Heb 13:5-9
Heb 13:5-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ki ọkàn nyin ki o máṣe fa si ifẹ owo, ki ohun ti ẹ ni ki o to nyin; nitori on tikalarẹ ti wipe, Emi kò jẹ fi ọ silẹ, bẹni emi kò jẹ kọ ọ silẹ. Nitorina ni awa ṣe nfi igboiya wipe, Oluwa li oluranlọwọ mi, emi kì yio bẹ̀ru; kili enia le ṣe si mi? Ẹ mã ranti awọn ti nwọn jẹ olori nyin, ti nwọn ti sọ ọ̀rọ Ọlọrun fun nyin; ki ẹ mã ro opin ìwa-aiye wọn, ki ẹ si mã ṣe afarawe igbagbọ́ wọn. Jesu Kristi ọkanna ni li aná, ati li oni, ati titi lai. Ẹ máṣe jẹ ki a fi onirũru ati ẹkọ́ àjeji gbá nyin kiri. Nitori o dara ki a mu nyin li ọkàn le nipa ore-ọfẹ, kì iṣe nipa onjẹ, ninu eyiti awọn ti o ti nrìn ninu wọn kò li ère.
Heb 13:5-9 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ má jẹ́ kí ìfẹ́ owó gbà yín lọ́kàn. Ẹ ní ìtẹ́lọ́rùn pẹlu ohun tí ẹ ní. Nítorí Ọlọrun fúnrarẹ̀ ti sọ pé, “N kò ní fi ọ́ sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni n kò ní kọ̀ ọ́!” Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, a lè fi ìgboyà sọ pé, “Oluwa ni olùrànlọ́wọ́ mi, ẹ̀rù kò ní bà mí. Ohun yòówù tí eniyan lè ṣe sí mi.” Ẹ ranti àwọn aṣiwaju yín, àwọn tí wọ́n mú ọ̀rọ̀ Ọlọrun wá fun yín. Ẹ ronú nípa iṣẹ́ wọn ati bí wọ́n ṣe kú. Kí ẹ ṣe àfarawé igbagbọ wọn. Bákan náà ni Jesu Kristi wà lánàá, lónìí ati títí lae. Ẹ má ṣe jẹ́ kí oríṣìíríṣìí ẹ̀kọ́ àjèjì mu yín ṣìnà. Ohun tí ó dára ni pé kí ọkàn yín gba agbára nípa oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun, kì í ṣe nípa ìlànà ohun tí a jẹ, tabi ohun tí a kò jẹ, irú ìlànà bẹ́ẹ̀ kò ṣe àwọn tí ó ń tẹ̀lé e ní anfaani.
Heb 13:5-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Kí ọkàn yín má ṣe fà sí ìfẹ́ owó, ki ohun tí ẹ ní tó yin; nítorí òun tìkára rẹ̀ ti wí pé, “Èmi kò jẹ́ fi ọ́ sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò jẹ́ kọ̀ ọ́ sílẹ̀.” Nítorí náà ni àwa ṣe ń fi ìgboyà wí pé, “Olúwa ni olùrànlọ́wọ́ mi, èmi kì yóò bẹ̀rù; kín ni ènìyàn lè ṣe sí mi?” Ẹ máa rántí àwọn tiwọn jẹ́ aṣáájú yín, tiwọn ti sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún yín; kí ẹ máa ro òpin ìwà ayé wọn, kí ẹ sì máa ṣe àfarawé ìgbàgbọ́ wọn. Jesu Kristi ọ̀kan náà ni lánàá, àti lónìí, àti títí láé. Ẹ má ṣe jẹ́ kí a fi onírúurú àti àjèjì ẹ̀kọ́ gbá yin kiri. Nítorí ó dára kí a mú yin lọ́kàn le nípa oore-ọ̀fẹ́, kì í ṣe nípa oúnjẹ nínú èyí tí àwọn tí ó ti rìn nínú wọn kò ní èrè.