Ẹ má jẹ́ kí ìfẹ́ owó gbà yín lọ́kàn. Ẹ ní ìtẹ́lọ́rùn pẹlu ohun tí ẹ ní. Nítorí Ọlọrun fúnrarẹ̀ ti sọ pé, “N kò ní fi ọ́ sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni n kò ní kọ̀ ọ́!” Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, a lè fi ìgboyà sọ pé, “Oluwa ni olùrànlọ́wọ́ mi, ẹ̀rù kò ní bà mí. Ohun yòówù tí eniyan lè ṣe sí mi.” Ẹ ranti àwọn aṣiwaju yín, àwọn tí wọ́n mú ọ̀rọ̀ Ọlọrun wá fun yín. Ẹ ronú nípa iṣẹ́ wọn ati bí wọ́n ṣe kú. Kí ẹ ṣe àfarawé igbagbọ wọn. Bákan náà ni Jesu Kristi wà lánàá, lónìí ati títí lae. Ẹ má ṣe jẹ́ kí oríṣìíríṣìí ẹ̀kọ́ àjèjì mu yín ṣìnà. Ohun tí ó dára ni pé kí ọkàn yín gba agbára nípa oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun, kì í ṣe nípa ìlànà ohun tí a jẹ, tabi ohun tí a kò jẹ, irú ìlànà bẹ́ẹ̀ kò ṣe àwọn tí ó ń tẹ̀lé e ní anfaani.
Kà HEBERU 13
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: HEBERU 13:5-9
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò