HEBERU 7:23-25

HEBERU 7:23-25 YCE

Àwọn alufaa ìdílé Lefi pọ̀ nítorí ikú kò jẹ́ kí èyíkéyìí ninu wọn lè wà títí ayé. Ṣugbọn ní ti Jesu, ó wà títí. Nítorí náà kò sí ìdí tí a óo fi tún yan alufaa mìíràn dípò rẹ̀. Ìdí nìyí tí ó fi lè gba àwọn tí wọ́n bá súnmọ́ Ọlọrun nípasẹ̀ rẹ̀ là, lọ́nà gbogbo títí lae nítorí pé ó wà láàyè títí láti máa bẹ̀bẹ̀ fún wọn.