HEBERU 7:24-26

HEBERU 7:24-26 YCE

Ṣugbọn ní ti Jesu, ó wà títí. Nítorí náà kò sí ìdí tí a óo fi tún yan alufaa mìíràn dípò rẹ̀. Ìdí nìyí tí ó fi lè gba àwọn tí wọ́n bá súnmọ́ Ọlọrun nípasẹ̀ rẹ̀ là, lọ́nà gbogbo títí lae nítorí pé ó wà láàyè títí láti máa bẹ̀bẹ̀ fún wọn. Irú olórí alufaa bẹ́ẹ̀ ni ó yẹ wá. Ẹni mímọ́; tí kò ní ẹ̀tàn, tí kò ní àbùkù, tí kò bá àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ kẹ́gbẹ́, tí a gbé ga kọjá àwọn ọ̀run.