HEBERU 7

7
Irú Alufaa tí Mẹlikisẹdẹki Jẹ́
1Nítorí Mẹlikisẹdẹki yìí jẹ́ ọba Salẹmu ati alufaa Ọlọrun Ọ̀gá Ògo. Òun ni ó pàdé Abrahamu nígbà tí Abrahamu ń pada bọ̀ láti ojú-ogun lẹ́yìn tí ó bá ọba mẹrin jà, tí ó sì pa wọ́n ní ìpakúpa. Ó bá súre fún Abrahamu. 2Abrahamu fún un ní ìdámẹ́wàá gbogbo ìkógun. Ní àkọ́kọ́, ìtumọ̀ orúkọ rẹ̀ ni “ọba òdodo.” Lẹ́yìn náà, ó tún jẹ́ ọba Salẹmu, èyí ni “ọba alaafia.”#Nọm 18:21 3Kò sí àkọsílẹ̀ pé ó ní baba tabi ìyá; kò ní ìtàn ìdílé. Kò sí àkọsílẹ̀ ìbẹ̀rẹ̀ tabi òpin ìgbé-ayé rẹ̀. Ó jẹ́ àwòrán Ọmọ Ọlọrun. Ó jẹ́ alufaa nígbà gbogbo.
4Ẹ kò rí bí ọkunrin yìí ti jẹ́ eniyan pataki tó, tí Abrahamu baba-ńlá wa fi fún un ní ìdámẹ́wàá àwọn nǹkan àṣàyàn ninu ìkógun rẹ̀. 5Àwọn ọmọ Lefi ni wọ́n ní àṣẹ láti gba ìdámẹ́wàá lọ́wọ́ àwọn eniyan gẹ́gẹ́ bí ìlànà òfin. Wọ́n ń gba ìdámẹ́wàá lọ́wọ́ àwọn eniyan wọn tí wọ́n jẹ́ ìran Abrahamu. 6Ṣugbọn Mẹlikisẹdẹki tí kì í ṣe ìran Abrahamu gba ìdámẹ́wàá lọ́wọ́ rẹ̀, ó sì súre fún Abrahamu tí ó rí àwọn ìlérí Ọlọrun gbà. 7Láìṣe àní-àní, ẹni tí ó bá tóbi ju eniyan lọ níí súre fún un. 8Ati pé, àwọn ọmọ Lefi tí wọn ń gba ìdámẹ́wàá, ẹni tí yóo kú ni wọ́n. Ṣugbọn Ìwé Mímọ́ sọ nípa Mẹlikisẹdẹki pé ó wà láàyè. 9A lè sọ pé nígbà tí Abrahamu san ìdámẹ́wàá, Lefi tí ń gba ìdámẹ́wàá náà san ìdámẹ́wàá, 10nítorí a lè sọ pé ó wà ní ara Abrahamu baba-ńlá rẹ̀ nígbà tí Mẹlikisẹdẹki pàdé rẹ̀.
11Nítorí náà, bí ó bá jẹ́ pé ètò iṣẹ́ alufaa ti ìdílé Lefi kò ní àbùkù, tí ó sì jẹ́ pé nípa rẹ̀ ni àwọn eniyan fi gba òfin, kí ló dé tí a fi tún ṣe ètò alufaa ní ìgbésẹ̀ Mẹlikisẹdẹki, tí kò fi jẹ́ ti Aaroni? 12Nítorí bí a bá yí ètò iṣẹ́ alufaa pada, ó níláti jẹ́ pé a yí òfin náà pada. 13Ẹni tí à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí wá láti inú ẹ̀yà mìíràn. Ninu ẹ̀yà yìí ẹ̀wẹ̀, kò sí ẹnikẹ́ni tí ó ní nǹkankan ṣe pẹlu ẹbọ rírú. 14Nítorí ó hàn gbangba pé láti inú ẹ̀yà Juda ni Oluwa wa ti wá. Mose kò sì sọ ohunkohun tí ó jẹ mọ́ iṣẹ́ alufaa nípa ẹ̀yà yìí.
Oyè Alufaa Titun, Gẹ́gẹ́ Bíi ti Mẹlikisẹdẹki
15Ohun tí à ń sọ hàn kedere nígbà tí a rí i pé a yan alufaa mìíràn gẹ́gẹ́ bí àwòrán Mẹlikisẹdẹki, 16ẹni tí ó di alufaa nípa agbára ìyà tí kò lópin, tí kì í ṣe nípa ìlànà àṣẹ tí a ti ọwọ́ eniyan ṣe ètò. 17Nítorí a rí ẹ̀rí níbìkan pé,
“Ìwọ yóo jẹ́ alufaa títí lae,
gẹ́gẹ́ bíi ti Mẹlikisẹdẹki.”#O. Daf 110:4
18A pa àṣẹ ti àkọ́kọ́ tì nítorí kò lágbára, kò sì wúlò. 19Nítorí kò sí ohun tí òfin sọ di pípé. A wá ṣe ètò ìrètí tí ó dára ju òfin lọ nípa èyí tí a lè fi súnmọ́ Ọlọrun.
20Ìrètí yìí ní ìbúra ninu. Àwọn ọmọ Lefi di alufaa láìsí ìbúra. 21Ṣugbọn pẹlu ìbúra ni, nígbà tí Ọlọrun sọ fún un pé,
“Oluwa ti búra,
kò ní yí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pada:
‘Ìwọ máa jẹ́ alufaa títí lae.’ ”#O. Daf 110:4
22Báyìí ni Jesu ṣe di onígbọ̀wọ́ majẹmu tí ó dára ju ti àtijọ́ lọ.
23Àwọn alufaa ìdílé Lefi pọ̀ nítorí ikú kò jẹ́ kí èyíkéyìí ninu wọn lè wà títí ayé. 24Ṣugbọn ní ti Jesu, ó wà títí. Nítorí náà kò sí ìdí tí a óo fi tún yan alufaa mìíràn dípò rẹ̀. 25Ìdí nìyí tí ó fi lè gba àwọn tí wọ́n bá súnmọ́ Ọlọrun nípasẹ̀ rẹ̀ là, lọ́nà gbogbo títí lae nítorí pé ó wà láàyè títí láti máa bẹ̀bẹ̀ fún wọn.
26Irú olórí alufaa bẹ́ẹ̀ ni ó yẹ wá. Ẹni mímọ́; tí kò ní ẹ̀tàn, tí kò ní àbùkù, tí kò bá àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ kẹ́gbẹ́, tí a gbé ga kọjá àwọn ọ̀run. 27Òun kì í ṣe ẹni tí ó níláti kọ́kọ́ rúbọ lojoojumọ fún ẹ̀ṣẹ̀ ti ara rẹ̀, kí ó tó wá rúbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn eniyan, bí àwọn olórí alufaa ti ìdílé Lefi ti ń ṣe. Nítorí lẹ́ẹ̀kan náà ni ó ti ṣe èyí, nígbà tí ó fi ara rẹ̀ rúbọ.#Lef 9:7 28Nítorí àwọn tí à ń yàn bí olórí alufaa lábẹ́ òfin Mose jẹ́ eniyan, wọ́n sì ní àìlera. Ṣugbọn olórí alufaa tí a yàn nípa ọ̀rọ̀ ìbúra tí ó dé lẹ́yìn òfin ni Ọmọ Ọlọrun tí a ṣe ní àṣepé títí lae.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

HEBERU 7: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀