HEBERU 8

8
Olórí Alufaa ti Majẹmu Titun
1Kókó ohun tí à ń sọ nìyí, pé a ní irú Olórí Alufaa báyìí, ẹni tí ó jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún ìtẹ́ ọlá ńlá ní ọ̀run.#O. Daf 110:1 2Òun yìí ni òjíṣẹ́ ní ilé ìsìn tí ó mọ́ jùlọ tíí ṣe àgọ́ tòótọ́, tí Oluwa fúnrarẹ̀ kọ́, kì í ṣe èyí tí eniyan kọ́.
3Nítorí gbogbo Olórí Alufaa tí a bá yàn, a yàn wọ́n pé kí wọ́n máa mú ẹ̀bùn ati ẹbọ àwọn eniyan wá siwaju Ọlọrun ni. Bákan náà ni òun náà níláti ní àwọn ohun tí yóo máa mú wá siwaju Ọlọrun. 4Bí ó bá jẹ́ pé ó wà ninu ayé, kì bá tí jẹ́ alufaa rárá, nítorí àwọn alufaa wà tí wọn ń mú ẹ̀bùn àwọn eniyan lọ siwaju Ọlọrun gẹ́gẹ́ bí ìlànà òfin. 5Àwọn yìí ń ṣe ìsìn wọn ninu ilé ìsìn tí ó jẹ́ ẹ̀dà ati àfijọ ti ọ̀run. A rí i pé bẹ́ẹ̀ ni ó rí nítorí nígbà tí Mose fẹ́ kọ́ àgọ́, ohun tí Ọlọrun sọ fún un ni pé, “Ṣe akiyesi pé o ṣe ohun gbogbo gẹ́gẹ́ bí àwòrán tí mo fihàn ọ́ ní orí òkè.”#Eks 25:40 6Ṣugbọn nisinsinyii iṣẹ́ ìsìn ti Olórí Alufaa wa dára pupọ ju ti àwọn ọmọ Lefi lọ, nítorí pé majẹmu tí ó jẹ́ alárinà fún dára ju ti àtijọ́ lọ, ìdí ni pé ìlérí tí ó dára ju ti àtijọ́ lọ ni majẹmu yìí dúró lé lórí.
7Bí majẹmu ti àkọ́kọ́ kò bá ní àbùkù, kò sí ìdí tí à bá fi fi òmíràn dípò rẹ̀. 8Nítorí Ọlọrun rí ẹ̀ṣẹ̀ kà sí wọn lọ́rùn ni ó fi sọ pé,
“Oluwa wí pé:
Ọjọ́ ń bọ̀ tí èmi yóo bá ilé Israẹli ati ilé Juda dá majẹmu titun.#Jer 31:31-34
9Kì í ṣe irú majẹmu tí mo bá àwọn baba wọn dá
ní ọjọ́ tí mo fà wọ́n lọ́wọ́ jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti.
Nítorí wọn kò pa majẹmu mi mọ́,
mo bá kẹ̀yìn sí wọn.
10Èyí ni majẹmu tí n óo bá ilé Israẹli dá nígbà tí ó bá yá. N óo fi òfin mi sí inú wọn, n óo kọ ọ́ sí ọkàn wọn, èmi óo jẹ́ Ọlọrun wọn, àwọn náà yóo sì jẹ́ eniyan mi.
11Kì yóo sí ìdí tí ẹnìkan yóo fi kọ́ aládùúgbò rẹ̀ tabi arakunrin rẹ̀, pé,
‘Mọ Oluwa.’
Nítorí pé gbogbo wọn ni wọn óo mọ̀ mí,
ohun tí ó ṣẹ̀ láti orí àwọn mẹ̀kúnnù inú wọn títí dé orí àwọn eniyan pataki pataki.
12Nítorí n óo fi àánú fojú fo ìwà burúkú wọn,
n kò sì ní ranti ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́.”
13Nígbà tí ó sọ̀rọ̀ nípa majẹmu titun, ohun tí ó ń sọ ni pé ti àtijọ́ ti di ògbólógbòó. Ohun tí ó bá sì ti di ògbólógbòó, kò níí pẹ́ parẹ́.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

HEBERU 8: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀