẹ̀ sì yé ẹnikẹ́ni tí ó bá lóye; nítorí pé ọ̀nà OLUWA tọ́, àwọn tí wọ́n bá dúró ṣinṣin ni yóo máa tọ̀ ọ́, ṣugbọn àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ yóo kọsẹ̀ níbẹ̀.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
HOSIA 14: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010